Ìṣẹ̀dá
Àgùntàn nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (38), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
- Abeli jẹ́ darandaranGẹ 4:2
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 4:2Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli. Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.
- Abeli mú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ wáGẹ 4:4
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 4:4Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀,
- Abrahamu rí àgbò kan tí ìwo rẹ̀ há sínú pàǹtíríGẹ 22:13
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 22:13Abrahamu sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀.
- Àwọn darandaran yí òkúta kúrò lẹ́nu kànga láti fún agbo ẹran ní omiGẹ 29:2–3
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 29:2–3Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi. Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọpọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà.
- Darandaran ni Rakeli; Jakọbu fún àgùntàn baba rẹ̀ ní omiGẹ 29:9–10
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 29:9–10Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakeli dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà. Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi.
- Àwọn ọmọbìnrin méje Jetro pọn omi fún agbo ẹran, Mose sì ràn wọ́n lọ́wọ́Ek 2:16–17
Àwọn ẹsẹ
Ek 2:16–17Ó sì ṣe, àlùfáà Midiani kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn. Àwọn darandaran kan wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mose dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.
- Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro nígbà tí ó dé HorebuEk 3:1
Àwọn ẹsẹ
Ek 3:1Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run.
- Dafidi, àbíkẹ́yìn, wà ní ìta tí ó ń tọ́jú agbo àgùntàn1Sa 16:11
Àwọn ẹsẹ
1Sa 16:11Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?” Jese dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.” Samuẹli sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.”
- Jakọbu gẹ́gẹ́ bí darandaran: ooru ní ọ̀sán, òtútù ní òru, àdánù sí ẹranko búburúGẹ 31:38–40
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 31:38–40“Mo ti wà lọ́dọ̀ rẹ fún ogún ọdún, àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rẹ kò sọnù bẹ́ẹ̀ n kò pa ọ̀kan jẹ rí nínú àwọn àgbò rẹ. Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fàya, èmi ni ó fi ara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀. Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi. Báyìí ni mo wà; oòrùn ń pa mi lọ́sàn án, òtútù ń pa mi lóru, mo sì ń ṣe àìsùn.
- Owó iṣẹ́ Jakọbu: àwọn ẹran onílà, alámì àti dúdúGẹ 30:32
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 30:32Jẹ́ kí èmi kí ó la agbo ẹran kọjá ní òní, èmi yóò sì mú gbogbo àgùntàn onílà àti èyí tí ó ní àmì, àti gbogbo àgbò dúdú pẹ̀lú ewúrẹ́ onílà tàbí tí ó ní àmì. Àwọn wọ̀nyí ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ mi.
- Ọ̀pá tí ó bó èèpo rẹ̀ níbi agbada omi àti àwọn ọmọ ẹran onílàGẹ 30:37–39
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 30:37–39Nígbà náà ni Jakọbu gé ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ tútù kan lára igi Poplari, àti igi almondi àti igi Pileeni. Ó sì bó èèpo kúrò ní ibi kọ̀ọ̀kan lára igi náà láti fún igi náà ní àwọ̀ ju ẹyọ kan lọ. Ó sì mú àwọn ọ̀pá wọ̀nyí tì sí ọ̀ọ́kán agbada omi níbi tí àwọn ẹran ti lè rí i nígbà tí wọ́n bá wá mu omi. Tí àwọn ẹran bá sì ń gùn, níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọn sì bí àwọn ẹran onílà àti alámì, àwọn tí ó ní tótòtó lára.
- Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń ṣọ́ agbo wọn ní òruLk 2:8
Àwọn ẹsẹ
Lk 2:8Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.
- Àwọn àgùntàn mọ ohùn olùṣọ́ wọn; ó ń pè wọ́n lórúkọJh 10:3–4
Àwọn ẹsẹ
Jh 10:3–4Òun ni aṣọ́nà yóò ṣílẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀, ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ, ó sì ṣe amọ̀nà wọn jáde. Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò síwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀.
Irun, wàrà àti rírẹ́ irun
- Wàrà agbo ẹran, ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti àgbò ti BaṣaniDe 32:14
Àwọn ẹsẹ
De 32:14Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntàn àti ti àgbò ẹran àti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́, pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣani tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì.
- Labani lọ rẹ́ irun àgùntàn nígbà tí Rakeli jí àwọn òrìṣàGẹ 31:19
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 31:19Nígbà tí Labani sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rakeli sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀.
- Juda gòkè lọ sọ́dọ̀ àwọn olùrẹ́run àgùntàn rẹ̀ ní TimnaGẹ 38:12–13
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 38:12–13Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Juda, ọmọbìnrin Ṣua sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Juda sì pé, ó gòkè lọ sí Timna, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hira ará Adullamu tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ. Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Tamari pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Timna láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.”
