Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Túbú àti ẹ̀wọ̀n

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Túbú àti ẹ̀wọ̀n nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (45), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

Nínú Májẹ̀mú Láéláé

  • A ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba síGẹ 39:20
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 39:20Ó sì ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Josẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀,
  • Alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n sí ìkáwọ́ JosẹfuGẹ 39:22
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 39:22Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Josẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀.
  • Olórí agbọ́tí àti olórí alásè Farao wà nínú ẹ̀wọ̀n kan náàGẹ 40:3
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 40:3Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Josẹfu pẹ̀lú wà.
  • A mú Josẹfu jáde láti inú ìhámọ́, ó fá irun rẹ̀, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀Gẹ 41:14
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 41:14Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Josẹfu, wọn sì mú un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá síwájú Farao.
  • Josẹfu fi àwọn arákùnrin rẹ̀ sínú túbú ọjọ́ mẹ́ta, lẹ́yìn náà ó dè Simeoni mọ́lẹ̀Gẹ 42:17, Gẹ 42:24
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 42:17Ó sì fi gbogbo wọn sínú túbú fún ọjọ́ mẹ́ta.
    Gẹ 42:24Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni kúrò láàrín wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.
  • Ahabu: ẹ fi Mikaiah sínú túbú, kí ẹ sì fi oúnjẹ àti omi ìpọ́njú bọ́ ọ1Ọb 22:27
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 22:27kí ẹ sì wí pé, ‘Báyìí ni ọba wí: Ẹ fi eléyìí sínú túbú, kí ẹ sì fi oúnjẹ ìpọ́njú àti omi ìpọ́njú bọ́ ọ, títí èmi yóò fi padà bọ̀ ní àlàáfíà.’ ”
  • Asa bínú, ó sì fi Hanani wòlíì sínú túbú2Kro 16:7, 2Kro 16:10
    Àwọn ẹsẹ
    2Kro 16:7Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.
    2Kro 16:10Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.
  • Ọba Asiria fi Hosea ọba sínú túbú2Ọb 17:4
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 17:4Ṣùgbọ́n ọba Asiria rí i wí pé Hosea jẹ́ ọlọ́tẹ̀, nítorí ó ti rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ ọba Ejibiti, kò sì san owó òde mọ́ fún ọba Asiria, gẹ́gẹ́ bí o ti máa ń ṣe ní ọdọọdún. Nígbà náà ọba Asiria fi agbára mú ún, ó sì fi sínú túbú.
  • A fi ìwọ̀ àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ mú Manase lọ sí Babeli2Kro 33:10–11
    Àwọn ẹsẹ
    2Kro 33:10–11Olúwa bá Manase sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mú àwọn alákòóso ọmọ-ogun ọba Asiria láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Manase nígbèkùn, ó fi ìwọ̀ mú un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú un lọ sí Babeli.
  • A yọ ojú Sedekiah, a sì fi ẹ̀wọ̀n idẹ mú un lọ sí Babeli2Ọb 25:7, Jr 52:11
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 25:7Wọ́n sì pa ọmọ Sedekiah níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Babeli.
    Jr 52:11Lẹ́yìn náà, ọba Babeli yọ Sedekiah ní ojú, o sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì gbe e lọ sí Babeli níbi tí ó ti fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.
  • A tú Jehoiakini sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlógójì, ó sì ń jẹun ní tábìlì ọba2Ọb 25:27–29
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 25:27–29Ní ọdún kẹtàdínlógójì ìgbèkùn Jehoiakini ọba Juda, ní oṣù kejìlá, ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣù, Efili-Merodaki ọba Babeli, ní ọdún tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ kúrò nínú túbú. Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli. Ó sì pàrọ̀ àwọn aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

Jeremiah

  • A lù ú, a sì fi í sínú túbú ní òkè ẹnu-ọ̀nà BenjaminiJr 20:2
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 20:2Ó mú kí wọ́n lù wòlíì Jeremiah, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu-ọ̀nà ti Benjamini ní tẹmpili Olúwa.
  • A sé e mọ́ inú túbú tí ó ṣókùnkùn ní ilé Jonatani akọ̀wéJr 37:15–16
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 37:15–16Nítorí náà ni àwọn ìjòyè ṣe bínú sí Jeremiah, wọ́n jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n tún fi sí túbú nílé Jonatani akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú. Wọ́n fi Jeremiah sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri; níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́.
  • A pa á mọ́ ní àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, a sì ń fún un ní àkàrà lójoojúmọ́Jr 32:2, Jr 37:21
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 32:2Àwọn ogun ọba Babeli ìgbà náà há Jerusalẹmu mọ́. A sì sé wòlíì Jeremiah mọ́ inú túbú tí wọ́n ń ṣọ́ ní àgbàlá ilé ọba Juda.
    Jr 37:21Ọba Sedekiah wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremiah sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà tó wà ní ìlú yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremiah wà nínú àgbàlá náà.
  • A fi okùn sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sínú ihò tí kò ní omi, bí kò ṣe ẹrọ̀fọ̀Jr 38:6
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 38:6Wọ́n gbé Jeremiah sọ sínú ihò Malkiah, ọmọ ọba, tí ó wà ní àgbàlá ilé túbú; wọ́n fi okùn sọ Jeremiah kalẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ihò; kò sì ṣí omi nínú ihò náà bí kò ṣe ẹrọ̀fọ̀, Jeremiah sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀ náà.
  • A tú u sílẹ̀ ní Rama kúrò nínú ẹ̀wọ̀n ọwọ́ rẹ̀Jr 40:1, Jr 40:4
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 40:1Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa lẹ́yìn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rama. Ó rí Jeremiah tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrín gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jerusalẹmu àti Juda. Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli.
    Jr 40:4Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lé mi ká lọ sí Babeli, èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, dúró síbí. Wò ó, gbogbo orílẹ̀-èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.”

