Ṣàwárí › Àkòrí › Kòkòrò aṣọ àti ìdin
Ìṣẹ̀dá
Kòkòrò aṣọ àti ìdin nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (18), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
Kòkòrò aṣọ
- Kòkòrò ń jẹ aṣọJk 5:2
Àwọn ẹsẹ
Jk 5:2Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín.
- Kòkòrò àti ìpáàrà ń ba ìṣúra ayé jẹ́Mt 6:19–20
Àwọn ẹsẹ
Mt 6:19–20“Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ. Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ.
- Ìṣúra ní ọ̀run, níbi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́Lk 12:33
Àwọn ẹsẹ
Lk 12:33Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́.
- “bi aṣọ tí kòkòrò jẹ”Jb 13:28
Àwọn ẹsẹ
Jb 13:28“Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn ń ṣègbé bí ohun ìdíbàjẹ́, bi aṣọ tí kòkòrò jẹ.
- “kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ”Isa 50:9, Isa 51:8
- “Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ”Jb 27:18
Àwọn ẹsẹ
Jb 27:18Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ, àti bí ahéré tí olùṣọ́ kọ́.
- Àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀, tí a ń run bí kòkòròJb 4:19
Àwọn ẹsẹ
Jb 4:19Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀, ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀ tí yóò di rírun kòkòrò.
Ìdin
- Manna tí a pamọ́ di ọjọ́ kejì kún fún ìdin, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rùnEk 16:20
Àwọn ẹsẹ
Ek 16:20Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mose, wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mose bínú sí wọn.
- Èyí tí a pamọ́ fún ọjọ́ ìsinmi kò ní ìdinEk 16:24
Àwọn ẹsẹ
Ek 16:24Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mose ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin.
- Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, kòkòrò kan jẹ ìtàkùn Jona, ó sì rọJon 4:7
Àwọn ẹsẹ
Jon 4:7Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ.
- Ìdin jẹ Herodu, ó sì kúÌṣe 12:21–23
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 12:21–23Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Herodu sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba. Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni èyí, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” Lójúkan náà, nítorí ti Herodu kò fi ògo fún Ọlọ́run, angẹli Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́.
- Kòkòrò ń jẹ èso àjàrà, nítorí náà kò sí ẹni tí ń kó wọn jọDe 28:39
Àwọn ẹsẹ
De 28:39Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ̀ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èso jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run.
- Jobu: “Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ”Jb 7:5
Àwọn ẹsẹ
Jb 7:5Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ, awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́.
- Nínú ibojì, kòkòrò ń bo ọlọ́rọ̀ àti oníkoro bákan náàJb 21:23–26
Àwọn ẹsẹ
Jb 21:23–26Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀, ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá. Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú, egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá. Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀, tí kò sì fi inú dídùn jẹun. Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀, kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.
- “ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú”Isa 51:8
Àwọn ẹsẹ
Isa 51:8Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ, ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé, àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”
- “àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀”Isa 14:11
Àwọn ẹsẹ
Isa 14:11Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì, pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ, àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.
- Saamu kan: “kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn”Sm 22:6
Àwọn ẹsẹ
Sm 22:6Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn; mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn.
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.