Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Àkéekèe

Ìṣẹ̀dá

Àkéekèe nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (8), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Aginjù ní ejò olóró àti àkéekèeDe 8:15
    Àwọn ẹsẹ
    De 8:15Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.
  • A sọ fún Esekiẹli pé kí ó má bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ ń gbé àárín àkéekèeEl 2:6
    Àwọn ẹsẹ
    El 2:6Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárín àwọn àkéekèe. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n.
  • Jesu fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀Lk 10:17, Lk 10:19
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 10:17Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”
    Lk 10:19Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá, kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.

Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n

  • Bí ó bá béèrè ẹyin, ǹjẹ́ baba yóò fún un ní àkéekèe?Lk 11:12
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 11:12Tàbí bí ó sì béèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekèe?
  • Rehoboamu: “Baba mi ti fi pàṣán nà yín, Èmi yóò fi àkéekèe nà yín”1Ọb 12:11, 1Ọb 12:14, 2Kro 10:14
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 12:11Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín; Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín. Baba mi ti fi pàṣán nà yín, Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”
    1Ọb 12:14Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo, èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i, baba mi fi pàṣán nà yín èmi yóò fi àkéekèe nà yín.”
    2Kro 10:14Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; èmi yóò sì mú kí ó wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.”

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.