Ṣàwárí › Àkòrí › Ẹ̀tàn àti ìparadà
Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu
Ẹ̀tàn àti ìparadà nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (45), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
Nínú Gẹnẹsisi
- Ejò sọ fún obìnrin náà pé: ‘Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan’Gẹ 3:4
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 3:4Ejò wí fún obìnrin náà pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.”
- Abramu ní kí Sarai sọ pé arábìnrin òun niGẹ 12:13
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 12:13Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.”
- Ní Gerari, Abrahamu tún sọ nípa Sara pé: ‘Arábìnrin mi ni’Gẹ 20:2
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 20:2Abrahamu sì sọ ní ti Sara aya rẹ̀ níbẹ̀ pé, “Arábìnrin mi ni.” Abimeleki ọba Gerari sì ránṣẹ́ mú Sara wá sí ààfin rẹ̀.
- Isaaki sọ pé arábìnrin òun ni Rebeka, nítorí ó bẹ̀rù pé àwọn ọkùnrin ibẹ̀ yóò pa òunGẹ 26:7
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 26:7Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà bi í léèrè ní ti aya rẹ̀, ó sì wí pé, “Arábìnrin mi ní í ṣe,” nítorí tí ó bẹ̀rù láti jẹ́wọ́ wí pé, “Aya mi ni.” Ó ń rò wí pé, “Kí àwọn ọkùnrin ibẹ̀ náà má ba à pa mí nítorí Rebeka, nítorí tí òun ní ẹwà púpọ̀.”
- Rebeka fi aṣọ Esau àti awọ ewúrẹ́ wọ JakọbuGẹ 27:15–16
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 27:15–16Nígbà náà ni Rebeka mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Esau ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rebeka, ó sì fi wọ Jakọbu ọmọ rẹ̀ àbúrò. Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ọ̀bọ̀rọ́ ọrùn.
- Jakọbu sọ fún baba rẹ̀ tí kò ríran: ‘Èmi ni Esau àkọ́bí rẹ’Gẹ 27:1, Gẹ 27:19
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 27:1Nígbà ti Isaaki di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tó bẹ́ẹ̀ tí kò le ríran. Ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Ọmọ mi.” Esau sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
Gẹ 27:19Jakọbu sì fèsì pé, “Èmi ni Esau àkọ́bí rẹ, èmi ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ fún mi, jọ̀wọ́ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.”
- Labani fi Lea fún un dípò Rakeli; Jakọbu: ‘èéṣe tí ìwọ tàn mi?’Gẹ 29:23, Gẹ 29:25
- Jakọbu sá lọ láìsọ fún LabaniGẹ 31:20
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 31:20Síwájú sí i, Jakọbu tan Labani ará Aramu, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sálọ.
- Rakeli fi àwọn òrìṣà ilé Labani pamọ́ sínú gàárì, ó sì jókòó lé wọnGẹ 31:34–35
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 31:34–35Rakeli sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ìbákasẹ, ó sì jókòó lé e lórí. Labani sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun. Rakeli sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ baba à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà ìdílé náà.
- Àwọn ọmọ Jakọbu ní kí àwọn ọkùnrin Ṣekemu kọlà, lẹ́yìn náà wọ́n kọlu ìlú náàGẹ 34:13, Gẹ 34:15, Gẹ 34:25
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 34:13Àwọn ọmọ Jakọbu sì fi ẹ̀tàn dá Ṣekemu àti Hamori baba rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì wí pé, nítorí tí ó ti ba ògo Dina arábìnrin wọn jẹ́.
Gẹ 34:15Àwa yóò fi ara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà.
Gẹ 34:25Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jakọbu méjì, Simeoni àti Lefi tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dina, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà.
- Àwọn arákùnrin tẹ aṣọ Josẹfu bọ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́, wọ́n sì fi hàn JakọbuGẹ 37:31–33
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 37:31–33Nígbà náà ni wọ́n mú aṣọ Josẹfu, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì tẹ aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà. Wọ́n sì mú aṣọ ọlọ́nà aláràbarà náà padà sí ọ̀dọ̀ baba wọn, wọ́n sì wí pé, “A rí èyí he nínú oko, yẹ̀ ẹ́ wò, kí o sì mọ̀ bóyá ti ọmọ rẹ ni.” Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Háà! Aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àní àní, ó ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”
- Tamari fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, Juda sì rò pé panṣágà niGẹ 38:14–15
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 38:14–15Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́n. Ó sì jókòó sí ẹnu-bodè Enaimu, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Timna. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣela ti dàgbà, síbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya. Nígbà tí Juda rí i, ó rò pé panṣágà ni, nítorí ó ti bo ojú rẹ̀.
