Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ìràwọ̀

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Ìràwọ̀ nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (21), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá méjì, ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lúGẹ 1:16
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 1:16Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú.
  • A sọ fún Abrahamu pé kí ó ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá lè kà wọ́nGẹ 15:5
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 15:5Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”
  • Irú-ọmọ tí ó pọ̀ bí ìràwọ̀ àti bí iyanrìnGẹ 22:17, De 1:10
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 22:17nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn,
    De 1:10Olúwa Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run.
  • Ó ka iye àwọn ìràwọ̀, ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan ní orúkọSm 147:4
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 147:4Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ.
  • Ìràwọ̀ yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ní ògo1Kọ 15:41
    Àwọn ẹsẹ
    1Kọ 15:41Ọ̀tọ̀ ni ògo ti oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.
  • Josẹfu lá àlá ìràwọ̀ mọ́kànlá tí ń foríbalẹ̀Gẹ 37:9
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 37:9O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń foríbalẹ̀ fún mi.”
  • Láti inú ipa ọ̀nà wọn ni àwọn ìràwọ̀ bá Sisera jàOn 5:20
    Àwọn ẹsẹ
    On 5:20Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá láti inú ipa ọ̀nà wọn ni wọ́n bá Sisera jà.
  • Àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀Jb 38:7
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 38:7nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?
  • Àwọn amòye rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrùnMt 2:2
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 2:2Wọ́n si béèrè pé, “Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà? Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrùn, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un.”
  • Ìràwọ̀ náà ṣáájú wọn, ó sì dúró lókè ibẹ̀Mt 2:9–10
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 2:9–10Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà. Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn.
  • Dafidi kò ka àwọn tí kò tó ogún ọdún: Israẹli yóò dàbí ìràwọ̀1Kro 27:23
    Àwọn ẹsẹ
    1Kro 27:23Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí Olúwa ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

Àwọn ìràwọ̀ tí a dárúkọ

  • Beari, Orioni, Pleiadesi àti àwọn ìràwọ̀ gúúsùJb 9:9
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 9:9Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari àti Orioni, Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù.
  • Ìwọ ha lè de Pleiadesi tàbí tú ìràwọ̀ Orioni?Jb 38:31–32
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 38:31–32“Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára? Tàbí ìwọ le tún di ìràwọ̀ Orioni? Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn? Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
  • Amosi: ó dá Pleiadesi àti OrioniAm 5:8
    Àwọn ẹsẹ
    Am 5:8Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀ tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀ ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀ tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ Olúwa ni orúkọ rẹ̀,

Bíbọ ìràwọ̀

  • A sọ fún Israẹli pé kí wọ́n má ṣe foríbalẹ̀ fún oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀De 4:19
    Àwọn ẹsẹ
    De 4:19Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ dé bi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run.
  • Israẹli àti Ọba Manase tẹrí ba fún gbogbo ogun ọ̀run2Ọb 17:16, 2Ọb 21:3
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 17:16Wọ́n kọ̀ gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n sì ṣe òrìṣà méjì fún ara wọn, wọ́n sì gbẹ́ ẹ ọ̀kan ní ère ẹgbọrọ màlúù, àti ọ̀kan ní ère òrìṣà Aṣerah. Wọ́n sì tẹrí wọn ba sí gbogbo ogun ọ̀run, wọ́n sì sin Baali.
    2Ọb 21:3Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ Baali dìde, ó sì ṣe ère òrìṣà Aṣerah, gẹ́gẹ́ bí Ahabu ọba Israẹli ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.
  • Josiah lé àwọn àlùfáà tí ń sun tùràrí sí àwọn àmì ìràwọ̀ kúrò2Ọb 23:5
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 23:5Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Juda láti sun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Juda àti àwọn tí ó yí Jerusalẹmu ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Baali, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run.
  • Àwọn ènìyàn ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé fún ogun ọ̀runJr 19:13, Sf 1:5
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 19:13Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
    Sf 1:5àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé, àwọn tí ń sin ogun ọ̀run, àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra, tí wọ́n sì ń fi Moleki búra.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.