Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ẹyẹ

Ìṣẹ̀dá

Ẹyẹ nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (38), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • A dá àwọn ẹyẹ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá inú òkun ní ọjọ́ karùn-únGẹ 1:20–23
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 1:20–23Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.” Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńlá ńlá sí inú òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ karùn-ún.
  • Lẹ́yìn ìkún omi, a fi àwọn ẹyẹ pẹ̀lú ṣe oúnjẹGẹ 9:2–3
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 9:2–3Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.
  • Israẹli lè jẹ ẹyẹ èyíkéyìí tí ó mọ́De 14:11
    Àwọn ẹsẹ
    De 14:11Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́.
  • A kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, ẹyẹ ìwò, ògòǹgò, òwìwí, àkọ̀, òòdẹ̀, atọ́ka, àdánLe 11:13–19
    Àwọn ẹsẹ
    Le 11:13–19“ ‘Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n: idì, oríṣìíríṣìí igún, àwòdì àti onírúurú àṣá, onírúurú ẹyẹ ìwò, Òwìwí, onírúurú ògòǹgò, onírúurú ẹ̀lúùlú, onírúurú àwòdì, Òwìwí kéékèèké, onírúurú òwìwí, Òwìwí funfun àti òwìwí ilẹ̀ pápá, àti àkàlà, àkọ̀, onírúurú òòdẹ̀, atọ́ka àti àdán.
  • Àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi, wọ́n sì ń kọrin láàrín ẹ̀kaSm 104:12
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 104:12Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.
  • Àkọ̀ ń tẹ́ ilé rẹ̀ sórí igi gígaSm 104:17
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 104:17Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.
  • Ní ìgbà ìrúwé, a ń gbọ́ ohùn àdàbàOrin 2:12
    Àwọn ẹsẹ
    Orin 2:12Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀ àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
  • Àkọ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò wọnJr 8:7
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 8:7Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Olúwa wọn fẹ́.
  • Ògòǹgò fi ẹyin rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀ kí wọ́n gbóná nínú ekuruJb 39:14–15
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 39:14–15Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀, a sì mú wọn gbóná nínú ekuru; tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́, tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́.
  • Nígbà tí ó gbé ara sókè, ògòǹgò ń gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣinJb 39:18
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 39:18Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.
  • Àwòdì ń na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsùJb 39:26
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 39:26“Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè, tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù?
  • A ń ta ológoṣẹ́ méjì ní owó wẹ́wẹ́ kan, tàbí márùn-ún ní owó wẹ́wẹ́ méjìMt 10:29, Lk 12:6
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 10:29Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin.
    Lk 12:6Ológoṣẹ́ márùn-ún sá à ni a ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run?
  • Ológoṣẹ́ àti alápáǹdẹ̀dẹ̀ ń tẹ́ ìtẹ́ nítòsí pẹpẹ ilé OlúwaSm 84:3
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 84:3Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀, níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí: ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
  • Àwọn ẹyẹ kì í gbìn, wọn kì í kórè, wọn kì í kójọ sínú àkáMt 6:26
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 6:26Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?
  • Àwọn ẹyẹ ń gbé lórí ẹ̀ka igi músítádì tí ó ti dàgbàMt 13:32
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 13:32Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrín èso rẹ̀, síbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé.”
  • “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́”Mt 8:20
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 8:20Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”
  • Ènìyàn ti tu gbogbo onírúurú ẹyẹ lójúJk 3:7
    Àwọn ẹsẹ
    Jk 3:7Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá.
  • Solomoni sọ̀rọ̀ nípa ẹranko, ẹyẹ, ohun tí ń rákò àti ẹja1Ọb 4:33
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 4:33Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti kedari tí ń bẹ ní Lebanoni dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja.

