Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ọlọ, ààrò àti àkàrà yíyan

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Ọlọ, ààrò àti àkàrà yíyan nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (32), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

Ọlọ àti lílọ ọkà

  • A kò gbọdọ̀ gba ọlọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdúró fún gbèsèDe 24:6
    Àwọn ẹsẹ
    De 24:6Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ìyá ọlọ tàbí ọmọ ọlọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdúró fún gbèsè, nítorí pé ẹ̀mí ènìyàn ni ó gbà ní pàṣípàrọ̀ n nì.
  • Ní Ejibiti, ẹrúbìnrin tí ó rẹlẹ̀ jùlọ ni ó ń lọ ọlọEk 11:5
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 11:5Gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni yóò kùú, bẹ̀rẹ̀ lórí àkọ́bí ọkùnrin Farao tí ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, tí ó fi dé orí àkọ́bí ọmọkùnrin ti ẹrúbìnrin tí ń lọ ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú.
  • A ń lọ manna lórí ọlọ tàbí gún un nínú odóNu 11:8
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 11:8Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le sè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe.
  • Ní Tebesi, obìnrin kan sọ ọmọ ọlọ lu Abimeleki lóríOn 9:53, 2Sa 11:21
    Àwọn ẹsẹ
    On 9:53obìnrin kan sọ ọmọ ọlọ lu Abimeleki lórí, ó sì fọ́ ọ ní agbárí.
    2Sa 11:21Ta ni ó pa Abimeleki ọmọ Jerubu-Beṣeti? Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta-ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tebesi? Èéha ti rí tí ẹ̀yin fi súnmọ́ odi náà? Ìwọ yóò sì wí fún un pé, Uriah ìránṣẹ́ rẹ ará Hiti kú pẹ̀lú.’ ”
  • Samsoni, tí a ti yọ ojú rẹ̀ tí a sì dè, ń lọ ọlọ nínú túbú ní GasaOn 16:21
    Àwọn ẹsẹ
    On 16:21Nígbà náà ni àwọn Filistini mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú un lọ sí Gasa. Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú.
  • Jesu sọ nípa obìnrin méjì tí ń jùmọ̀ lọ ọlọMt 24:41, Lk 17:35
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 24:41Àwọn obìnrin méjì yóò jùmọ̀ máa lọ ọlọ pọ̀, a yóò mú ọ̀kan, a ó fi ẹni kejì sílẹ̀.
    Lk 17:35Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.”
  • Jesu: ó sàn kí a so òkúta ńlá mọ́ ènìyàn lọ́rùn, kí a sì rì íMt 18:6
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 18:6“Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi Òkun.
  • Jeremiah dárúkọ ìró ọlọ pẹ̀lú ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwóJr 25:10
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 25:10Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà.
  • Ẹkún Jeremiah: àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ń ru òkúta ọlọẸj 5:13
    Àwọn ẹsẹ
    Ẹj 5:13Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta; àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.

