Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ọkọ̀ ojú omi àti ìrìnàjò lójú omi

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Ọkọ̀ ojú omi àti ìrìnàjò lójú omi nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (31), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Ọkọ̀ Noa: igi ọ̀mọ̀, pẹ̀lú yàrá, a fi ọ̀dà rẹ́ ẹGẹ 6:14–15
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 6:14–15Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn. Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún (300) ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́.
  • Solomoni kan àwọn ọkọ̀ ní Esioni-Geberi létí Òkun Pupa1Ọb 9:26
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 9:26Solomoni ọba sì túnṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Geberi, tí ó wà ní ẹ̀bá Elati ní Edomu, létí Òkun Pupa.
  • Àwọn atukọ̀ Hiramu mú tálẹ́ǹtì wúrà 450 wá láti Ofiri2Kro 8:18
    Àwọn ẹsẹ
    2Kro 8:18Hiramu sì fi ọ̀kọ̀ ránṣẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye Òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Solomoni, lọ sí Ofiri wọ́n sì gbé àádọ́ta lé ní irinwó (450) tálẹ́ǹtì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Solomoni wá.
  • Ní ọdún mẹ́ta-mẹ́ta: wúrà, fàdákà, eyín erin, ìnàkí àti ẹyẹ-ológe1Ọb 10:22
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 10:22Ọba sì ní ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹ̀lú ọkọ̀ Hiramu ní Òkun. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ọkọ̀ Tarṣiṣi ń dé, tí ó ń mú wúrà àti fàdákà, eyín erin àti ìnàkí àti ẹyẹ-ológe wá.
  • Àwọn ọkọ̀ Jehoṣafati fọ́ kí wọ́n tó ṣíkọ̀ rárá1Ọb 22:48, 2Kro 20:36–37
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 22:48Jehoṣafati kan ọkọ̀ Tarṣiṣi láti lọ sí Ofiri fún wúrà, ṣùgbọ́n wọn kò lọ, nítorí àwọn ọkọ̀ náà fọ́ ní Esioni-Geberi.
    2Kro 20:36–37Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan ọkọ̀ láti lọ sí Tarṣiṣi, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Esioni-Geberi. Elieseri ọmọ Dodafahu ti Meraṣa sọtẹ́lẹ̀ sí Jehoṣafati, wí pe, “Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, Olúwa yóò pa ohun ti ìwọ ti ṣe run.” Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà.
  • Esekiẹli ṣàpèjúwe Tire bí ọkọ̀ ti igi junifa, kedari, óákù àti aṣọ ọ̀gbọ̀El 27:5–7
    Àwọn ẹsẹ
    El 27:5–7Wọn ṣe gbogbo pákó rẹ ní igi junifa láti Seniri; wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wá láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ. Nínú igi óákù ti Baṣani ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ ọ̀pá rẹ̀; ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú igi bokisi láti erékùṣù Kittimu wá. Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ; aṣọ aláró àti elése àlùkò láti erékùṣù ti Eliṣa ni èyí tí a fi bò ó.
  • Ọkọ̀ eèsún papirusi ń gbé àwọn ikọ̀ lójú omiIsa 18:2
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 18:2tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe. Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára, sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀, sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri, orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè, tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.
  • Ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí ọkọ̀ ńláJk 3:4
    Àwọn ẹsẹ
    Jk 3:4Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀.
  • Ipa ọkọ̀ lójú agbami Òkun: ó ya Aguri lẹ́nuÒw 30:18–19
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 30:18–19“Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi, ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.

Ìrìnàjò

  • Jona sanwó ọkọ̀ tí ń lọ sí TarṣiṣiJon 1:3
    Àwọn ẹsẹ
    Jon 1:3Ṣùgbọ́n Jona dìde kúrò láti sálọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Joppa, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tarṣiṣi: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa.
  • Nínú ìjì, àwọn atukọ̀ kó ẹrù dà sínú ÒkunJon 1:4–5
    Àwọn ẹsẹ
    Jon 1:4–5Nígbà náà ni Olúwa rán ìjì ńlá jáde sí ojú Òkun, ìjì líle sì wà nínú Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́. Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú Òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́. Ṣùgbọ́n Jona sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra.
  • Wọ́n gbìyànjú láti wà ọkọ̀ dé ilẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe éJon 1:13
    Àwọn ẹsẹ
    Jon 1:13Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn.
  • Jesu kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ SimoniLk 5:2–3
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 5:2–3Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà.
  • Jesu sùn lórí ìrọ̀rí ní ìdí ọkọ̀ nígbà ìjìMk 4:37–38
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 4:37–38Ìjì líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì. Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?”
  • Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń wa ọkọ̀ pẹ̀lú wàhálà nítorí ìjì líleMk 6:48
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 6:48Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá,
  • Ọkọ̀ Paulu rì ní ìgbà mẹ́ta, ó sì wà nínú ibú fún ọ̀sán kan àti òru kan2Kọ 11:25
    Àwọn ẹsẹ
    2Kọ 11:25Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú.

