Ṣàwárí › Àkòrí › Iye náà ogójì
Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu
Iye náà ogójì nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (31), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
Ogójì ọjọ́
- Òjò rọ̀ sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òruGẹ 7:4, Gẹ 7:12, Gẹ 7:17
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 7:4Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.”
Gẹ 7:12Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.
Gẹ 7:17Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i.
- Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa ṣí fèrèsé ọkọ̀Gẹ 8:6
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 8:6Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀.
- Ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú JakọbuGẹ 50:3
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 50:3Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Ejibiti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.
- Mose wà lórí òkè ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òruEk 24:18, Ek 34:28, De 9:9
Àwọn ẹsẹ
Ek 24:18Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.
Ek 34:28Mose wà níbẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru láìjẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.
De 9:9Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba wàláà òkúta, wàláà májẹ̀mú ti Olúwa ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mu omi.
- Àwọn amí padà lẹ́yìn ogójì ọjọ́Nu 13:25
Àwọn ẹsẹ
Nu 13:25Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.
- Goliati jáde wá fún ogójì ọjọ́, ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́1Sa 17:16
Àwọn ẹsẹ
1Sa 17:16Fún ogójì ọjọ́, Filistini wá síwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn.
- Elijah rìn ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru dé Horebu1Ọb 19:8
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 19:8Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run.
- Jona: ogójì ọjọ́ sí i, a ó sì bi Ninefe wóJon 3:4
Àwọn ẹsẹ
Jon 3:4Jona sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ́n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Ninefe wó.”
- Jesu gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òruMt 4:2
Àwọn ẹsẹ
Mt 4:2Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á.
- Lẹ́yìn tí ó jíǹde, Jesu fara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́Ìṣe 1:3
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 1:3Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láààyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run.
Ogójì ọdún
- Israẹli jẹ manna fún ogójì ọdún ní aginjùEk 16:35
Àwọn ẹsẹ
Ek 16:35Àwọn ará Israẹli jẹ manna fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kenaani ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ, wọ́n jẹ manna títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbègbè Kenaani.
- Ogójì ọdún ìrìnkiri, ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi yẹ ilẹ̀ wòNu 14:34
Àwọn ẹsẹ
Nu 14:34Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi.
- Isaaki fẹ́ Rebeka nígbà tí ó di ẹni ogójì ọdúnGẹ 25:20
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 25:20Nígbà tí Isaaki di ọmọ ogójì ọdún ni ó gbé Rebeka ọmọ Betueli ará Aramu ti Padani-Aramu tí í ṣe arábìnrin Labani ará Aramu ní ìyàwó.
- Ní ogójì ọdún Mose bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò; ogójì ọdún lẹ́yìn náà, igbó náàÌṣe 7:23, Ìṣe 7:30
- Lábẹ́ onídàájọ́ mélòó kan, ilẹ̀ náà sinmi fún ogójì ọdúnOn 3:11, On 5:31, On 8:28
Àwọn ẹsẹ
On 3:11Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú.
On 5:31“Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kí ó ṣègbé Olúwa! Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn, nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.” Ilẹ̀ náà sì sinmi ní ogójì ọdún.
On 8:28Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Midiani ba níwájú àwọn ọmọ Israẹli bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbé orí mọ́. Ní ọjọ́ Gideoni, Israẹli wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún.
- Àwọn ará Filistini jọba lórí Israẹli fún ogójì ọdúnOn 13:1
Àwọn ẹsẹ
On 13:1Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Olúwa sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistini lọ́wọ́ fún ogójì ọdún.
- Eli darí Israẹli fún ogójì ọdún1Sa 4:18
Àwọn ẹsẹ
1Sa 4:18Nígbà tí ó dárúkọ àpótí ẹ̀rí Olúwa, Eli sì ṣubú sẹ́yìn kúrò lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ bodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí tí ó jẹ́ arúgbó ọkùnrin, ó sì tóbi, ó ti darí àwọn Israẹli fún ogójì ọdún.
- Ogójì ọdún lábẹ́ Saulu, ni Paulu wíÌṣe 13:21
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 13:21Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì béèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, ọkùnrin kan nínú ẹ̀yà Benjamini, fún ogójì ọdún.
- Dafidi jọba fún ogójì ọdún: méje ní Hebroni, mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu2Sa 5:4, 1Ọb 2:11
- Solomoni jọba fún ogójì ọdún1Ọb 11:42
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 11:42Solomoni sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo Israẹli ní ogójì ọdún.
- Jehoaṣi jọba ní Jerusalẹmu fún ogójì ọdún2Ọb 12:1
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 12:1Ní ọdún keje tí Jehu, Jehoaṣi di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Sibia: Ó wá láti Beerṣeba.
Ogójì pàṣán
- Òfin kò gbà ju ogójì pàṣán lọDe 25:3
Àwọn ẹsẹ
De 25:3Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàṣán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.
- Ẹ̀ẹ̀márùn-ún ni Paulu gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan2Kọ 11:24
Àwọn ẹsẹ
2Kọ 11:24Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù.
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.