Ààrò àti àkàrà yíyan

  • Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò wọ ibi ìdáná àti ìkòkò ìyẹ̀fun EjibitiEk 8:3
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 8:3Odò Naili yóò kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọ́. Wọn yóò gòkè wá sí ààfin rẹ, àti yàrá rẹ ni orí ibùsùn rẹ. Wọn yóò gòkè wá sí ilé àwọn ìjòyè rẹ àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ, àti sí ibi ìdáná rẹ, àti sí inú ìkòkò ìyẹ̀fun rẹ.
  • A lè yan ọrẹ ohun jíjẹ nínú ààrò tàbí sè é lórí àwo ìdánáLe 2:4, Le 7:9
    Àwọn ẹsẹ
    Le 2:4“ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ, èyí tí a yan lórí ààrò iná, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára, àkàrà tí a ṣe láìní ìwúkàrà, tí a sì fi òróró pò àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ṣe láìní ìwúkàrà èyí tí a fi òróró pò.
    Le 7:9Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a bá yan lórí ààrò, àti gbogbo èyí tí a yan nínú apẹ, àti nínú àwopẹ̀tẹ́, ni kí ó jẹ́ ti àlùfáà tí ó rú ẹbọ náà.
  • Ààrò tí òkú aláìmọ́ bá kàn ni a gbọdọ̀ fọ́Le 11:35
    Àwọn ẹsẹ
    Le 11:35Gbogbo ohun tí èyíkéyìí nínú òkú wọn bá já lé lórí di àìmọ́. Yálà ààrò ni tàbí ìkòkò ìdáná wọn gbọdọ̀ di fífọ́. Wọ́n jẹ́ àìmọ́. Ẹ sì gbọdọ̀ kà wọ́n sí àìmọ́.
  • Ègún nínú Òfin: obìnrin mẹ́wàá yóò máa se oúnjẹ nínú ààrò kanLe 26:26
    Àwọn ẹsẹ
    Le 26:26Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, dé bi pé: inú ààrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa se oúnjẹ yín. Òsùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín, ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó.
  • Sara yóò po òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta, yóò sì ṣe àkàràGẹ 18:6
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 18:6Abrahamu sì yára tọ Sara aya rẹ̀ lọ nínú àgọ́, ó wí pé, “Tètè mú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta kí o sì pò ó pọ̀, kí o sì ṣe oúnjẹ.”
  • Lọti dín àkàrà aláìwú fún àwọn àlejò rẹ̀Gẹ 19:3
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 19:3Ṣùgbọ́n Lọti rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe àsè fún wọn, ó sì dín àkàrà aláìwú fún wọ́n, wọ́n sì jẹ.
  • Olórí alásè Farao lá àlá agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí rẹ̀Gẹ 40:16–17
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 40:16–17Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtumọ̀ tí Josẹfu fún àlá náà dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá, mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí. Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Farao, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi.”
  • Bí wọ́n ti ń kúrò ní Ejibiti, Israẹli fi ìyẹ̀fun tí wọ́n gbé ṣe àkàrà aláìwúEk 12:34, Ek 12:39
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 12:34Àwọn ènìyàn náà sì mú ìyẹ̀fun púpọ̀ kí wọn tó fi ìwúkàrà sí i, wọ́n gbe le èjìká wọn nínú ọpọ́n tí wọ́n ti fi aṣọ dì.
    Ek 12:39Pẹ̀lú ìyẹ̀fun tí kò ní ìwúkàrà nínú tí wọ́n gbé jáde láti Ejibiti wá ni wọ́n fi ṣe àkàrà aláìwú. Ìyẹ̀fun náà kò ni ìwúkàrà nínú nítorí a lé wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wọn kò si rí ààyè láti tọ́jú oúnjẹ fún ara wọn.
  • Kí ọjọ́ ìsinmi tó dé: ‘Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan’Ek 16:23
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 16:23Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún Olúwa. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ”
  • A yan ìṣù àkàrà méjìlá fún tábìlì wúrà níwájú OlúwaLe 24:5–6
    Àwọn ẹsẹ
    Le 24:5–6“Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan. Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fà mẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa.
  • Samuẹli: ọba yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa se oúnjẹ àti láti máa ṣe àkàrà1Sa 8:13
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 8:13Yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa ṣe olùṣe ìkunra olóòórùn dídùn àti láti máa ṣe àsè àti láti máa ṣe àkàrà.
  • Obìnrin abókùúsọ̀rọ̀ ní Endori po ìyẹ̀fun, ó sì ṣe àkàrà aláìwú fún Saulu1Sa 28:24
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 28:24Obìnrin náà sì ni ẹgbọrọ màlúù kan ti ó sanra ni ilé, ó sì yára, ó pa á, ó sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà àìwú.
  • Tamari po ìyẹ̀fun, ó sì dín àkàrà fún Amnoni2Sa 13:8
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 13:8Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà.
  • Elijah jí, ó sì rí àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yín iná1Ọb 19:6
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 19:6Ó sì wò ó yíká, àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yín iná, àti orù-omi wà lẹ́bàá orí rẹ̀. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì tún dùbúlẹ̀.
  • Isaiah: a fi apá kan igi ṣe àkàrà, èyí tí ó kù sì di òrìṣàIsa 44:15, Isa 44:19
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 44:15Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn; díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́, ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà. Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín; ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un.
    Isa 44:19Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú, kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye láti sọ wí pé, “Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná; mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀, mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí? Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”
  • Jeremiah ń gba àkàrà lójoojúmọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alákàràJr 37:21
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 37:21Ọba Sedekiah wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremiah sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà tó wà ní ìlú yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremiah wà nínú àgbàlá náà.
  • Odi Jerusalẹmu ní ilé ìṣọ́ ìléruNe 3:11, Ne 12:38
    Àwọn ẹsẹ
    Ne 3:11Malkiah ọmọ Harimu àti Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti ilé ìṣọ́ ìléru.
    Ne 12:38Àwọn ẹgbẹ́ akọrin kejì gba ọ̀nà òdìkejì lọ. Mo tẹ̀lé wọn ní orí odi, pẹ̀lú ìdajì àwọn ènìyàn, kọjá ilé ìṣọ́ ìléru lọ sí odi fífẹ̀,

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.