Nínú àwọn ìtàn

  • Àdàbà Noa padà pẹ̀lú ewé olifi tútù ní ẹnu rẹ̀Gẹ 8:8–12
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 8:8–12Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Noa. Noa na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀. Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀. Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.
  • Àwọn ẹyẹ igún ń bà lé òkú ẹran Abramu, ó sì ń lé wọnGẹ 15:10–11
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 15:10–11Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn. Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn.
  • Ní àṣálẹ́, àwọn àparò bo ibùdó mọ́lẹ̀Ek 16:13
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 16:13Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn àparò fò dé, wọ́n sì bo àgọ́ mọ́lẹ̀, ní òwúrọ̀ ìrì sì sẹ̀ yí gbogbo àgọ́ náà ká.
  • Afẹ́fẹ́ kó àparò wá láti inú Òkun; ẹni tí ó kó kéré jùlọ kó homeri mẹ́wàáNu 11:31–32
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 11:31–32Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì kó àparò wá láti inú Òkun. Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká. Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí, ẹni tó kó kéré jùlọ kó ìwọ̀n homeri mẹ́wàá, wọ́n sì ṣà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó.
  • Ẹyẹ tí ó sanra fún tábìlì Solomoni; adìyẹ lójoojúmọ́ fún ti Nehemiah1Ọb 4:23, Ne 5:18
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 4:23Màlúù mẹ́wàá tí ó sanra, àti ogún màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti èsúró, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.
    Ne 5:18Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni a máa ń pèsè màlúù kan, ààyò àgùntàn mẹ́fà àti adìyẹ fún mi àti lẹ́ẹ̀kan ní ọjọ́ mẹ́wàá ni wọ́n máa ń pèsè onírúurú wáìnì tí ó pọ̀ fún mi. Fún gbogbo èyí, èmi kò béèrè oúnjẹ baálẹ̀, nítorí ohun ti a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí pọ̀ jọjọ.
  • Àkùkọ kọ nígbà tí Peteru sẹ́ JesuMt 26:74–75
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 26:74–75Peteru sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í búra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.” Lójúkan náà àkùkọ sì kọ. Nígbà náà ni Peteru rántí nǹkan tí Jesu ti sọ pé, “Kí àkùkọ tó ó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

Nínú Òfin

  • Gbé àwọn ọmọ ẹyẹ láti inú ìtẹ́, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ ìyá wọn lọDe 22:6–7
    Àwọn ẹsẹ
    De 22:6–7Bí ìwọ bá ṣe alábòápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jókòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ. Ìwọ lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó ba à lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn.
  • Ìwẹ̀mọ́ kúrò nínú ààrùn awọ ara: ẹyẹ méjì, a tú ọ̀kan sílẹ̀ sínú pápáLe 14:4–7
    Àwọn ẹsẹ
    Le 14:4–7Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́. Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀. Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà. Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ kúrò nínú ààrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ìta gbangba.
  • Fún ọmọ ọwọ́ Jesu: àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjìLk 2:22, Lk 2:24
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 2:22Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa
    Lk 2:24àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”

Ọ̀rọ̀ nípa okùn ọdẹ

  • “Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀, ní ojú ẹyẹ!”Òw 1:17
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 1:17Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀, ní ojú ẹyẹ!
  • “Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un?”Am 3:5
    Àwọn ẹsẹ
    Am 3:5Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un? Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?
  • “Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ”Sm 124:7
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 124:7Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ; okùn já àwa sì yọ.
  • Bí ẹyẹ tí a mú nínú okùnSu 9:12
    Àwọn ẹsẹ
    Su 9:12Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé, gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.

Ọ̀rọ̀ mìíràn

  • “Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀”Òw 27:8
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 27:8Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.
  • Ilé tí ó kún fún ẹ̀tàn “Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ”Jr 5:27
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 5:27Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ, ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn; wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,
  • “èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé”Sm 102:7
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 102:7Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
  • “Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀, èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà”Isa 38:14
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 38:14Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀, èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà. Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run. Ìdààmú bá mi, Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.