- Josẹfu ní kí a fi kọ́ọ̀bù rẹ̀ pamọ́ sínú àpò BenjaminiGẹ 44:1–2
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 44:1–2Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Di oúnjẹ kún inú àpò àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n èyí tí wọ́n le rù, kí o sì mú owó olúkúlùkù àwọn ọkùnrin náà padà sí ẹnu àpò rẹ̀. Nígbà náà ni kí o mú kọ́ọ̀bù idẹ mi sí ẹnu àpò èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn nínú wọn pẹ̀lú owó tí ó fi ra ọkà,” ó sì ṣe bí Josẹfu ti sọ.
Àwọn onídàájọ́ àti àwọn ọba
- Àwọn ará Gibeoni mú àpò gbígbó àti àkàrà bíbu wá, wọ́n ní ilẹ̀ jíjìn ni wọ́n ti wáJoṣ 9:4–6
Àwọn ẹsẹ
Joṣ 9:4–6wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn. Wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí aṣojú tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn kún fún ẹrù tí a fi àwọn àpò tó ti gbó dì, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán. Àwọn ọkùnrin náà sì wọ bàtà àti aṣọ tí ó ti gbó. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n pèsè fún ara wọn sì bu. Wọ́n sì tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Gilgali, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa.”
- Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ṣe àdéhùn, Israẹli gbọ́ pé aládùúgbò wọn ni wọ́nJoṣ 9:16
Àwọn ẹsẹ
Joṣ 9:16Ní ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn ará Gibeoni, àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé aládùúgbò wọn ni wọ́n, tí ń gbé ní tòsí wọn.
- Jaeli pe Sisera wọlé, ó fún un ní wàrà, ó sì pa á lójú oorunOn 4:18–21
Àwọn ẹsẹ
On 4:18–21Jaeli sì jáde síta láti pàdé Sisera, ó sì wí fún un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, Olúwa mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó. Sisera wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì ṣí awọ wàrà kan, ó sì fún un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà. Sisera sọ fún Jaeli pé, “Kí ó dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ” Ṣùgbọ́n Jaeli ìyàwó Heberi mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òòlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó sùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin, ó sì kú.
- Mikali tẹ́ ère pẹ̀lú irun ewúrẹ́ sórí ibùsùn Dafidi: ‘Ó rẹ̀ ẹ́’1Sa 19:13–16
Àwọn ẹsẹ
1Sa 19:13–16Mikali gbé ère ó sì tẹ́ e lórí ibùsùn, ó sì fi irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀. Nígbà ti Saulu rán ènìyàn láti lọ fi agbára mú Dafidi, Mikali wí pé, “Ó rẹ̀ ẹ́.” Nígbà náà ni Saulu rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dafidi ó sì sọ fún wọn pé, “Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ère ni ó bá lórí ibùsùn àti irun ewúrẹ́ ní orí ère náà.
- Dafidi sọ fún àlùfáà ní Nobu pé iṣẹ́ àṣírí ọba ni òun ń ṣe1Sa 21:1–2
Àwọn ẹsẹ
1Sa 21:1–2Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?” Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí.
- Dafidi kọlu àwọn ará Geṣuri, ṣùgbọ́n ó sọ fún Akiṣi pé gúúsù Juda ni òun kọlù1Sa 27:8, 1Sa 27:10
Àwọn ẹsẹ
1Sa 27:8Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Geṣuri, àti àwọn ará Gesri, àti àwọn ará Amaleki àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣuri títí ó fi dé ilẹ̀ Ejibiti.
1Sa 27:10Akiṣi sì bi í pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí?” Dafidi sì dáhùn pé, “Sí ìhà gúúsù ti Juda ni, tàbí sí ìhà gúúsù ti Jerahmeeli,” tàbí “Sí ìhà gúúsù ti àwọn ará Keni.”
- Amnoni díbọ́n pé òun ṣàìsàn kí Tamari lè wá sọ́dọ̀ òun2Sa 13:6
Àwọn ẹsẹ
2Sa 13:6Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn, ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.”
- Joabu rán ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti Tekoa láti ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀2Sa 14:2–3
Àwọn ẹsẹ
2Sa 14:2–3Joabu sì ránṣẹ́ sí Tekoa, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀. Kí o sì tọ ọba wá, kí o sọ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí.” Joabu sì fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu.
- Absalomu béèrè láti lọ sí Hebroni nítorí ẹ̀jẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀tẹ̀ níbẹ̀2Sa 15:7, 2Sa 15:10
Àwọn ẹsẹ
2Sa 15:7Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Absalomu sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hebroni.
