Bible Explorer

Bíbélì › Saamu › 124

YCB · Orí 124 / 150

Saamu 124

1Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,” kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;

2ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa, nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,

3nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,

4nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,

5nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa.

6Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.

7Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ; okùn já àwa sì yọ.

8Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa, tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org