Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Bíríkì àti bíríkì ṣíṣe

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Bíríkì àti bíríkì ṣíṣe nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (15), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Ní Babeli: ‘ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà’Gẹ 11:3
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 11:3Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi).
  • Wọ́n lo bíríkì dípò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ dípò ẹfunGẹ 11:3
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 11:3Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi).
  • Esekiẹli ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sí orí amọ̀ ṣíṣù kanEl 4:1
    Àwọn ẹsẹ
    El 4:1“Nísinsin yìí, ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sí orí rẹ̀.
  • Dafidi fi àwọn ará Ammoni sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe2Sa 12:31
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 12:31Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtulẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ammoni. Dafidi àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jerusalẹmu.
  • Jeremiah rì òkúta mọ́ inú bíríkì pèpéle ààfin Farao ní TafanesiJr 43:9
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 43:9“Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu-ọ̀nà ààfin Farao ní Tafanesi.
  • Ìyangàn nínú Isaiah: ‘Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀ ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán’Isa 9:10
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 9:10Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀ ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán, a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀ ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn.
  • Isaiah sọ nípa tùràrí tí a ń sun lórí pẹpẹ bíríkìIsa 65:3
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 65:3àwọn ènìyàn tí wọ́n bí mi nínú nígbà gbogbo lójú ara mi gan an, wọ́n ń rú ẹbọ nínú ọgbà wọ́n sì ń sun tùràrí lórí i pẹpẹ bíríkì;
  • Nahumu sí Ninefe: ‘wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀’, tún ibi sísun bíríkì ṣeNh 3:14
    Àwọn ẹsẹ
    Nh 3:14Pọn omi nítorí ìhámọ́, mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀, kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.

Ní Ejibiti

  • A mú ayé àwọn ọmọ Israẹli korò nípa iṣẹ́ bíríkì àti amọ̀Ek 1:14
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 1:14Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Ejibiti ń lò wọ́n ní ìlòkulò.
  • Wọ́n kọ́ Pitomi àti Ramesesi, ìlú ìṣúraEk 1:11
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 1:11Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pitomi àti Ramesesi gẹ́gẹ́ bí ìlú ìṣúra pamọ́ sí fún Farao.
  • Farao: kò sí koríko gbígbẹ mọ́, ṣùgbọ́n iye bíríkì kan náàEk 5:7–8
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 5:7–8“Ẹ̀yin kò ní láti pèsè koríko gbígbẹ fún bíríkì sísun mọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ jẹ́ kí wọn máa wá koríko gbígbẹ fún ara wọn. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú. Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run wa.’
  • Àwọn ènìyàn fọ́n káàkiri Ejibiti láti ṣa ìdì koríkoEk 5:12
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 5:12Gbogbo wọn sí fọ́n káàkiri ni ilẹ̀ Ejibiti láti sa ìdì koríko tí wọn yóò lò bí ì koríko gbígbẹ fún sísun bíríkì.
  • A lu àwọn alábojútó iṣẹ́ ọmọ Israẹli nítorí wọn kò pé iye bíríkìEk 5:14
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 5:14Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao yàn lára ọmọ Israẹli ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?”
  • ‘Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ … Ẹ ṣe bíríkì!’Ek 5:16
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 5:16Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ ṣe bíríkì!’ Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”
  • ‘Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù’Ek 5:18–19
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 5:18–19Nísinsin yìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe.” Àwọn ọmọ Israẹli tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù.”

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.