2Sa 15:10Ṣùgbọ́n Absalomu rán àmì sáàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Absalomu jẹ ọba ní Hebroni.’ ”
- Huṣai, ọ̀rẹ́ Dafidi, kí Absalomu: ‘Kí ọba ó pẹ́!’2Sa 16:16
Àwọn ẹsẹ
2Sa 16:16Ó sì ṣe, nígbà tí Huṣai ará Arki, ọ̀rẹ́ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.”
- Absalomu yan ìmọ̀ràn Huṣai dípò ti Ahitofeli2Sa 17:14
Àwọn ẹsẹ
2Sa 17:14Absalomu àti gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wí pé, “Ìmọ̀ Huṣai ará Arki sàn ju ìmọ̀ Ahitofeli lọ! Nítorí Olúwa fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Ahitofeli po.” Nítorí kí Olúwa lè mú ibi wá sórí Absalomu.
- Wòlíì àgbà kan purọ́ láti mú ènìyàn Ọlọ́run padà sí ilé rẹ̀1Ọb 13:18
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 13:18Wòlíì àgbà náà sì wí fún un pé, “Wòlíì ni èmi náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìwọ. Angẹli sì sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘Mú un padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ àti kí ó lè mu omi.’ ” (Ṣùgbọ́n ó purọ́ fún un ni.)
- Aya Jeroboamu para dà; Ahijah, tí kò ríran, pè é lórúkọ1Ọb 14:2, 1Ọb 14:4, 1Ọb 14:6
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 14:2Jeroboamu sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́n ní aya Jeroboamu. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣilo. Ahijah wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yìí.
1Ọb 14:4Bẹ́ẹ̀ ni aya Jeroboamu sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Ahijah ní Ṣilo. Ahijah kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀.
1Ọb 14:6Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Ahijah sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jeroboamu. Kí ló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ.
- Gehasi parọ́ iṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Eliṣa láti gba fàdákà lọ́wọ́ Naamani2Ọb 5:22, 2Ọb 5:25
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 5:22“Gbogbo nǹkan wà dáradára,” Gehasi dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Efraimu. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’ ”
2Ọb 5:25Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Eliṣa. “Níbo ni o ti wà Gehasi?” Eliṣa béèrè. “Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Gehasi dá a lóhùn.
- Jehu kéde ẹbọ ńlá fún Baali láti kó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jọ2Ọb 10:19
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 10:19Nísinsin yìí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Baali jọ fún mi, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan kí ó kù, nítorí èmí yóò rú ẹbọ ńlá sí Baali. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti wá, kò ní wà láààyè mọ́.” Ṣùgbọ́n Jehu fi ẹ̀tàn ṣe é, kí ó lè pa àwọn òjíṣẹ́ Baali run.
- Sanballati pe Nehemiah sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono, ó ń gbèrò láti ṣe é ní ibiNe 6:2
Àwọn ẹsẹ
Ne 6:2Sanballati àti Geṣemu rán iṣẹ́ yìí sí mi pé, “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi;
- Ọkùnrin kan tí a bẹ̀ ní ọ̀yà rọ Nehemiah láti fi ara pamọ́ sínú tẹmpiliNe 6:10, Ne 6:12
Àwọn ẹsẹ
Ne 6:10Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemaiah ọmọ Delaiah, ọmọ Mehetabeeli, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó wí pé, “Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú tẹmpili, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹmpili dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́.”
Ne 6:12Èmi wòye pé Ọlọ́run kò rán an, ṣùgbọ́n ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí mi nítorí Tobiah àti Sanballati ti bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀.
Nínú Májẹ̀mú Tuntun
- Herodu sọ fún àwọn amòye pé òun náà fẹ́ lọ foríbalẹ̀ fún ọmọ náàMt 2:8
Àwọn ẹsẹ
Mt 2:8Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”
- Àwọn olórí àlùfáà ń wá ọ̀nà láti mú Jesu ní ìkọ̀kọ̀Mk 14:1
Àwọn ẹsẹ
Mk 14:1Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni àjọ ìrékọjá àti tí àìwúkàrà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jesu ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á.
- A fún àwọn ọmọ-ogun ní owó kí wọ́n sọ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jí òkú náàMt 28:12–13
Àwọn ẹsẹ
Mt 28:12–13Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’
- Anania àti Safira yan apá kan nínú owó ilẹ̀ wọn pamọ́Ìṣe 5:1–2, Ìṣe 5:8
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 5:1–2Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan. Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.
Ìṣe 5:8Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.”
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.