Ìrìnàjò Paulu lọ sí Romu

  • Ọkọ̀ Adramittiu kan lẹ́bàá etí Òkun AsiaÌṣe 27:2
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:2Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-òkun Adramittiu kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí Òkun Asia, a ṣíkọ̀: Aristarku, ará Makedonia láti Tẹsalonika wà pẹ̀lú wa.
  • Ìrìnàjò lójú omi léwu lẹ́yìn àwẹ̀Ìṣe 27:9
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:9Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìnàjò wa sì ti léwu gan an nítorí nísinsin yìí àwẹ̀ ti kọjá lọ, Paulu dá ìmọ̀ràn.
  • Ìjì Eurakuilo dé; wọ́n fi okùn dí ọkọ̀ nísàlẹ̀Ìṣe 27:14, Ìṣe 27:17
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:14Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Eurakuilo fẹ́ lù erékùṣù náà.
    Ìṣe 27:17Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ̀-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrìn dídẹ̀, wọn fi ìgbokùn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ń gbá wa kiri.
  • Wọ́n kó ẹrù, lẹ́yìn náà ohun èlò ọkọ̀, dà sínú omiÌṣe 27:18–19
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:18–19Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ọjọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀. Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun èlò ọkọ̀ dànù.
  • Wíwọ̀n jíjìn omi: omi ń dín kùÌṣe 27:28
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:28Nígbà tí wọ́n sì wọn Òkun, wọ́n rí i ó jì ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún síwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn Òkun, wọn rí i pé ó jì ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.
  • Wọ́n sọ ìdákọ̀ró mẹ́rin sílẹ̀ ní ìdí ọkọ̀Ìṣe 27:29
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:29Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ró mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí ọkọ̀, wọ́n ń retí ojúmọ́.
  • Àwọn atukọ̀ fẹ́ sá nínú ọkọ̀ kékeré; àwọn ọmọ-ogun gé okùn rẹ̀Ìṣe 27:30, Ìṣe 27:32
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:30Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ àwọn ọkọ̀ kéékèèké kalẹ̀ sí ojú Òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀.
    Ìṣe 27:32Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gé okùn àwọn ọkọ̀ kéékèèké, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣubú sọ́hùn-ún.
  • Ènìyàn 276 ni ó wà nínú ọkọ̀Ìṣe 27:37
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:37Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-òkun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó dín mẹ́rin (276).
  • Wọ́n kó alikama dà sínú omi láti mú ọkọ̀ fúyẹ́Ìṣe 27:38
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:38Nígbà tí wọn jẹun yó tan, wọn bẹ̀rẹ̀ sí mu ọkọ̀-òkun náà fúyẹ́, nípa kíkó alikama dà sí omi.
  • Ọkọ̀ gúnlẹ̀, ìdí ọkọ̀ sì fọ́Ìṣe 27:41
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:41Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí Òkun méjì pàdé, wọn fi orí ọkọ̀ sọlẹ̀: iwájú rẹ̀ sì kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin, ó dúró, kò lè yí, ṣùgbọ́n agbára rírú omi bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ìdí ọkọ̀ náà.
  • Gbogbo wọn dé ilẹ̀, àwọn kan lórí pátákóÌṣe 27:44
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:44Àti àwọn ìyókù, òmíràn lórí pátákó, àti òmíràn lórí àwọn igi tí ó ya kúrò lára ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe tí gbogbo wọn yọ, ní àlàáfíà dé ilẹ̀.
  • Sí Romu nínú ọkọ̀ Alekisandiria tí àmì rẹ̀ jẹ́ ìbejìÌṣe 28:11
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 28:11Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú omi kan èyí tí ó lo àkókò òtútù ní erékùṣù náà. Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú omi ti Alekisandiria, èyí tí àmì rẹ̀ jẹ́ tí òrìṣà ìbejì ti Kasitoru òun Polukisu.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.