Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Orúkọ tuntun

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Orúkọ tuntun nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (16), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Orúkọ rere sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ lọÒw 22:1
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 22:1Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.

Àpẹẹrẹ

  • Abramu di AbrahamuGẹ 17:5
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 17:5A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Abramu mọ́, bí kò ṣe Abrahamu, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.
  • Sarai di SaraGẹ 17:15
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 17:15Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Sarai mọ́, bí kò ṣe Sara.
  • Jakọbu di IsraẹliGẹ 32:28
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 32:28Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”
  • Rakeli pe ọmọ rẹ̀ ní Bene-Oni; baba rẹ̀ pè é ní BenjaminiGẹ 35:18
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 35:18Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi, torí pé ó ń kú lọ, ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bene-Oni, ọmọ ìpọ́njú. Ṣùgbọ́n Jakọbu sọ ọmọ náà ní Benjamini, ọmọ oókan àyà mi.
  • Farao sọ Josẹfu ní Safenati-PaneaGẹ 41:45
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 41:45Farao sì sọ Josẹfu ní orúkọ yìí Safenati-Panea (èyí tí ó túmọ̀ sí ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà). Ó sì fun un ní Asenati ọmọ Potifẹra, alábojútó òrìṣà Oni, gẹ́gẹ́ bí aya. Josẹfu sì rin gbogbo ilẹ̀ Ejibiti já.
  • Mose sọ Hosea ọmọ Nuni ní JoṣuaNu 13:16
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 13:16Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)
  • Naomi: ẹ má ṣe pè mí ní Naomi, ẹ pè mí ní MaraRu 1:20
    Àwọn ẹsẹ
    Ru 1:20Naomi sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Naomi mọ́, ẹ pè mí ní Mara, nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò.
  • A tún pe Solomoni ní Jedidiah2Sa 12:24–25
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 12:24–25Dafidi sì ṣìpẹ̀ fún Batṣeba aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀, òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dafidi sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Solomoni, Olúwa sì fẹ́ ẹ. Ó sì rán Natani wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jedidiah, nítorí Olúwa.
  • Farao Neko yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu2Ọb 23:34
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 23:34Farao Neko ṣe Eliakimu ọmọ Josiah ní ọba ní ipò baba rẹ̀ Josiah. Ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu. Ṣùgbọ́n ó mú Jehoahasi, ó sì gbé e lọ sí Ejibiti, níbẹ̀ ni ó sì kú.
  • Ọba Babeli yí orúkọ Mattaniah padà sí Sedekiah2Ọb 24:17
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 24:17Ọba Babeli sì mú Mattaniah arákùnrin baba Jehoiakini, jẹ ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekiah.
  • Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli, Asariah: Belteṣassari, Ṣadraki, Meṣaki, AbednegoDa 1:7
    Àwọn ẹsẹ
    Da 1:7Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun: Ó fún Daniẹli ní Belteṣassari, ó fún Hananiah ní Ṣadraki, ó fún Miṣaeli ní Meṣaki àti Asariah ní Abednego.
  • A pe Simoni ní Kefa, èyí ni PeteruJh 1:42
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 1:42Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu. Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).
  • A pe Jakọbu àti Johanu ní Boanaji, àwọn ọmọ àráMk 3:17
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 3:17Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí “àwọn ọmọ àrá”).
  • A pe Josẹfu ará Saipurọsi ní Barnaba, ọmọ ìtùnúÌṣe 4:36
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 4:36Àti Josẹfu, tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli sọ àpèlé rẹ̀ ní Barnaba (ìtumọ̀ èyí tí ń jẹ ọmọ ìtùnú), ẹ̀yà Lefi, àti ará Saipurọsi.
  • Saulu, tí a tún ń pè ní PauluÌṣe 13:9
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 13:9Ṣùgbọ́n Saulu ti a ń pè ni Paulu, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Elimu, ó sì wí pé,

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.