Ìṣẹ̀dá
Ihò àpáta nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (30), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
Ààbò àti ibi ìfarapamọ́
- Lọti àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì ń gbé inú ihò àpáta lórí òkèGẹ 19:30
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 19:30Lọti àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Soari, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Soari.
- Elijah sùn mọ́jú nínú ihò òkúta kan ní Horebu1Ọb 19:8–9
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 19:8–9Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run. Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Elijah?”
- Ó fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì dúró ní ẹnu ihò náà1Ọb 19:13
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 19:13Nígbà tí Elijah sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà. Nígbà náà ni ohùn kan tọ̀ ọ́ wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín, Elijah?”
- Àwọn ọba márùn-ún fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta ní MakkedaJoṣ 10:16–17
Àwọn ẹsẹ
Joṣ 10:16–17Ní báyìí àwọn ọba Amori márùn-ún ti sálọ, wọ́n sì fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Makkeda, nígbà tí wọ́n sọ fún Joṣua pé, a ti rí àwọn ọba márààrún, ti ó fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Makkeda,
- Joṣua ní kí wọ́n yí òkúta ńlá dí ẹnu rẹ̀Joṣ 10:18
Àwọn ẹsẹ
Joṣ 10:18ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ.
- Lẹ́yìn náà òkúta wọ̀nyí wà ní ẹnu ihò náà “di òní yìí”Joṣ 10:27
Àwọn ẹsẹ
Joṣ 10:27Nígbà tí oòrùn wọ̀, Joṣua pàṣẹ, wọ́n sì sọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúrò ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sá pamọ́ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí.
- Àwọn ọmọ Israẹli fi ara pamọ́ nínú ihò, igbó, àpáta, ọ̀fìn àti kànga gbígbẹ1Sa 13:6
Àwọn ẹsẹ
1Sa 13:6Nígbà tí àwọn ọkùnrin Israẹli sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fi ara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàrín àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kànga gbígbẹ.
- Àwọn Filistini: “Àwọn Heberu ń yọ jáde wá láti inú ihò”1Sa 14:11
Àwọn ẹsẹ
1Sa 14:11Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Filistini. Àwọn Filistini sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Heberu ń yọ jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.”
- Obadiah fi ọgọ́rùn-ún wòlíì pamọ́, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú àkàrà àti omi1Ọb 18:4, 1Ọb 18:13
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 18:4Nígbà tí Jesebeli sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Obadiah sì mú ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.
1Ọb 18:13Ṣé Olúwa mi kò ha ti gbọ́ ohun tí mo ṣe nígbà tí Jesebeli ń pa àwọn wòlíì Olúwa? Mo fi ọgọ́rùn-ún wòlíì Olúwa pamọ́ sínú ihò òkúta méjì, àràádọ́ta ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo sì fi omi àti oúnjẹ bọ́ wọn.
- Samsoni dúró nínú ihò àpáta EtamuOn 15:8, On 15:11
Àwọn ẹsẹ
On 15:8Ó kọlù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Etamu.
On 15:11Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin láti Juda sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Etamu, wọ́n sì sọ fún Samsoni pé, “Kò ti yé ọ pé àwọn Filistini ní ń ṣe alákòóso lórí wa? Kí ni o ṣe sí wa?” Òun sì dáhùn pé, “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni èmi náà ṣe sí wọn.”
- Dafidi sá sí ihò Adullamu; nǹkan bí ọkùnrin 400 dara pọ̀ mọ́ ọn1Sa 22:1–2
Àwọn ẹsẹ
1Sa 22:1–2Dafidi sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Adullamu; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀. Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ìpọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbèsè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó ìwọ̀n irinwó (400) ọmọkùnrin.
- Mẹ́ta nínú àwọn olórí wá sọ́dọ̀ Dafidi nínú ihò Adullamu ní àkókò ìkórè2Sa 23:13, 1Kro 11:15
Àwọn ẹsẹ
2Sa 23:13Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ Dafidi wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Adullamu, ọ̀wọ́ àwọn Filistini sì dó sí àfonífojì Refaimu.
1Kro 11:15Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dafidi wá lọ sí orí àpáta nínú ihò Adullamu, nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Filistini sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Refaimu.
- Saulu wọ ihò tí Dafidi fi ara pamọ́ sí; Dafidi gé etí agbádá rẹ̀1Sa 24:3–4
Àwọn ẹsẹ
1Sa 24:3–4Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà. Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dafidi sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Saulu.
- Dafidi jáde kúrò nínú ihò, ó sì kọ sí Saulu1Sa 24:8
Àwọn ẹsẹ
1Sa 24:8Dafidi sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Saulu pé, “Olúwa mi, ọba!” Saulu sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dafidi sì dojú rẹ́ bo ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un.
- Àkọlé Saamu méjì: Dafidi “nínú ihò òkúta”Sm 57:1, Sm 142:1
Àwọn ẹsẹ
Sm 57:1Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà. Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.
Sm 142:1Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà. Èmi kígbe sókè sí Olúwa; èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
- Àwọn tí a lé jáde ń gbé inú pàlàpálá òkúta àti ihò ilẹ̀Jb 30:6
Àwọn ẹsẹ
Jb 30:6A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta àfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.
- Àwọn kan ń kiri nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀Hb 11:38
Àwọn ẹsẹ
Hb 11:38àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún. Wọ́n ń kiri nínú aṣálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀.
Ihò ìsìnkú
- Abrahamu ra ihò àpáta Makpela lọ́wọ́ Efroni ará HitiGẹ 23:9, Gẹ 23:17–20
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 23:9kí ó ta ihò àpáta Makpela tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrín yín.”
Gẹ 23:17–20Báyìí ni ilẹ̀ Efroni tí ó wà ni Makpela nítòsí Mamre, ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú, bí ohun ìní fún Abrahamu níwájú gbogbo ará Hiti tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà. Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani. Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé, bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un.
- Isaaki àti Iṣmaeli sin Abrahamu síbẹ̀Gẹ 25:9–10
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 25:9–10Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki àti Iṣmaeli sì sin ín sínú ihò àpáta ni Makpela ní ẹ̀gbẹ́ Mamre, ní oko Efroni ọmọ Sohari ará Hiti, inú oko tí Abrahamu rà lọ́wọ́ ara Hiti yìí ni a sin Abrahamu àti Sara aya rẹ̀ sí.
- Jakọbu: Abrahamu, Sara, Isaaki, Rebeka àti Lea wà nínú ihò náàGẹ 49:29–32
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 49:29–32Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni. Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Makpela, nítòsí Mamre ní Kenaani, èyí tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. Níbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí. Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hiti.”
- Àwọn ọmọ Jakọbu gbé e láti Ejibiti lọ sí MakpelaGẹ 50:13
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 50:13Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makpela, ní tòsí i Mamre tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti, pẹ̀lú ilẹ̀ náà.
- Ibojì Lasaru jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀Jh 11:38
Àwọn ẹsẹ
Jh 11:38Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀.
- A gbẹ́ ibojì Jesu sínú àpáta, a sì yí òkúta dí iMt 27:60, Mk 15:46
Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.