Nínú Májẹ̀mú Tuntun

  • Herodu fi ẹ̀wọ̀n dè Johanu, ó sì fi í sínú túbúMt 14:3
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 14:3Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀,
  • Láti inú ẹ̀wọ̀n, Johanu rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí JesuMt 11:2
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 11:2Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀
  • A bẹ́ orí Johanu nínú ilé túbúMt 14:10
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 14:10Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú.
  • Barabba wà nínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyànLk 23:19
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 23:19Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn.
  • Jesu: ‘ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò’Mt 25:36
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 25:36Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’
  • A ti Peteru àti Johanu mọ́ túbú títí di ọjọ́ kejì nítorí alẹ́ ti lẹ́Ìṣe 4:3
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 4:3Wọn sì nawọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ọjọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan.
  • Àwọn aposteli kò sí nínú túbú mọ́, bí ó tilẹ̀ wà ní títì pẹ̀lú àwọn olùṣọ́Ìṣe 5:18–19, Ìṣe 5:23
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 5:18–19Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú. Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde.
    Ìṣe 5:23“Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùṣọ́ dúró lóde níwájú ìlẹ̀kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ṣí ìlẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.”
  • Lábẹ́ ìṣọ́ líle, Peteru sùn láàrín ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n dè éÌṣe 12:4, Ìṣe 12:6
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 12:4Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́.
    Ìṣe 12:6Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà.
  • Ẹ̀wọ̀n bọ́ sílẹ̀, ìlẹ̀kùn irin sì ṣí fúnra rẹ̀Ìṣe 12:7, Ìṣe 12:10
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 12:7Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru.
    Ìṣe 12:10Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ èkínní àti èkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tìkára rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
  • Ní Filipi: túbú inú lọ́hùn, a sì kan àbà mọ́ wọn lẹ́sẹ̀Ìṣe 16:23–24
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 16:23–24Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára. Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n sínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́sẹ̀.
  • Ní ọ̀gànjọ́, ilẹ̀ mímì ṣí àwọn ìlẹ̀kùn, ìdè gbogbo wọn sì túÌṣe 16:25–26
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 16:25–26Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run, àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn. Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀.
  • Ní Jerusalẹmu, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè PauluÌṣe 21:33
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 21:33Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe.
  • Feliksi fi Paulu sílẹ̀ nínú túbú fún ọdún méjìÌṣe 24:27
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 24:27Lẹ́yìn ọdún méjì, Porkiu Festu rọ́pò Feliksi, Feliksi sì ń fẹ́ ṣe ojúrere fún àwọn Júù, ó fi Paulu sílẹ̀ nínú túbú.
  • Ní Romu, Paulu ń dágbé pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ń ṣọ́ ọ, a sì fi ẹ̀wọ̀n dè éÌṣe 28:16, Ìṣe 28:20
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 28:16Nígbà tí a sì dé Romu, olórí àwọn ọmọ-ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n wọ́n gba Paulu láààyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń ṣọ́ ọ.
    Ìṣe 28:20Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Israẹli ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí.”
  • Ó gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ fún ọdún méjì gbákoÌṣe 28:30
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 28:30Paulu sì gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ lọ́dún méjì gbáko, ó sì ń gbà gbogbo àwọn tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá.
  • Ẹ̀wọ̀n Paulu kò ti Onesiforu lójú2Tm 1:16
    Àwọn ẹsẹ
    2Tm 1:16Kí Olúwa fi àánú fún ilé Onesiforu; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú.

Ẹ̀wọ̀n wúrà

  • Farao fi ẹ̀gbà sí Josẹfu lọ́rùnGẹ 41:42
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 41:42Farao sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Josẹfu ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn.
  • Belṣassari pàṣẹ kí a fi ẹ̀gbà wúrà sí Daniẹli lọ́rùnDa 5:29
    Àwọn ẹsẹ
    Da 5:29Nígbà náà ni Belṣassari pàṣẹ pé kí a wọ Daniẹli ní aṣọ elése àlùkò, kí a sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, a sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí kẹta ní ìjọba rẹ̀.
  • Gideoni kó àwọn ẹ̀wọ̀n ọrùn àwọn ìbákasẹ MidianiOn 8:26
    Àwọn ẹsẹ
    On 8:26Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó béèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán (1,700) ìwọ̀n ṣékélì, láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ elése àlùkò tí àwọn ọba Midiani ń wọ̀ tàbí àwọn ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn.
  • Solomoni tan ẹ̀wọ̀n wúrà sí iwájú ibi mímọ́ jùlọ1Ọb 6:21
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 6:21Solomoni sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.