YCB · Orí 27 / 31
Òwe 27
1Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.
2Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ, àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ̀.
3Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.
4Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?
5Ìbániwí gbangba sàn ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.
6Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.
7Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó ṣùgbọ́n òróǹró gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
8Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.
9Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.
10Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀, má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.
11Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.
12Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.
13Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.
14Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀ a ó kà á sí bí èpè.
15Àyà tí ó máa ń jà dàbí ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;
16dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.
17Bí irin tí ń pọ́n irin mú bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.
18Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀ ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.
19Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.
20Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.
21Iná fún fàdákà iná ìléru fún wúrà, ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.
22Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó, fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́ ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.
23Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;
24nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.
25Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé
26àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ, àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.
27Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́ láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org