Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Wákàtí àti ìṣọ́ òru

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Wákàtí àti ìṣọ́ òru nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (49), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • ‘Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní’Gẹ 1:5
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 1:5Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “ọ̀sán,” àti òkùnkùn ní “òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.
  • Jesu: ‘Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí?’Jh 11:9
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 11:9Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí.
  • Ìrìn ọjọ́ kan: Elijah lọ tó bẹ́ẹ̀ sínú aginjù1Ọb 19:4
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 19:4nígbà tí òun tìkára rẹ̀ sì lọ ní ìrìn ọjọ́ kan sí aginjù, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, Olúwa, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ.”
  • Ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan: láti Òkè Olifi dé JerusalẹmuÌṣe 1:12
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 1:12Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerusalẹmu láti orí òkè ti a ń pè ni olifi, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan.
  • Ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́: ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ ìsinmiMk 15:42, Jh 19:31
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 15:42Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí i ṣe, ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú,
    Jh 19:31Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má ba à wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi (nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ ìsinmi náà), nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pilatu pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò.
  • Nehemiah ti àwọn ìlẹ̀kùn nígbà tí òjìji ìrọ̀lẹ́ ń ṣú ṣáájú ọjọ́ ìsinmiNe 13:19
    Àwọn ẹsẹ
    Ne 13:19Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì ṣí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.
  • Òjìji padà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi2Ọb 20:9–11
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 20:9–11Isaiah dáhùn pé, “Èyí ni àmì tí Olúwa fún ọ wí pé Olúwa yóò ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí: kí òjìji lọ síwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, tàbí kí ó padà lọ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?” “Ó jẹ́ ohun ìrọ̀rùn fún òjìji láti lọ síwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá,” Hesekiah wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí ó lọ padà ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.” Nígbà náà wòlíì Isaiah ké pe Olúwa, Olúwa sì ṣe òjìji padà sí ìgbésẹ̀ mẹ́wàá ó ti sọ̀kalẹ̀ ní òpópó ọ̀nà Ahasi.

Àwọn ìṣọ́ òru

  • Ẹkún Jeremiah: ‘kígbe sókè ní àṣálẹ́, bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀’Ẹj 2:19
    Àwọn ẹsẹ
    Ẹj 2:19Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́, bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀ tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi níwájú Olúwa. Gbé ọwọ́ yín sókè sí i nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀ tí ó ń kú lọ nítorí ebi ní gbogbo oríta òpópó.
  • Gideoni dé ibùdó àwọn ará Midiani ní nǹkan bí agogo méjìláOn 7:19
    Àwọn ẹsẹ
    On 7:19Gideoni àti àwọn ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé òpin ibùdó àwọn ará Midiani ní nǹkan bí agogo méjìlá padà. Wọ́n fun fèrè wọn, wọ́n sì tún fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà ní ọwọ́ mọ́lẹ̀.
  • Ní ìṣọ́ òwúrọ̀, ìpayà bá ibùdó àwọn ará EjibitiEk 14:24
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 14:24Ní ìṣọ́ òwúrọ̀ Olúwa bojú wo ogun àwọn ará Ejibiti láàrín ọ̀wọ̀n iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ-ogun Ejibiti.
  • Saulu kọlu ibùdó àwọn ará Ammoni ní ìṣọ́ òwúrọ̀1Sa 11:11
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 11:11Ní ọjọ́ kejì Saulu pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ammoni ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóoru ọjọ́. Àwọn tókù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan.
  • Jesu rìn lórí Òkun ní ìṣọ́ kẹrin òruMt 14:25, Mk 6:48
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 14:25Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi.
    Mk 6:48Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá,
  • Olúwa wọn lè dé ní ìṣọ́ kejì tàbí ìṣọ́ kẹtaLk 12:38
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 12:38Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà.
  • Ní ìrọ̀lẹ́, ní ọ̀gànjọ́ òru, nígbà tí àkùkọ ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀Mk 13:35
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 13:35“Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí ṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò dé. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀.
  • Onísáàmù kan ń ronú ní gbogbo ìṣọ́ òruSm 63:6, Sm 119:148
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 63:6Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
    Sm 119:148Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.

