Ìṣẹ̀dá
Ejò nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (28), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
- Gẹnẹsisi: ejò ṣe alárékérekè ju gbogbo ẹranko igbó lọGẹ 3:1
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 3:1Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”
- Gẹnẹsisi: ejò yóò máa fi àyà wọ́, yóò sì máa jẹ erùpẹ̀Gẹ 3:14
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 3:14Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
- “ipa ejò lórí àpáta” — ọ̀kan nínú nǹkan mẹ́rin tí ó yani lẹ́nuÒw 30:18–19
Àwọn ẹsẹ
Òw 30:18–19“Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi, ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.
- Ejò nínú ògiri: ó lè ṣán ẹni tí ó bá la ògiri tàbí tí ó fara tì íSu 10:8, Am 5:19
- Atunilójú ejò: kò sí èrè bí ejò bá ṣán kí a tó lo oògùn rẹ̀Su 10:11
Àwọn ẹsẹ
Su 10:11Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.
- Ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di etí rẹ̀ sí ìpè atunilójúSm 58:4–5
Àwọn ẹsẹ
Sm 58:4–5Oró wọn dàbí oró ejò, wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí, tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú, bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.
- Paramọ́lẹ̀ tí a kò lè pa oró wọnJr 8:17
Àwọn ẹsẹ
Jr 8:17“Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ,” ni Olúwa wí.
- Paramọ́lẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀, ẹni tí ń gùn ún sì ṣubú sẹ́yìnGẹ 49:17
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 49:17Dani yóò jẹ́ ejò ni pópónà àti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ó bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀, kí ẹni tí ń gùn ún bá à le è ṣubú sẹ́yìn.
- Aginjù ní ejò olóró àti àkéekèeDe 8:15
Àwọn ẹsẹ
De 8:15Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.
- Ilẹ̀ gúúsù: ilẹ̀ kìnnìún, paramọ́lẹ̀ àti ejò olóróIsa 30:6
Àwọn ẹsẹ
Isa 30:6Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní gúúsù. Láàrín ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú, ti kìnnìún àti abo kìnnìún ti paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró, àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ohun ìní wọn ní orí àwọn ìbákasẹ, sí orílẹ̀-èdè aláìlérè,
- Bí a bá pa ẹyin paramọ́lẹ̀, paramọ́lẹ̀ ni yóò jádeIsa 59:5
Àwọn ẹsẹ
Isa 59:5Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀ wọn sì ń ta owú aláǹtakùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú, àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde.
Nínú àwọn ìtàn
- Ọ̀pá Mose di ejò; ó sá fún un, lẹ́yìn náà ó mú un ní ìrùEk 4:3–4
Àwọn ẹsẹ
Ek 4:3–4Olúwa sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.” Mose sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un. Nígbà náà ni Olúwa wá sọ fún un pé, “Na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù.” Mose sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀.
- Ọ̀pá Aaroni di ejò, ó sì gbé ọ̀pá àwọn onídán mìEk 7:10–12
Àwọn ẹsẹ
Ek 7:10–12Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn, Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Farao sì pe àwọn amòye, àwọn oṣó àti àwọn onídán ilẹ̀ Ejibiti jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mose àti Aaroni ṣe. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Ṣùgbọ́n ọ̀pá Aaroni gbé ọ̀pá tiwọn mì.
- Ejò olóró bu àwọn ọmọ Israẹli jẹ ní aginjù, ọ̀pọ̀ sì kúNu 21:6
Àwọn ẹsẹ
Nu 21:6Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú.
- Mose rọ ejò idẹ sórí igi; ẹni tí ejò bù tí ó bá wò ó yèNu 21:8–9
Àwọn ẹsẹ
Nu 21:8–9Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.
- Hesekiah fọ́ ejò idẹ náà, Nehuṣitani, nítorí wọ́n ń sun tùràrí sí i2Ọb 18:4
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 18:4Ó mú ibi gíga náà kúrò, ó sì fọ́ àwọn ère òkúta, ó sì gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀, ó sì fọ́ ejò idẹ tí Mose ti ṣe náà túútúú, títí di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli ń sun tùràrí sí. (Wọ́n sì pè é ní Nehuṣitani.)
- Ní Mẹlita, paramọ́lẹ̀ tí ooru iná lé jáde di mọ́ ọwọ́ PauluÌṣe 28:3–4
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 28:3–4Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́. Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú Òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láààyè.”
- Paulu gbọn ọ́n sínú iná; àwọn ará erékùṣù náà ń retí kí ó wúÌṣe 28:5–6
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 28:5–6Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é. Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì; nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.
- Jesu fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀Lk 10:17, Lk 10:19
Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n
- “kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà”Mt 10:16
Àwọn ẹsẹ
Mt 10:16“Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrín ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà.
- Baba wo ni yóò fún ọmọ rẹ̀ ní ejò nígbà tí ó béèrè ẹja?Mt 7:10, Lk 11:11
- Wáìnì “á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀”Òw 23:31–32
Àwọn ẹsẹ
Òw 23:31–32Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n, nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago, tí a gbé e mì, tí ó ń dùn. Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.
- “Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò”Sm 140:3
Àwọn ẹsẹ
Sm 140:3Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.
- “Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò”Mik 7:17
Àwọn ẹsẹ
Mik 7:17Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò, wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló. Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.
- Ejibiti “yóò pòṣé bí ejò tí ń sá”Jr 46:22
Àwọn ẹsẹ
Jr 46:22Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára. Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké, gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.