Ṣàwárí › Àkòrí › Àgbọ̀nrín àti èsúró
Ìṣẹ̀dá
Àgbọ̀nrín àti èsúró nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (19), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
- A lè jẹ àgbọ̀nrín àti èsúró, ẹni mímọ́ àti aláìmọ́ bákan náàDe 12:15, De 14:5
Àwọn ẹsẹ
De 12:15Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ lọ pa àwọn ẹran yín ní èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín, kí ẹ sì jẹ ẹran náà tó bí ẹ ti fẹ́, bí ẹ ti ń ṣe sí àgbọ̀nrín àti èsúró, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fi fún un yín, àti ẹni mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ nínú àwọn ẹran náà.
De 14:5àgbọ̀nrín, èsúró, etu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó.
- A pèsè àgbọ̀nrín, èsúró àti ogbúgbu fún tábìlì Solomoni1Ọb 4:22–23
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 4:22–23Oúnjẹ Solomoni fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta òsùwọ̀n ìyẹ̀fun, Màlúù mẹ́wàá tí ó sanra, àti ogún màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti èsúró, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.
- Jobu: abo àgbọ̀nrín ń bẹ̀rẹ̀ láti bímọ; àwọn ọmọ ń dàgbà nínú pápáJb 39:1–4
Àwọn ẹsẹ
Jb 39:1–4“Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ? Ìwọ sì lè kíyèsi ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ? Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pé, ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ. Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bímọ, wọ́n sì mú ìkáàánú wọn jáde. Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn; wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.
- Nínú ọ̀dá, abo àgbọ̀nrín fi ọmọ rẹ̀ tuntun sílẹ̀ nítorí kò sí koríkoJr 14:5
Àwọn ẹsẹ
Jr 14:5Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, torí pé kò sí koríko.
- “Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi”Sm 42:1
Àwọn ẹsẹ
Sm 42:1Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora. Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
- Àgbọ̀nrín tí kò rí ewé tútù jẹ kò lágbára láti sá fún ọdẹẸj 1:6
Àwọn ẹsẹ
Ẹj 1:6Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé kúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nrín tí kò rí ewé tútù jẹ; nínú àárẹ̀ wọ́n sáré níwájú ẹni tí ó ń lé wọn.
- Èsúró gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹÒw 6:5
Àwọn ẹsẹ
Òw 6:5Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ, bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.
Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n
- Ẹsẹ̀ Asaheli fẹ́rẹ̀ bí ti èsúró inú pápá2Sa 2:18
Àwọn ẹsẹ
2Sa 2:18Àwọn ọmọkùnrin Seruiah mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó wà níbẹ̀: Joabu, Abiṣai àti Asaheli. Nísinsin yìí ẹsẹ̀ Asaheli sì fẹ́rẹ̀ bí ẹsẹ̀ èsúró tí ó wà ní pápá.
- Àwọn jagunjagun ará Gadi yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè1Kro 12:8
Àwọn ẹsẹ
1Kro 12:8Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.
- “Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín” lórí ibi gíga2Sa 22:34, Sm 18:33, Hk 3:19
Àwọn ẹsẹ
2Sa 22:34Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó sì mú mi dúró ní ibi gíga mi.
Sm 18:33Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
Hk 3:19Olúwa Olódùmarè ni agbára mi, òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín, yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga. Sí olórí akọrin lórí ohun èlò orin olókùn mi.
- “Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ”Òw 5:19
Àwọn ẹsẹ
Òw 5:19Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ, jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo, kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkígbà.
- Olùfẹ́ náà, bí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín lórí àwọn òkèOrin 2:9, Orin 2:17, Orin 8:14
Àwọn ẹsẹ
Orin 2:9Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà.
Orin 2:17Títí ìgbà ìtura ọjọ́ títí òjìji yóò fi fò lọ, yípadà, olùfẹ́ mi, kí o sì dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín lórí òkè Beteri.
Orin 8:14Yára wá, Olùfẹ́ mi, kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin, tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín, lórí òkè òórùn dídùn.
- “mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú”Orin 2:7
Àwọn ẹsẹ
Orin 2:7Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.
- “Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín tí a tú sílẹ̀”Gẹ 49:21
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 49:21“Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín tí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ dáradára.
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.