Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Kọ́kọ́rọ́, èdìdì àti òrùka èdìdì

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Kọ́kọ́rọ́, èdìdì àti òrùka èdìdì nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (27), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

Kọ́kọ́rọ́ àti ìdábùú

  • Ehudu ti ìlẹ̀kùn yàrá òkè Egloni ọba lẹ́yìn rẹ̀On 3:23
    Àwọn ẹsẹ
    On 3:23Ehudu ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.
  • Àwọn ìránṣẹ́ dúró, lẹ́yìn náà wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùnOn 3:24–25
    Àwọn ẹsẹ
    On 3:24–25Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ìlẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.” Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyanu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.
  • Àwọn ọmọ Lefi ń ṣọ́ ilé Ọlọ́run ní òru, wọ́n sì ń ṣí i ní àràárọ̀1Kro 9:27
    Àwọn ẹsẹ
    1Kro 9:27Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ, wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.
  • A tún àwọn ibodè Jerusalẹmu kọ́ pẹ̀lú ìlẹ̀kùn, ìdábùú àti ìdèNe 3:3
    Àwọn ẹsẹ
    Ne 3:3Àwọn ọkùnrin Senaa ni wọ́n mọ ibodè ẹja. Wọ́n kún ọ̀pọ̀ ìgbéró rẹ̀, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn rẹ̀, ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè e rẹ̀ sí ààyè e wọn.

Èdìdì àti òrùka èdìdì

  • Juda fi èdìdì, okùn àti ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ Tamari ní ẹ̀ríGẹ 38:18
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 38:18Juda sì bi í pé, “Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ?” Ó sì dáhùn pé, “Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.” Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípasẹ̀ rẹ̀.
  • Tamari: ‘bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí’Gẹ 38:25
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 38:25Bí wọ́n sì ti ń mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó fún mi lóyún. Wò ó, bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí.”
  • Farao fi òrùka èdìdì rẹ̀ wọ Josẹfu lọ́wọ́Gẹ 41:42
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 41:42Farao sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Josẹfu ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn.
  • Jesebeli kọ̀wé ní orúkọ Ahabu, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í1Ọb 21:8
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 21:8Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Ahabu, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbàgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Naboti pẹ̀lú rẹ̀.
  • Ahaswerusi fi òrùka èdìdì rẹ̀ fún HamaniEt 3:10
    Àwọn ẹsẹ
    Et 3:10Nítorí náà, ọba sì bọ́ òrùka èdìdì tí ó wà ní ìka rẹ̀, ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù.
  • A kọ àṣẹ Hamani ní orúkọ ọba, a sì fi òrùka náà ṣe èdìdì rẹ̀Et 3:12
    Àwọn ẹsẹ
    Et 3:12Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnra rẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀.
  • A gba òrùka náà lọ́wọ́ Hamani, a sì fi fún MordekaiEt 8:2
    Àwọn ẹsẹ
    Et 8:2Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ Hamani ó sì fi fún Mordekai, Esteri sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí ilé e Hamani.
  • Àṣẹ tí a fi òrùka ọba ṣe èdìdì rẹ̀ kò ṣe é yí padàEt 8:8
    Àwọn ẹsẹ
    Et 8:8Nísinsin yìí, kọ ìwé àṣẹ mìíràn ní orúkọ ọba bí àwọn Júù ṣe jẹ́ pàtàkì sí ọ, kí o sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì dì í, nítorí kò sí àkọsílẹ̀ tí a bá ti kọ ní orúkọ ọba tí a sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì tí a lè yìí padà.”
  • Mordekai fi èdìdì di àwọn lẹ́tà, ó sì rán wọn láti ọwọ́ àwọn tí ń gun ẹṣinEt 8:10
    Àwọn ẹsẹ
    Et 8:10Mordekai sì fi àṣẹ ọba Ahaswerusi kọ̀wé, ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀, ó rán an lọ ní kíákíá, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ ayaba, tiwọn yára bí àṣà àwọn tí wọ́n ń gun ẹṣin tí ó yára, ní pàtàkì èyí tí a ń bọ́ fún ọba.
  • A fi òrùka ọba àti ti àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ṣe èdìdì ihò kìnnìúnDa 6:17
    Àwọn ẹsẹ
    Da 6:17A sì gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà, ọba sì dì í pa pẹ̀lú òrùka èdìdì rẹ̀ àti pẹ̀lú òrùka àwọn ọlọ́lá rẹ̀, nítorí kí a má ṣe yí ohunkóhun padà nítorí i Daniẹli.
  • Àdéhùn tí a kọ sínú ìwé, tí àwọn olórí, ọmọ Lefi àti àlùfáà fi èdìdì dìNe 9:38, Ne 10:1
    Àwọn ẹsẹ
    Ne 9:38“Nítorí gbogbo èyí, a ń ṣe àdéhùn tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé, àwọn olórí ọmọ Lefi àwọn àlùfáà sì fi èdìdì dì í.”
    Ne 10:1Àwọn tí ó fi èdìdì dì í ni: Nehemiah baálẹ̀, ọmọ Hakaliah. Sedekiah
  • Jeremiah fọwọ́ sí ìwé ìrà, ó sì lẹ̀ ẹ́: ẹ̀dà kan ní lílẹ̀, ọ̀kan ní ṣíṣíJr 32:10–11
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 32:10–11Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí sí i, mo sì wọn fàdákà náà lórí òsùwọ̀n. Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀.
  • A gbé àwọn ìwé náà sínú ìkòkò amọ̀ kí wọ́n lè wà fún ọjọ́ púpọ̀Jr 32:14
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 32:14èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀.
  • A ṣé òkúta ibojì Jesu dáradára, a sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀Mt 27:66
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 27:66Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáradára. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.

Fínfín bí èdìdì

  • Òkúta óníkìsì méjì tí a fín orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sí bí èdìdìEk 28:9, Ek 28:11, Ek 39:6
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 28:9“Ìwọ yóò sì mú òkúta óníkìsì méjì, ìwọ yóò sì fín orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sára wọn.
    Ek 28:11Iṣẹ́ ọnà òkúta fínfín, bí ìfín èdìdì àmì, ni ìwọ yóò fún òkúta méjèèjì gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli: ìwọ yóò sì dè wọ́n sí ojú ìdè wúrà.
    Ek 39:6Ó ṣiṣẹ́ òkúta óníkìsì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Israẹli.
  • Òkúta méjìlá ìgbàyà, ọ̀kọ̀ọ̀kan tí a fín orúkọ ẹ̀yà kan sí bí èdìdìEk 28:21, Ek 39:14
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 28:21Òkúta méjìlá yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli olúkúlùkù èdìdì àmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Israẹli méjìlá.
    Ek 39:14Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá, ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.
  • Àwo wúrà tí a fín sí bí èdìdì: MÍMỌ́ SÍ OLÚWAEk 28:36, Ek 39:30
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 28:36“Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fínfín èdìdì àmì pé. Mímọ́ sí Olúwa.
    Ek 39:30Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì: Mímọ́ sí Olúwa.
  • Ọ̀rọ̀ inú Orin Solomoni: ‘Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì’Orin 8:6
    Àwọn ẹsẹ
    Orin 8:6Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.