Ṣàwárí › Àkòrí › Wèrè, ti gidi àti ti ìdíbọ́n
Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu
Wèrè, ti gidi àti ti ìdíbọ́n nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (22), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
- Òwe: ẹlẹ́tàn tí ó wí pé ‘Àwàdà lásán ni mo ń ṣe’ dàbí asínwínÒw 26:18–19
Àwọn ẹsẹ
Òw 26:18–19Bí i asínwín ti ń ju ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”
Dafidi ní Gati
- Bí ó ti ń sá fún Saulu, Dafidi wá sọ́dọ̀ Akiṣi ọba Gati1Sa 21:10
Àwọn ẹsẹ
1Sa 21:10Dafidi sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Saulu, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati.
- Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi mọ̀ ọ́n, ẹ̀rù sì ba Dafidi gidigidi1Sa 21:11–12
Àwọn ẹsẹ
1Sa 21:11–12Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀. Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?” Dafidi sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Akiṣi ọba Gati gidigidi.
- Ó díbọ́n bí aṣiwèrè, ó ń ha ìlẹ̀kùn, itọ́ sì ń ṣàn sí irùngbọ̀n rẹ̀1Sa 21:13
Àwọn ẹsẹ
1Sa 21:13Òun sì pa ìṣe rẹ̀ dà níwájú wọn, ó sì sọ ara rẹ̀ di aṣiwèrè ní ọwọ́ wọn, ó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ ha ìlẹ̀kùn ojú ọ̀nà, ó sì ń wá itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀.
- Akiṣi: ‘Mo ha ni un fi aṣiwèrè ṣe?’1Sa 21:14–15
Àwọn ẹsẹ
1Sa 21:14–15Nígbà náà ni Akiṣi wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wó o, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe mú un tọ̀ mí wá. Mo ha ni un fi aṣiwèrè ṣe? Tí ẹ̀yin fi mú èyí tọ̀ mí wá láti hu ìwà aṣiwèrè níwájú mi? Eléyìí yóò ha wọ inú ilé mi?”
- Àkọlé Saamu 34 rántí rẹ̀: ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrèSm 34:1
Àwọn ẹsẹ
Sm 34:1Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ. Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo; ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
Àwọn mìíràn
- Ẹ̀mí búburú ń yọ Saulu lẹ́nu, dùùrù Dafidi sì ń tù ú lára1Sa 16:14–16, 1Sa 16:23
Àwọn ẹsẹ
1Sa 16:14–16Nísinsin yìí, ẹ̀mí Olúwa ti kúrò lára Saulu, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì ń yọ ọ́ lẹ́nu. Àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu. Jẹ́ kí olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn-ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.”
1Sa 16:23Ó sì ṣe, nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá bá dé sí Saulu, Dafidi a sì fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lára dùùrù: a sì san fún Saulu, ara rẹ̀ a sì dá; ẹ̀mí búburú náà a sì fi sílẹ̀.
- Lẹ́yìn náà, bí Dafidi ti ń ta dùùrù, Saulu ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí i1Sa 18:10–11
Àwọn ẹsẹ
1Sa 18:10–11Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Saulu, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dafidi sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Saulu sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dafidi pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dafidi yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì.
- Nebukadnessari jẹ koríko bí màlúù; irun rẹ̀ gùn bí ìyẹ́ idìDa 4:33
Àwọn ẹsẹ
Da 4:33Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadnessari ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ.
- Iyè rẹ̀ sọjí, a sì dá a padà sórí ìtẹ́ rẹ̀Da 4:34, Da 4:36
Àwọn ẹsẹ
Da 4:34Ní òpin ìgbà náà, èmi, Nebukadnessari gbé ojú mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀gá-ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé. Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé ni ìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran.
Da 4:36Ní àkókò kan náà, iyè mi padà, ọlá àti ògo dídán mi padà tọ̀ mí wá fún ògo ìjọba mi. Àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn ọlọ́lá mi, wá mi rí, wọ́n sì dá mi padà sórí ìjọba mi, mo sì di alágbára ju ti ìṣáájú lọ.
- Olùṣọ́ náà: ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti Jehu, bí ti aṣiwèrè!2Ọb 9:20
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 9:20Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jehu ọmọ Nimṣi, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.”
- Àwọn ìjòyè ẹgbẹ́ Jehu pe wòlíì ọ̀dọ́ náà ní ‘aṣiwèrè’2Ọb 9:11
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 9:11Nígbà tí Jehu jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?” Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jehu fèsì.
- Lẹ́tà kan: aṣiwèrè èyíkéyìí tí ó bá ṣe bí wòlíì ni kí a fi sínú àgòJr 29:26
Àwọn ẹsẹ
Jr 29:26‘ Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jehoiada láti máa jẹ́ alákòóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin.
- Ọkùnrin kan tí ń gbé inú ibojì já ẹ̀wọ̀n rẹ̀, ó sì ń fi òkúta ṣá ara rẹ̀Mk 5:3–5
Àwọn ẹsẹ
Mk 5:3–5Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ibojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é. Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀. Tọ̀sán tòru láàrín àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.
- Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn rí i tí ó wọ aṣọ, tí iyè rẹ̀ sì bọ̀ sípòMk 5:15
Àwọn ẹsẹ
Mk 5:15Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù, tí ó jókòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ ìyè rẹ sì bọ̀ sípò, ẹ̀rù sì bà wọ́n.
- Àwọn ẹbí Jesu wá láti mú un lọ ilé: ‘Orí rẹ̀ ti dàrú’Mk 3:21
Àwọn ẹsẹ
Mk 3:21Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wá láti mú un lọ ilé, nítorí tí wọn wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”
- Àwọn kan wí nípa Jesu pé: ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú’Jh 10:20
Àwọn ẹsẹ
Jh 10:20Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?”
- Roda sọ pé Peteru wà ní ẹnu-ọ̀nà; ‘Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!’Ìṣe 12:13–15
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 12:13–15Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn. Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Peteru, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sísọ pé, Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Angẹli rẹ̀ ni!”
- Festu: ‘Paulu! Orí rẹ dàrú’; Paulu: ‘Orí mi kò dàrú’Ìṣe 26:24–25
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 26:24–25Bí ó sì ti ń sọ tẹnu rẹ̀, Festu wí ní ohùn rara pé, “Paulu! Orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!” Paulu dalóhùn wí pé, “Orí mi kò dàrú, Festu ọlọ́lá jùlọ; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ òye ni èmi ń sọ jáde.
- Paulu: bí gbogbo yín bá ń fi èdè fọ̀, àwọn àjèjì yóò wí pé ẹ̀ ń ṣe òmùgọ̀1Kọ 14:23
Àwọn ẹsẹ
1Kọ 14:23Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fi èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹ̀yin ń ṣe òmùgọ̀?
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.