Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ọjọ́ ìbí

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Ọjọ́ ìbí nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (8), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Ní ọjọ́ ìbí Farao, ó se àsè fún àwọn ìjòyè rẹ̀Gẹ 40:20
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 40:20Ọjọ́ kẹta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Farao, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n.
  • Ní ọjọ́ náà ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò rẹ̀, ó sì so olórí alásè kọ́Gẹ 40:21–22
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 40:21–22Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa fi ago lé Farao ní ọwọ́, ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti sọ fún wọn nínú ìtumọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn.
  • Ní ọjọ́ ìbí Herodu, ó se àsè fún àwọn ènìyàn pàtàkì GaliliMk 6:21
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 6:21Níkẹyìn Herodia rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Herodu, òun sì pèsè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn ènìyàn pàtàkì ní Galili.
  • Ọmọbìnrin Herodia jó, ó sì béèrè orí JohanuMt 14:6–8
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 14:6–8Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi. Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”.
  • Jobu fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ réJb 3:1–3
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 3:1–3Ẹ̀yìn èyí ní Jobu yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré Jobu sọ, ó sì wí pé, “Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé, àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A lóyún ọmọkùnrin kan!’
  • Jeremiah: ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí miJr 20:14, Jr 20:18
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 20:14Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.
    Jr 20:18Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn, láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀ àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?
  • Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ, ọjọ́ ikú sì ju ọjọ́ ìbí lọSu 7:1
    Àwọn ẹsẹ
    Su 7:1Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.