Àwọn wákàtí ọ̀sán

  • Peteru: ‘wákàtí kẹta ọjọ́ sá à ni èyí’Ìṣe 2:15
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 2:15Àwọn wọ̀nyí kò mu ọtí yó, bí ẹ̀yin tí rò ó; wákàtí kẹta ọjọ́ sá à ni èyí.
  • A gba àwọn alágbàṣe ní wákàtí kẹta, kẹfà, kẹsàn-án àti kọkànláMt 20:3, Mt 20:5–6
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 20:3“Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà.
    Mt 20:5–6Wọ́n sì lọ. “Ó tún jáde lọ́sàn án ní nǹkan bí wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsànán, ó túnṣe bákan náà. Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárín ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’
  • Nígbà tí àṣálẹ́ dé, a san owó fún gbogbo wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìnMt 20:8–9
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 20:8–9“Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’ “Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnìkọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan.
  • Ní wákàtí kẹta ni wọ́n kàn Jesu mọ́ àgbélébùúMk 15:25
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 15:25Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú.
  • Òkùnkùn láti wákàtí kẹfà títí dé wákàtí kẹsàn-ánMt 27:45, Mk 15:33, Lk 23:44
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 27:45Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsànán ọjọ́.
    Mk 15:33Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán.
    Lk 23:44Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́.
  • Pilatu: ‘Ẹ wo ọba yín!’ Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfàJh 19:14
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 19:14Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà: Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!”
  • Ibà fi ọmọ ọkùnrin ọlọ́lá náà sílẹ̀ ní wákàtí kejeJh 4:52
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 4:52Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”
  • Ọmọ-ẹ̀yìn méjì bá Jesu lọ ní ìwọ̀n wákàtí kẹwàáJh 1:39
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 1:39Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.” Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.
  • Peteru àti Johanu lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà, wákàtí mẹ́ta ọ̀sánÌṣe 3:1
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 3:1Ní ọjọ́ kan Peteru àti Johanu jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán.
  • Korneliu ń gbàdúrà ní wákàtí kẹsàn-án ọjọ́Ìṣe 10:3, Ìṣe 10:30
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 10:3Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”
    Ìṣe 10:30Korneliu sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹsànán ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi.
  • Peteru gun òkè ilé láti gbàdúrà ní ìwọ̀n wákàtí kẹfàÌṣe 10:9
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 10:9Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́,
  • Àwọn ọmọ-ogun lọ sí Kesarea ní wákàtí kẹta òruÌṣe 23:23
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 23:23Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ sí Kesarea, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹta òru.

Òwúrọ̀, ọ̀sán àti ọ̀gànjọ́

  • Daniẹli ń gbàdúrà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, fèrèsé rẹ̀ ṣí sí JerusalẹmuDa 6:10
    Àwọn ẹsẹ
    Da 6:10Lóòótọ́, Daniẹli mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó ṣí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jerusalẹmu sílẹ̀. Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
  • Saamu kan: ‘Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán èmi sọkún jáde’Sm 55:17
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 55:17Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú, o sì gbọ́ ohùn mi.
  • Abrahamu jókòó ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀ nígbà tí oòrùn mú ní ọ̀sánGẹ 18:1
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 18:1Olúwa sì farahan Abrahamu nítòsí àwọn igi ńlá Mamre, bí ó ti jókòó ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, nígbà tí ọjọ́-kanrí tí oòrùn sì mú.
  • Isaaki jáde lọ sí oko ní ìrọ̀lẹ́Gẹ 24:63
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 24:63Isaaki sì jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àṣàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ìbákasẹ tí ń bọ̀ wá.
  • A pa ẹran ìrékọjá ní àfẹ̀mọ́júmọ́Ek 12:6
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 12:6Ṣe ìtọ́jú wọn títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò pa ẹran náà ní àfẹ̀mọ́júmọ́.
  • Elijah gbàdúrà ní àkókò ìrúbọ àṣálẹ́1Ọb 18:36
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 18:36Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣálẹ́, wòlíì Elijah sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “ Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Israẹli àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ.
  • Àwọn ọkùnrin Nehemiah di ọ̀kọ̀ mú láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí ìràwọ̀ fi yọNe 4:21
    Àwọn ẹsẹ
    Ne 4:21Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ.
  • Ní ọ̀gànjọ́, Samsoni fa ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè ìlú Gasa tuOn 16:3
    Àwọn ẹsẹ
    On 16:3Ṣùgbọ́n Samsoni sùn níbẹ̀ di àárín ọ̀gànjọ́. Òun sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó fi ọwọ́ di àwọn ìlẹ̀kùn odi ìlú náà mú, pẹ̀lú òpó méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu, pẹ̀lú ìdábùú àti ohun gbogbo tí ó wà lára rẹ̀. Ó gbé wọn lé èjìká rẹ̀ òun sì gbé wọn lọ sí orí òkè tí ó kọjú sí Hebroni.
  • Ní ọ̀gànjọ́, Boasi jí, ó sì rí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀Ru 3:8
    Àwọn ẹsẹ
    Ru 3:8Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárín òru, ẹ̀rù bà á, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.
  • Ní nǹkan bí ọ̀gànjọ́, Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin nínú túbúÌṣe 16:25
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 16:25Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run, àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn.
  • Paulu sọ̀rọ̀ títí di ọ̀gànjọ́, Eutiku sì ṣubú láti ojú fèrèséÌṣe 20:7, Ìṣe 20:9
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 20:7Ọjọ́ èkínní ọ̀sẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Paulu sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ọjọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárín ọ̀gànjọ́.
    Ìṣe 20:9Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Eutiku sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Paulu sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lójú oorun, ó ṣubú láti òkè kẹta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú.
  • Àkùkọ kọ lẹ́ẹ̀kejì, Peteru sì rántíMk 14:30, Mk 14:72
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 14:30Jesu si wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tó ó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”
    Mk 14:72Lójúkan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Peteru rántí ọ̀rọ̀ Jesu fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀méjì, ìwọ yóò sẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkún.
  • Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, bí oòrùn ti ń yọ, wọ́n lọ sí ibojìMk 16:2
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 16:2Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibi ibojì nígbà tí oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí yọ,

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.