Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Afẹ́fẹ́

Ìṣẹ̀dá

Afẹ́fẹ́ nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (32), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

Afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn

  • Àlá Farao: síírí ọkà tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ dànùGẹ 41:6, Gẹ 41:23
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 41:6Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yómọ, afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù.
    Gẹ 41:23Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán.
  • Afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́ fún ọ̀sán kan àti òru kan, ó sì gbá eṣú wáEk 10:13
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 10:13Nígbà náà ni Mose na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ sórí ilẹ̀ Ejibiti, Olúwa sì mú kí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn fẹ́ kọjá lórí ilẹ̀ náà ni gbogbo ọ̀sán àti ni gbogbo òru ni ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ afẹ́fẹ́ náà ti gbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú wá;
  • Ìjì líle láti ìlà-oòrùn lé òkun sẹ́yìn ní gbogbo òruEk 14:21
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 14:21Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi òkun sì pínyà,
  • Ẹ̀fúùfù gbígbóná ìlà-oòrùn àti oòrùn mú kí àárẹ̀ mú JonaJon 4:8
    Àwọn ẹsẹ
    Jon 4:8Ó sì ṣe, nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jona lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”
  • Afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń fọ́ ọkọ̀ ní ojú ÒkunSm 48:7, El 27:26
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 48:7Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi, wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
    El 27:26Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ wá sínú omi ńlá. Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ ní àárín gbùngbùn Òkun.

Àwọn afẹ́fẹ́ mìíràn

  • Afẹ́fẹ́ líle láti ìwọ̀-oòrùn gbá eṣú lọ sínú Òkun PupaEk 10:19
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 10:19Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun Pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti.
  • “Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá”Òw 25:23
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 25:23Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá, bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.
  • Òtútù ń wá láti inú afẹ́fẹ́Jb 37:9
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 37:9Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.
  • Aṣọ ń gbóná nígbà tí atẹ́gùn gúúsù mú ilẹ̀ dákẹ́Jb 37:17
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 37:17Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná, nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.
  • “Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù bá ń fẹ́, ẹ̀yin á ní, ‘Oòrùn yóò mú,’”Lk 12:55
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 12:55Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù bá ń fẹ́, ẹ̀yin á ní, ‘Oòrùn yóò mú,’ yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀.
  • Lẹ́yìn tí afẹ́fẹ́ gbá ojú ọ̀run mọ́, kò sí ẹni tí ó lè wo oòrùnJb 37:21
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 37:21Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀, ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.

Nínú àwọn ìtàn

  • Afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi ìkún omi sì bẹ̀rẹ̀ sí í fàGẹ 8:1
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 8:1Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà.
  • Afẹ́fẹ́ kó àparò wá láti inú ÒkunNu 11:31
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 11:31Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì kó àparò wá láti inú Òkun. Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká.
  • Ẹ̀fúùfù láti ijù kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé àwọn ọmọ JobuJb 1:18–19
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 1:18–19Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n. Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.
  • Ní Horebu, ìjì ńlá fọ́ àwọn àpáta, lẹ́yìn náà ilẹ̀ mì1Ọb 19:11
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 19:11Olúwa sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú Olúwa, nítorí Olúwa fẹ́ rékọjá.” Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú Olúwa; ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà.
  • Ìjì ńlá lójú Òkun fẹ́rẹ̀ fọ́ ọkọ̀ JonaJon 1:4
    Àwọn ẹsẹ
    Jon 1:4Nígbà náà ni Olúwa rán ìjì ńlá jáde sí ojú Òkun, ìjì líle sì wà nínú Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́.
  • Jesu bá afẹ́fẹ́ àti Òkun wí, ìdákẹ́rọ́rọ́ ńlá sì déMt 8:24–27
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 8:24–27Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì líle dìde lórí Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jesu ń sùn. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, gbà wá! Àwa yóò rì!” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú Òkun náà wí, gbogbo rẹ̀ sì parọ́rọ́. Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?”
  • Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń wa ọkọ̀ pẹ̀lú wàhálà, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọnMk 6:48, Mt 14:24, Jh 6:18
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 6:48Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá,
    Mt 14:24ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.
    Jh 6:18Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúùfù líle tí ń fẹ́.
  • Afẹ́fẹ́ gúúsù jẹ́jẹ́, lẹ́yìn náà ìjì tí a ń pè ní EurakuiloÌṣe 27:13–15
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 27:13–15Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣe bí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń gba ẹ̀bá Krete lọ. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Eurakuilo fẹ́ lù erékùṣù náà. Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-òkun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ.
  • Pẹ̀lú afẹ́fẹ́ gúúsù, ọkọ̀ Paulu lọ láti Regiomu dé Puteoli ní ọjọ́ méjìÌṣe 28:13
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 28:13Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Regiomu: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Puteoli.

Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n

  • “Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúúsù, Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá”Su 1:6
    Àwọn ẹsẹ
    Su 1:6Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúúsù, Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá, a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.
  • “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn”Su 11:4
    Àwọn ẹsẹ
    Su 11:4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè.
  • “ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́”Su 11:5
    Àwọn ẹsẹ
    Su 11:5Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.
  • “Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀”Jh 3:8
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 3:8Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, àti ibi tí ó gbé ń lọ, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa ti Ẹ̀mí.”
  • Bí ìyàngbò ọkà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànùSm 1:4
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 1:4Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú! Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
  • “Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mi?”Mt 11:7
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 11:7Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ti lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Johanu: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginjù? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mi?
  • Ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí ọkọ̀ ńlá tí ẹ̀fúùfù líle ń gbá kiriJk 3:4
    Àwọn ẹsẹ
    Jk 3:4Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀.
  • “ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn”Jk 1:6
    Àwọn ẹsẹ
    Jk 1:6Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.