Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Kìnnìún

Ìṣẹ̀dá

Kìnnìún nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (31), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Kìnnìún ń bú ramúramù lórí ẹran ọdẹ rẹ̀; ọmọ kìnnìún ń ké nínú ihò rẹ̀Am 3:4
    Àwọn ẹsẹ
    Am 3:4Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó, bí kò bá ní ohun ọdẹ? Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀ bí kò bá rí ohun kan mú?
  • Abo kìnnìún àti ẹgbọrọ kìnnìún ń mọ́lẹ̀ nínú ihò, wọ́n ń ba de ohun ọdẹJb 38:39–40
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 38:39–40“Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí? Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn, nígbà tí wọ́n bá mọ́lẹ̀ nínú ihò tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?
  • Kìnnìún pa ẹran ọdẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì fi ẹran kún ihò rẹ̀Nh 2:11–12
    Àwọn ẹsẹ
    Nh 2:11–12Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún, níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún tí ń rìn, àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù. Kìnnìún tipa ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì fún un ẹran ọdẹ ní ọrùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀, ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀ àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ.
  • Kìnnìún ń ṣègbé nítorí àìrí ohun ọdẹ; àwọn ọmọ rẹ̀ túkáJb 4:10–11
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 4:10–11Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnnìún àti eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún ní a ká. Kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ, àwọn ẹgbọrọ kìnnìún sísanra ni a túká kiri.
  • Alágbára láàrín ẹranko, tí kì í sá fún ohunkóhunÒw 30:30
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 30:30Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun
  • Àwọn kìnnìún ń gbé inú igbó JordaniJr 49:19, Jr 50:44, Sek 11:3
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 49:19“Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”
    Jr 50:44Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Babeli kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”
    Sek 11:3Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn; ògo wọn bàjẹ́; gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún nítorí ògo Jordani bàjẹ́.
  • Olùṣọ́-àgùntàn lè gba itan méjì tàbí ẹ̀là etí kan ṣoṣo lẹ́nu kìnnìúnAm 3:12
    Àwọn ẹsẹ
    Am 3:12Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”
  • Igbe ẹgbẹ́ olùṣọ́-àgùntàn kò lè lé kìnnìún kúrò lórí ẹran ọdẹ rẹ̀Isa 31:4
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 31:4Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀ bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀, ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀.

