Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ìbákasẹ

Àwọn àlàyé tí ó yani lẹ́nu

Ìbákasẹ nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (26), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • A kò gbọdọ̀ jẹ ìbákasẹLe 11:4
    Àwọn ẹsẹ
    Le 11:4“ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátákò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbákasẹ ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátákò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́.
  • Abramu, Jakọbu àti Jobu ka ìbákasẹ mọ́ ọrọ̀ wọnGẹ 12:16, Gẹ 30:43, Jb 1:3
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 12:16Ó sì kẹ́ Abramu dáradára nítorí Sarai, Abramu sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú ìbákasẹ.
    Gẹ 30:43Nítorí ìdí èyí, Jakọbu di ọlọ́rọ̀ gidigidi, agbo ẹran rẹ̀ pọ̀ àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin, ìránṣẹ́bìnrin pẹ̀lú ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
    Jb 1:3Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
  • Jobu ní ìbákasẹ 3,000, lẹ́yìn náà 6,000Jb 1:3, Jb 42:12
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 1:3Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
    Jb 42:12Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; ẹgbàá méje (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìbákasẹ, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
  • Obili ará Iṣmaeli ni ó ń bójútó àwọn ìbákasẹ Dafidi1Kro 27:30
    Àwọn ẹsẹ
    1Kro 27:30Obili ará Iṣmaeli wà ní ìdí àwọn ìbákasẹ. Jehdeiah ará Meronoti wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Nínú àwọn ìtàn

  • Ìránṣẹ́ Abrahamu mú ìbákasẹ mẹ́wàá lọ láti wá aya fún IsaakiGẹ 24:10
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 24:10Ìránṣẹ́ náà sì mú ìbákasẹ mẹ́wàá, pẹ̀lú onírúurú ohun dáradára láti ọ̀dọ̀ olúwa rẹ̀, ó sì dìde ó sì lọ sí Aramu-Naharaimu, sí ìlú Nahori,
  • Ó mú àwọn ìbákasẹ kúnlẹ̀ nítòsí kànga ní ìrọ̀lẹ́Gẹ 24:11
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 24:11ó sì mú àwọn ìbákasẹ náà kúnlẹ̀ nítòsí kànga lẹ́yìn ìlú, ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní àkókò tí àwọn obìnrin máa ń lọ pọn omi.
  • Rebeka pọn omi fún gbogbo ìbákasẹ rẹ̀Gẹ 24:14, Gẹ 24:19–20
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 24:14Jẹ́ kí ó ṣe pé nígbà tí mo bá wí fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin pe, ‘Jọ̀wọ́ sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí n le mu omi,’ tí ó bá sì wí pé, ‘Mu ún, èmi ó sì fún àwọn ìbákasẹ rẹ náà mu pẹ̀lú,’ jẹ́ kí ó ṣe èyí tí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ Isaaki. Nípa èyí ni n ó fi mọ̀ pé o ti fi àánú hàn fún olúwa mi.”
    Gẹ 24:19–20Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.” Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ sí ibi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ìbákasẹ, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn.
  • Rebeka gun ìbákasẹ lọ pàdé IsaakiGẹ 24:61, Gẹ 24:64
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 24:61Nígbà náà ni Rebeka àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ múra, wọn sì gun àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì bá ọkùnrin náà padà lọ. Ìránṣẹ́ náà sì mú Rebeka, ó sì bá tirẹ̀ lọ.
    Gẹ 24:64Rebeka pẹ̀lú sì gbójú sókè, ó sì rí Isaaki. Ó sọ̀kalẹ̀ lórí ìbákasẹ,
  • Rakeli fi àwọn òrìṣà Labani pamọ́ sínú gàárì ìbákasẹ, ó sì jókòó lé wọnGẹ 31:34
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 31:34Rakeli sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ìbákasẹ, ó sì jókòó lé e lórí. Labani sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun.
  • Ẹ̀bùn Jakọbu fún Esau ní abo ìbákasẹ 30 pẹ̀lú ọmọ wọnGẹ 32:15
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 32:15ọgbọ̀n abo ìbákasẹ pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá.
  • Ìbákasẹ àwọn ará Iṣmaeli ru tùràrí lọ sí EjibitiGẹ 37:25
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 37:25Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Iṣmaeli tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gileadi. Ìbákasẹ wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjìá, wọ́n ń lọ sí Ejibiti.
  • Àwọn ìbákasẹ àwọn ará Midiani kò lóǹkà bí yanrìnOn 7:12
    Àwọn ẹsẹ
    On 7:12Àwọn ará Midiani, àwọn ará Amaleki àti gbogbo ènìyàn ìlà-oòrùn tó lọ ní àfonífojì bí eṣú ni wọ́n rí nítorí púpọ̀ wọn. Àwọn ìbákasẹ wọn kò sì lóǹkà, wọ́n sì pọ̀ bí yanrìn inú Òkun.
  • Gideoni mú ohun ọ̀ṣọ́ ọrùn àwọn ìbákasẹ àwọn ọba náàOn 8:21
    Àwọn ẹsẹ
    On 8:21Seba àti Salmunna dá Gideoni lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gideoni bọ́ síwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn.
  • Irinwó ará Amaleki gun ìbákasẹ sá mọ́ Dafidi lọ́wọ́1Sa 30:17
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 30:17Dafidi sì pa wọ́n láti àfẹ̀mọ́júmọ́ títí ó fi di àṣálẹ́ ọjọ́ kejì: kò sí ẹnìkan tí ó là nínú wọn, bí kọ̀ ṣe irinwó (400) ọmọkùnrin tí wọ́n gun ìbákasẹ tí wọ́n sì sá.
  • Ayaba Ṣeba wá pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí àti wúrà1Ọb 10:2
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 10:2Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.
  • Hasaeli mú ẹ̀bùn ogójì ẹrù ìbákasẹ tọ Eliṣa wá2Ọb 8:9
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 8:9Hasaeli lọ láti pàdé Eliṣa, ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ogójì ẹrù ìbákasẹ tí gbogbo ìní tí ó dára jù fún wíwò ti Damasku, ó sì wọlé lọ ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọ rẹ Beni-Hadadi ọba Siria rán mi láti béèrè pé, ‘Ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn mi yìí?’ ”
  • Àwọn ará Kaldea kó àwọn ìbákasẹ Jobu lọJb 1:17
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 1:17Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!”
  • Johanu wọ aṣọ irun ìbákasẹMt 3:4, Mk 1:6
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 3:4Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
    Mk 1:6Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Jesu

  • Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́Mt 19:24
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 19:24Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”
  • Ẹ ń tu kòkòrò-kantíkantí nù, ẹ sì ń gbé ìbákasẹ mìMt 23:24
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 23:24Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fi afọ́jú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò-kantíkantí tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ìbákasẹ mì.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.