Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Iyọ̀

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Iyọ̀ nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (21), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀Gẹ 19:26
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 19:26Ṣùgbọ́n aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀.
  • A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn láìsí iyọ̀?Jb 6:6
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 6:6A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀, tàbí adùn ha wà nínú funfun ẹyin?
  • Eliṣa da iyọ̀ sínú orísun omi Jeriko2Ọb 2:20–21
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 2:20–21Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un. Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà sá.’ ”
  • Abimeleki wó Ṣekemu palẹ̀, ó sì fọ́n iyọ̀ sí iOn 9:45
    Àwọn ẹsẹ
    On 9:45Ní gbogbo ọjọ́ náà ni Abimeleki fi bá àwọn ará ìlú náà jà, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa àwọn ènìyàn ìlú náà ó wó ìlú náà palẹ̀ pátápátá ó sì fọ́n iyọ̀ sí i.
  • A máa ń fi iyọ̀ pa ọmọ tuntun láraEl 16:4
    Àwọn ẹsẹ
    El 16:4Ní ọjọ́ tí a bí ọ, a kò gé okùn ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fi omi wẹ̀ ọ́ láti mú kí o mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára rárá, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi aṣọ wé ọ.
  • Ọba Persia fi iyọ̀ fún ilé Ọlọ́run láìní òṣùwọ̀nEsr 6:9, Esr 7:22
    Àwọn ẹsẹ
    Esr 6:9Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn ọ̀dọ́ akọ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, bí àwọn àlùfáà ní Jerusalẹmu ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láìyẹ̀.
    Esr 7:22tó ọgọ́rùn-ún kan tálẹ́ǹtì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òsùwọ̀n àlìkámà, àti dé ọgọ́rùn-ún bati ọtí wáìnì, àti dé ọgọ́rùn-ún bati òróró olifi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀.

Nínú ìsìn

  • A fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ohun jíjẹLe 2:13
    Àwọn ẹsẹ
    Le 2:13Ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ yín. Ẹ má ṣe aláìfi iyọ̀ májẹ̀mú Ọlọ́run yín sínú àwọn ọrẹ ohun jíjẹ yín, ẹ fi iyọ̀ sí gbogbo ọrẹ yín.
  • Àwọn àlùfáà ń wọ́n iyọ̀ sórí ẹbọ sísunEl 43:24
    Àwọn ẹsẹ
    El 43:24Ìwọ yóò mú wọn lọ sí iwájú Olúwa, àwọn àlùfáà ni yóò fi iyọ̀ wọ́n wọn, wọn yóò sì fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí Olúwa.
  • Májẹ̀mú iyọ̀Nu 18:19, 2Kro 13:5
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 18:19Ohunkóhun tí a bá ti yà sọ́tọ̀ nínú ọrẹ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n mú wá fún Olúwa ni mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe déédé. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀ láéláé níwájú Olúwa fún ìwọ àti ọmọ rẹ.”
    2Kro 13:5Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti fún Dafidi àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?

Àwọn ibi

  • Òkun Iyọ̀, ààlà ìlà-oòrùn IsraẹliGẹ 14:3, Nu 34:12, Joṣ 15:2
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 14:3Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí àfonífojì Siddimu (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀).
    Nu 34:12Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun Iyọ̀. “ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”
    Joṣ 15:2Ààlà wọn ní ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúúsù Òkun Iyọ̀,
  • Ìlú Iyọ̀ ní aginjù JudaJoṣ 15:62
    Àwọn ẹsẹ
    Joṣ 15:62Nibṣani, Ìlú Iyọ̀ àti En-Gedi: ìlú mẹ́fà àti ìletò wọn.
  • Ogun pẹ̀lú Edomu ní àfonífojì Iyọ̀2Sa 8:13, 2Ọb 14:7
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 8:13Dafidi sì ní òkìkí gidigidi nígbà tí ó padà wá ilé láti ibi pípa àwọn ará Siria ní àfonífojì Iyọ̀, àwọn tí o pa jẹ́ ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ènìyàn.
    2Ọb 14:7Òun ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ará Edomu ní àfonífojì iyọ̀, ó sì fi agbára mú Sela nínú ogun, tí ó ń pè é ní Jokteeli, orúkọ tí ó ní títí di òní.

Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n

  • Iyọ̀ tí ó di òbu kò wúlò fún ohunkóhun mọ́Mt 5:13, Lk 14:34
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 5:13“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
    Lk 14:34“Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kín ni a ó fi mú un dùn?
  • Ẹ ní iyọ̀ nínú ara yín, kí ẹ sì máa gbé ní àlàáfíàMk 9:50
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 9:50“Iyọ̀ dára, ṣùgbọ́n tí ó bá sọ adùn rẹ̀ nù, báwo ni ẹ ṣè lè padà mú un dùn? Ẹ ni iyọ̀ nínú ara yín, ki ẹ sì máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.”
  • Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́, kí a fi iyọ̀ dùn únKl 4:6
    Àwọn ẹsẹ
    Kl 4:6Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.