Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Beari

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Beari nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (7), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Dafidi lu kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn tí ó gbé àgùntàn pa1Sa 17:34–37
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 17:34–37Ṣùgbọ́n Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ti ń tọ́jú agbo àgùntàn baba rẹ̀. Nígbà tí kìnnìún tàbí àmọ̀tẹ́kùn bá wá láti wá gbé àgùntàn láti inú igbó. Mo sá tẹ̀lé e, mo lù ú, mo sì gba àgùntàn náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí ó kọjú sí mi, mo fi irun rẹ̀ gbá a mú, mo sì lù ú mo sì pa á. Ìránṣẹ́ rẹ ti pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, aláìkọlà Filistini yìí yóò jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pe ogun Ọlọ́run alààyè ní ìjà. Olúwa tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Filistini yìí.” Saulu wí fún Dafidi pé, “Lọ kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
  • Beari méjì lu méjìlélógójì nínú àwọn ọ̀dọ́ tí ó fi Eliṣa ṣe ẹlẹ́yà2Ọb 2:23–24
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 2:23–24Láti ibẹ̀ Eliṣa lọ sókè ní Beteli gẹ́gẹ́ bí ó ti ń rìn lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ kan jáde wá láti ìlú náà wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!” Wọ́n wí pé. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!” Ó sì yípadà, ó sì wò wọ́n ó sì fi wọ́n bú ní orúkọ Olúwa. Nígbà náà beari méjì sì jáde wá láti inú igbó ó sì lu méjìlélógójì lára àwọn ọ̀dọ́ náà.
  • Dafidi àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ korò bí àmọ̀tẹ́kùn tí a gbà ní ọmọ2Sa 17:8
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 17:8Huṣai sì wí pé, “Ìwọ mọ baba rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé alágbára ni wọ́n, wọ́n sì wà ní kíkorò ọkàn bí àmọ̀tẹ́kùn tí a gbà ní ọmọ ni pápá, baba rẹ sì jẹ́ jagunjagun ọkùnrin kì yóò bá àwọn ènìyàn náà gbé pọ̀ lóru.
  • Ó sàn láti pàdé beari tí a kó lọ́mọ ju aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀Òw 17:12
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 17:12Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
  • Olórí ìkà dàbí beari tí ń halẹ̀Òw 28:15
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 28:15Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀ ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára.
  • Ó sá fún kìnnìún, ó sì bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùnAm 5:19
    Àwọn ẹsẹ
    Am 5:19Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún, tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn. Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀ tí ejò sì bù ú ṣán.
  • Gbogbo wa là ń ké bí beariIsa 59:11
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 59:11Gbogbo wa là ń ké bí i beari; àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà. A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.