Ìpàdé pẹ̀lú kìnnìún

  • Samsoni fi ọwọ́ lásán fa ọ̀dọ́ kìnnìún yaOn 14:5–6
    Àwọn ẹsẹ
    On 14:5–6Samsoni sọ̀kalẹ̀ lọ sí Timna òun àti baba àti ìyá rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Timna, láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀.
  • Lẹ́yìn náà ó rí ìṣù oyin nínú òkú kìnnìún náàOn 14:8–9
    Àwọn ẹsẹ
    On 14:8–9Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnnìún náà. Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin, ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà.
  • Àlọ́ rẹ̀: “Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá”On 14:14, On 14:18
    Àwọn ẹsẹ
    On 14:14Ó dáhùn pé, “Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá; láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.” Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtumọ̀ sí àlọ́ náà.
    On 14:18Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé, “Kí ni ó dùn ju oyin lọ? Kí ni ó sì lágbára ju kìnnìún lọ?” Samsoni dá wọn lóhùn pé, “Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ abo màlúù mi kọ ilẹ̀, ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.”
  • Dafidi, ọmọdékùnrin olùṣọ́-àgùntàn, pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn tí ó gbé àgùntàn1Sa 17:34–36
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 17:34–36Ṣùgbọ́n Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ti ń tọ́jú agbo àgùntàn baba rẹ̀. Nígbà tí kìnnìún tàbí àmọ̀tẹ́kùn bá wá láti wá gbé àgùntàn láti inú igbó. Mo sá tẹ̀lé e, mo lù ú, mo sì gba àgùntàn náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí ó kọjú sí mi, mo fi irun rẹ̀ gbá a mú, mo sì lù ú mo sì pa á. Ìránṣẹ́ rẹ ti pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, aláìkọlà Filistini yìí yóò jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pe ogun Ọlọ́run alààyè ní ìjà.
  • Benaiah sọ̀kalẹ̀ sínú ihò ní ọjọ́ òjò-dídì, ó sì pa kìnnìún kan2Sa 23:20
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 23:20Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì.
  • Kìnnìún pa ènìyàn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò jẹ ẹ́, kò sì fọwọ́ kan kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀1Ọb 13:24–28
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 13:24–28Bí ó sì ti ń lọ ní ọ̀nà rẹ̀, kìnnìún kan pàdé rẹ̀ ní ọ̀nà, ó sì pa á, a sì gbé òkú rẹ̀ sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró tì í lẹ́gbẹ̀ẹ́. Àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá sì rí pé ó gbé òkú náà sọ sí ojú ọ̀nà, kìnnìún náà sì dúró ti òkú náà; wọ́n sì wá, wọ́n sì sọ ọ́ ní ìlú tí wòlíì àgbà náà ń gbé. Nígbà tí wòlíì tí ó mú un padà wá láti ọ̀nà rẹ̀ sì gbọ́ èyí, ó sì wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run náà ni tí ó ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́. Olúwa sì ti fi lé kìnnìún lọ́wọ́, tí ó sì fà á ya, tí ó sì pa á, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti kìlọ̀ fún un.” Wòlíì náà sì wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi,” wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà náà ni ó sì jáde lọ, ó sì rí òkú náà tí a gbé sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kìnnìún náà kò sì jẹ òkú náà, tàbí fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ya.
  • Kìnnìún pa ọkùnrin tí ó kọ̀ láti lu wòlíì1Ọb 20:35–36
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 20:35–36Nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, ọkùnrin kan nínú àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì wí fún èkejì rẹ̀ pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí,” ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti lù ú. Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn Olúwa gbọ́, kíyèsi i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́.” Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á.
  • Àwọn kìnnìún pa díẹ̀ nínú àwọn tí a kó wá sí ìlú Samaria2Ọb 17:25–26
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 17:25–26Nígbà tí wọ́n gbé bẹ̀ ní àkọ́kọ́, wọn kò sì bẹ̀rù Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni ó rán kìnnìún sí àárín wọn. Wọ́n sì pa nínú wọn. Wọ́n sì sọ fún ọba Asiria pé, “Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Samaria kò mọ ohun tí ọlọ́run ìlú náà béèrè. Ó sì ti rán kìnnìún sí àárín wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè.”
  • A ju Daniẹli sínú ihò kìnnìún, a sì fi òkúta àti òrùka èdìdì ọba dí iDa 6:16–17
    Àwọn ẹsẹ
    Da 6:16–17Nígbà náà, ni ọba pàṣẹ, wọ́n sì mú Daniẹli, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò kìnnìún. Ọba sì sọ fún Daniẹli pé, “Kí Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn nígbà gbogbo kí ó gbà ọ́!” A sì gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà, ọba sì dì í pa pẹ̀lú òrùka èdìdì rẹ̀ àti pẹ̀lú òrùka àwọn ọlọ́lá rẹ̀, nítorí kí a má ṣe yí ohunkóhun padà nítorí i Daniẹli.
  • Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, a fà Daniẹli jáde láìní ọgbẹ́Da 6:19–23
    Àwọn ẹsẹ
    Da 6:19–23Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, ni ọba dìde ó sì sáré lọ sí ibi ihò kìnnìún náà. Nígbà tí ó súnmọ́ ibi ihò náà ní ibi tí Daniẹli wà, ó pe Daniẹli pẹ̀lú ìtara pé, “Daniẹli, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, ṣé Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn tọ̀sán tòru, lè gbà ọ́ lọ́wọ́ kìnnìún bí?” Daniẹli sì dáhùn wí pé, “Ọba kí ẹ pẹ́! Ọlọ́run mi rán angẹli i rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún lẹ́nu. Wọn kò le è pa mí lára, nítorí a rí mi gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò hu ìwà ìbàjẹ́ kan níwájú rẹ ìwọ ọba.” Inú ọba dùn gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a mú Daniẹli jáde wá láti inú ihò. Nígbà tí a mú Daniẹli jáde nínú ihò, kò sí ojú ọgbẹ́ kan ní ara rẹ̀, nítorí tí ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
  • A ju àwọn alátakò rẹ̀ sínú ihò, àwọn kìnnìún sì borí wọn kí wọ́n tó dé ìsàlẹ̀Da 6:24
    Àwọn ẹsẹ
    Da 6:24Ọba pàṣẹ pé, kí a mú àwọn alátakò Daniẹli wá, kí a jù wọ́n sí inú ihò kìnnìún, pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ wọn. Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀ ihò, kìnnìún lágbára lórí i wọn, wọ́n sì fọ́ gbogbo egungun wọn.

Kìnnìún nínú iṣẹ́ ọnà

  • Ìtẹ́ Solomoni: kìnnìún lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìrọpá kọ̀ọ̀kan àti kìnnìún méjìlá lórí àtẹ̀gùn mẹ́fà1Ọb 10:19–20
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 10:19–20Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè. Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni ìrọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí.
  • Kìnnìún, màlúù àti kérúbù ṣe ọ̀ṣọ́ sí ìjókòó idẹ ilé Olúwa1Ọb 7:29, 1Ọb 7:36
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 7:29Lórí àlàfo ọnà àárín tí ó wà lágbedeméjì ni àwòrán kìnnìún, màlúù, àti àwọn kérúbù wà, àti lórí ìpàdé etí bákan náà. Lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún, màlúù sì ni iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà.
    1Ọb 7:36Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ, sára ìgbátí rẹ̀ àti sára pákó tí ó gbé ró, ní gbogbo ibi tí ààyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri.

Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n

  • “ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!”Su 9:4
    Àwọn ẹsẹ
    Su 9:4Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!
  • Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde!”Òw 22:13, Òw 26:13
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 22:13Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde! Yóò pa mí ní ìgboro!”
    Òw 26:13Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”
  • “Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún”Òw 20:2
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 20:2Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún; ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.
  • Saulu àti Jonatani: “Wọ́n yára ju idì lọ, wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ”2Sa 1:23
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 1:23Saulu àti Jonatani— ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn, ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n. Wọ́n yára ju idì lọ, wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.
  • Ojú àwọn jagunjagun ará Gadi dàbí ti kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín1Kro 12:8
    Àwọn ẹsẹ
    1Kro 12:8Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.