- Nabali ní àgùntàn 3,000 àti ewúrẹ́ 1,000, ó ń rẹ́ irun wọn ní Karmeli1Sa 25:2
Àwọn ẹsẹ
1Sa 25:2Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Maoni, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Karmeli; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli.
- Àkókò rírẹ́ irun jẹ́ àkókò àsè: ti Nabali àti ti Absalomu1Sa 25:11, 1Sa 25:36, 2Sa 13:23–24
Àwọn ẹsẹ
1Sa 25:11Ǹjẹ́ ki èmi o mú oúnjẹ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pa fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi sì fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá?”
1Sa 25:36Abigaili sì tọ Nabali wá, sì wò ó, òun sì ṣe àsè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àsè ọba: inú Nabali sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara; òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀: títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀
2Sa 13:23–24Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu, Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”
- Àkọ́rẹ́ irun àgùntàn jẹ́ ti àwọn àlùfáàDe 18:3–4
Àwọn ẹsẹ
De 18:3–4Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rú ẹbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà. Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn.
- Jobu fi irun àgùntàn rẹ̀ mú kí ara tálákà gbónáJb 31:20
Àwọn ẹsẹ
Jb 31:20bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi, tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;
Agbo ẹran ní iye
- Meṣa ọba Moabu san ọ̀dọ́-àgùntàn 100,000 àti irun àgbò 100,0002Ọb 3:4
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 3:4Nísinsin yìí Meṣa ọba Moabu ń sin àgùntàn, ó sì gbọdọ̀ fi fún ọba Israẹli pẹ̀lú ọ̀kẹ́ márùn-ún ọ̀dọ́-àgùntàn àti pẹ̀lú irun ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) àgbò.
- Àwọn ará Arabia mú àgbò 7,700 àti òbúkọ 7,700 wá fún Jehoṣafati2Kro 17:11
Àwọn ẹsẹ
2Kro 17:11Lára àwọn ará Filistini, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jehoṣafati, àwọn ará Arabia sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún un, ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) àgbò àti ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) òbúkọ.
- A kó àgùntàn 250,000 lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hagari1Kro 5:21
Àwọn ẹsẹ
1Kro 5:21Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000) àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún (250,000), àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì (2,000), àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000).
- Jobu ní àgùntàn 7,000, lẹ́yìn náà 14,000Jb 1:3, Jb 42:12
Àwọn ẹsẹ
Jb 1:3Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
Jb 42:12Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; ẹgbàá méje (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìbákasẹ, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
- Kedari ṣòwò ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́ pẹ̀lú TireEl 27:21
Àwọn ẹsẹ
El 27:21“ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé ìlú Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ; ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ.
- Solomoni rú àgùntàn 120,000 ní ìyàsímímọ́ ilé Olúwa1Ọb 8:63
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 8:63Solomoni rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ya ilé Olúwa sí mímọ́.
Nínú Òfin
- Àgùntàn tí a jí tí a pa tàbí tí a tà: san àgùntàn mẹ́rin padàEk 22:1
Àwọn ẹsẹ
Ek 22:1“Bí ọkùnrin kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tí ó sì pa á tàbí tà á. Ó gbọdọ̀ san akọ màlúù márùn-ún padà fún ọ̀kan tí ó jí, àti àgùntàn mẹ́rin mìíràn fún ọ̀kan tí ó jí.
- Àgùntàn tí ẹranko búburú fà ya: mú òkú rẹ̀ wá ní ẹ̀ríEk 22:10, Ek 22:13
Àwọn ẹsẹ
Ek 22:10“Bí ẹnikẹ́ni bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, akọ màlúù, àgùntàn tàbí ẹranko mìíràn láti bá òun tọ́jú rẹ̀, tí ó sì kú, tàbí tí ó fi ara pa, tàbí tí a jí gbé, níbi tí kò ti sí ẹni tí o ṣe àkíyèsí.
Ek 22:13Bí ẹranko búburú bá fà á ya, ó ní láti mú àyakù ẹran náà wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, kò sì ní san ẹran náà padà.
Ní Jerusalẹmu
- Àwọn àlùfáà tún ibodè Àgùntàn mọNe 3:1
Àwọn ẹsẹ
Ne 3:1Eliaṣibu olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún ibodè Àgùntàn mọ. Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn-ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hananeli.
- Adágún Betisaida wà létí bodè àgùntànJh 5:2
Àwọn ẹsẹ
Jh 5:2Adágún omi kan sì wà ní Jerusalẹmu, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Betisaida ní èdè Heberu, tí ó ní ẹnu-ọ̀nà márùn-ún.
Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n
- Eyín “bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀”Orin 4:2
Àwọn ẹsẹ
Orin 4:2Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀; olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́; kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.
- “Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà”Òw 27:23
Àwọn ẹsẹ
Òw 27:23Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;
- “àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ”Òw 27:26
Àwọn ẹsẹ
Òw 27:26àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ, àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.
- “gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀”Isa 53:7
Àwọn ẹsẹ
Isa 53:7A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.