Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Àwọn Nasiri àti ẹ̀jẹ́ wọn

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Àwọn Nasiri àti ẹ̀jẹ́ wọn nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (27), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

Nínú Òfin

  • Ọkùnrin tàbí obìnrin lè jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì ti NasiriNu 6:2
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì, ẹ̀jẹ́ ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ sí Olúwa nípa àìgé irun orí (Nasiri),
  • Kò sí wáìnì, ọtí líle, ọtí kíkan, omi èso àjàrà, èso àjàrà tútù tàbí gbígbẹNu 6:3
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:3irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èso àjàrà tútù tàbí gbígbẹ.
  • Kò sí ohunkóhun láti ara àjàrà, kódà kóró tàbí èèpo rẹ̀Nu 6:4
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:4Níwọ́n ìgbà tí ó sì jẹ́ Nasiri, ní kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi èso àjàrà ṣe, ìbá à ṣe kóró tàbí èèpo rẹ̀.
  • Abẹ kò gbọdọ̀ kan orí: irun rẹ̀ gbọdọ̀ gùnNu 6:5
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:5“ ‘Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí. Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa yóò fi pé; ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn.
  • Kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú, kódà ti baba tàbí ìyá rẹ̀Nu 6:6–7
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:6–7“ ‘Ní gbogbo àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Olúwa kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú ènìyàn. Ìbá à ṣe òkú baba, àti ìyá rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí àbúrò rẹ̀, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí wọn, nítorí pé àmì ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run wà ní orí rẹ̀.
  • Bí ẹnìkan bá kú lójijì lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀: kí ó fá orí rẹ̀ ní ọjọ́ kejeNu 6:9
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:9“ ‘Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́; ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje.
  • Ní ọjọ́ kẹjọ: àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjìNu 6:10
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:10Ní ọjọ́ kẹjọ, yóò mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé méjì wá sọ́dọ̀ àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
  • A kò ka àwọn ọjọ́ ti tẹ́lẹ̀; ẹ̀jẹ́ náà tún bẹ̀rẹ̀Nu 6:12
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:12Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí Olúwa fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.
  • Ní òpin rẹ̀: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, abo ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti àkàrà aláìwúNu 6:13–15
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:13–15“ ‘Èyí ni òfin fún Nasiri nígbà tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé. Wọn ó mu wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún Olúwa, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọrọ-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu, apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà ṣe, àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun dáradára pò mọ́ òróró àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi òróró sọjọ̀ lé lórí.
  • Nasiri fá orí rẹ̀, ó sì fi irun náà sínú ináNu 6:18
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:18“ ‘Nígbà náà ni Nasiri náà yóò fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Yóò fi irun náà sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ àlàáfíà.
  • Lẹ́yìn èyí, Nasiri lè mu wáìnìNu 6:20
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:20Àlùfáà yóò fi gbogbo rẹ̀ níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, wọ́n jẹ́ mímọ́, wọ́n sì jẹ́ ti àlùfáà pẹ̀lú igẹ̀ tí a fì àti itan tí wọ́n mú wá. Lẹ́yìn èyí, Nasiri náà lè mu wáìnì.

Àwọn Nasiri tí a dárúkọ

  • Ìyá Samsoni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí jẹ ohun aláìmọ́ kankanOn 13:4, On 13:7, On 13:14
    Àwọn ẹsẹ
    On 13:4Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan,
    On 13:7Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má ṣe jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Nasiri Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ”
    On 13:14kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èso àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pàṣẹ fún un.”
  • Samsoni yóò jẹ́ Nasiri láti inú ìyá rẹ̀; abẹ kò gbọdọ̀ kan orí rẹ̀On 13:5
    Àwọn ẹsẹ
    On 13:5nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má ṣe fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Filistini.”
  • Samsoni: ‘Abẹ kò tí ì kan orí mi rí’On 16:17
    Àwọn ẹsẹ
    On 16:17Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un. Ó ní, “Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá. Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòókù.”
  • Dẹlila mú kí a fá irun orí rẹ̀On 16:19
    Àwọn ẹsẹ
    On 16:19Òun sì mú kí Samsoni sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀. Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.
  • Hana jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé abẹ kì yóò kan orí ọmọ rẹ̀ láé1Sa 1:11
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 1:11Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ wí pé, “ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”
  • Johanu Onítẹ̀bọmi kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líleLk 1:15, Lk 7:33
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 1:15Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá.
    Lk 7:33Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí wáìnì, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’
  • Amosi: a gbé Nasiri dìde nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín, ṣùgbọ́n ẹ fún wọn ní ọtí muAm 2:11–12
    Àwọn ẹsẹ
    Am 2:11–12“Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?” ni Olúwa wí. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀.

Ẹ̀jẹ́ nínú Ìṣe àwọn Aposteli

  • Paulu fá orí rẹ̀ ní Kenkerea nítorí ẹ̀jẹ́ kanÌṣe 18:18
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 18:18Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea, nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́.
  • Paulu san owó fún ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fá irun orí wọnÌṣe 21:23–24, Ìṣe 21:26
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 21:23–24Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe, àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́. Àwọn ni kí ìwọ mú, kí o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkára rẹ ń rìn déédé, ìwọ sì ń pa òfin Mose mọ́.
    Ìṣe 21:26Nígbà náà ni Paulu mú àwọn ọkùnrin náà; ní ọjọ́ kejì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹmpili lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olúkúlùkù wọn.

Àwọn ọmọ Rekabu

  • Àwọn ọmọ Rekabu kò mu ọtí wáìnì, bí Jonadabu baba ńlá wọn ti pàṣẹJr 35:6, Jr 35:14
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 35:6Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jonadabu ọmọ Rekabu, baba wa pàṣẹ fún wa pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé.
    Jr 35:14‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.
  • Wọn kò kọ́ ilé, wọn kò fúnrúgbìn, wọ́n sì ń gbé inú àgọ́Jr 35:7
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 35:7Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbi tí ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.