Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ọ̀nà

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Ọ̀nà nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (15), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Israẹli béèrè láti gba òpópónà ọba kọjá ní EdomuNu 20:17–19
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 20:17–19Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀-èdè rẹ kọjá, àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kànga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.” Ṣùgbọ́n Edomu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun sí yín, a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.” Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé, “A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkan kan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”
  • Ìbéèrè kan náà sí Sihoni ọba àwọn ará AmoriNu 21:22, De 2:27
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 21:22“Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”
    De 2:27“Jẹ́ kí a la ilẹ̀ ẹ yín kọjá. Àwa yóò gba ti òpópónà nìkan. A kò ní yà sọ́tùn tàbí sósì.
  • A ṣe ọ̀nà sí àwọn ìlú ààbòDe 19:3
    Àwọn ẹsẹ
    De 19:3Ṣe àwọn ọ̀nà sí wọn àti kí o pín ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún sí ọ̀nà mẹ́ta nítorí kí apànìyàn lè sá níbẹ̀.
  • A sin Rakeli sí ọ̀nà EfrataGẹ 35:19
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 35:19Báyìí ni Rakeli kú, a sì sin ín sí ọ̀nà Efrata (ti o túmọ̀ sí, Bẹtilẹhẹmu).
  • Joṣua lépa àwọn ọ̀tá gba ọ̀nà gíga Beti-HoroniJoṣ 10:10
    Àwọn ẹsẹ
    Joṣ 10:10Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda.
  • Ní ọjọ́ Ṣamgari, àwọn ọ̀nà òpópó dáOn 5:6
    Àwọn ẹsẹ
    On 5:6“Ní ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati, ní ọjọ́ Jaeli, àwọn ọ̀nà òpópó dá; àwọn arìnrìn-àjò sì ń gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀.
  • Ṣilo, ní ìhà ìlà-oòrùn òpópó tí ó lọ láti Beteli sí ṢekemuOn 21:19
    Àwọn ẹsẹ
    On 21:19Wọ́n sì wí pé, “Kíyèsi i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣilo ní ìhà àríwá Beteli àti ìhà ìlà-oòrùn òpópó náà tí ó gba Beteli kọjá sí Ṣekemu, àti sí ìhà gúúsù Lebona.”
  • Àwọn màlúù fa àpótí ẹ̀rí tààrà gba ọ̀nà Beti-Ṣemeṣi1Sa 6:12
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 6:12Nígbà náà; àwọn màlúù lọ tààrà sí ìhà Beti-Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà, wọ́n sì ń dún bí wọ́n ti ń lọ. Wọn kò yà sí ọ̀tún tàbí yà sí òsì. Àwọn aláṣẹ Filistini tẹ̀lé wọn títí dé ibodè Beti-Ṣemeṣi.
  • Ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀ lẹ́bàá ìṣàn omiIsa 7:3
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 7:3Lẹ́yìn èyí, Olúwa sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀.
  • Ọkùnrin kan tí ń sọ̀kalẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ sí Jeriko bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́ṣàLk 10:30–31
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 10:30–31Jesu sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán. Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà. Nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì.
  • Bartimeu jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tí ó jáde láti JerikoMk 10:46
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 10:46Wọ́n dé Jeriko, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jeriko, ọkùnrin afọ́jú kan, Bartimeu, ọmọ Timeu jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń ṣagbe.
  • Emmausi, ní nǹkan bí ọgọ́ta ibùsọ̀ sí JerusalẹmuLk 24:13
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 24:13Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀.
  • Ọ̀nà ijù láti Jerusalẹmu lọ sí GasaÌṣe 8:26
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 8:26Angẹli Olúwa sì sọ fún Filipi pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerusalẹmu lọ sí Gasa.”
  • Jesu ní láti kọjá láàrín Samaria lọ sí GaliliJh 4:3–5
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 4:3–5Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili. Òun sì ní láti kọjá láàrín Samaria. Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.