Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu
Oyin nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (22), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
- Ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyinEk 3:8, Le 20:24
Àwọn ẹsẹ
Ek 3:8Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi.
Le 20:24Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, “Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn, Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.” Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn yòókù.
- Ilẹ̀ òróró olifi àti oyinDe 8:8
Àwọn ẹsẹ
De 8:8Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà barle, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pomegiranate, òróró olifi àti oyin.
- Manna dùn bí àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi oyin ṣeEk 16:31
Àwọn ẹsẹ
Ek 16:31Àwọn ènìyàn Israẹli sì pe oúnjẹ náà ní manna. Ó funfun bí irúgbìn korianderi, ó sì dùn bí àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ti a fi oyin ṣe.
- A kò gbọdọ̀ sun oyin nínú ọrẹLe 2:11
Àwọn ẹsẹ
Le 2:11“ ‘Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ tí ẹ bá mú wá fún Olúwa kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà nínú, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ sun ohun wíwú tàbí oyin nínú ọrẹ tí ẹ fi iná sun sí Olúwa.
- Oyin láti inú àpátaDe 32:13, Sm 81:16
Nínú àwọn ìtàn
- Jakọbu fi oyin díẹ̀ ránṣẹ́ ní ẹ̀bùn sí EjibitiGẹ 43:11
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 43:11Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi
- Samsoni jẹ oyin láti inú òkú kìnnìúnOn 14:8–9
Àwọn ẹsẹ
On 14:8–9Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnnìún náà. Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin, ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà.
- Jonatani tọ́ oyin wò nínú igbó, ó sì rú ìbúra Saulu1Sa 14:25–27, 1Sa 14:43
Àwọn ẹsẹ
1Sa 14:25–27Gbogbo àwọn ènìyàn sì wọ inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀ náà. Nígbà tí wọ́n dé inú igbó náà, wọ́n sì rí oyin ń sun jáde, kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan ẹnu rẹ̀ síbẹ̀, nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìfiré. Ṣùgbọ́n Jonatani kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ìfibú kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán.
1Sa 14:43Saulu sì wí fún Jonatani pé, “Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi.” Jonatani sì sọ fún un pé, “Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò. Nísinsin yìí ṣé mo ní láti kú?”
- Ojú rẹ̀ dán lẹ́yìn tí ó tọ́ oyin díẹ̀ wò1Sa 14:29
Àwọn ẹsẹ
1Sa 14:29Jonatani sì wí pé, “Baba mi ti mú ìdààmú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí.
- Àwọn ọ̀rẹ́ mú oyin wá fún àwọn ènìyàn Dafidi tí ebi ń pa2Sa 17:29
Àwọn ẹsẹ
2Sa 17:29Àti oyin, àti òrí-àmọ́, àti àgùntàn, àti wàràǹkàṣì màlúù, wá fún Dafidi àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, láti jẹ: nítorí tí wọ́n wí pé, “Ebi ń pa àwọn ènìyàn, ó sì rẹ̀ wọ́n, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní aginjù.”
- Aya Jeroboamu mú ìgò oyin lọ fún wòlíì1Ọb 14:3
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 14:3Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì sọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.”
- Juda fi oyin ṣòwò pẹ̀lú TireEl 27:17
Àwọn ẹsẹ
El 27:17“ ‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.
- Johanu jẹ eṣú àti oyin ìgànMt 3:4
Àwọn ẹsẹ
Mt 3:4Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n
- Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dáraÒw 24:13
Àwọn ẹsẹ
Òw 24:13Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára, oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
- Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nbaÒw 25:16, Òw 25:27
- Oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó yó; òróǹró dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń paÒw 27:7
Àwọn ẹsẹ
Òw 27:7Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
- Ó dùn ju oyin àti afárá oyin lọSm 19:10
Àwọn ẹsẹ
Sm 19:10Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ, ju wúrà tí o dára jùlọ, wọ́n dùn ju oyin lọ, àti ju afárá oyin lọ.
- Ètè rẹ, ìyàwó mi, ń kan dídùn bí afárá oyinOrin 4:11
Àwọn ẹsẹ
Orin 4:11Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi; wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ. Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni.
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.