Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ìbínú

Ìgbésí ayé ojoojúmọ́

Ìbínú nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (41), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n

  • Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà; ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókèÒw 15:1
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 15:1Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.
  • Onísùúrù sàn ju ajagun lọÒw 16:32, Òw 14:29
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 16:32Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.
    Òw 14:29Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀, ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
  • Ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu dàbí ìlú tí odi rẹ̀ ti wóÒw 25:28
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 25:28Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.
  • Aláìgbọ́n tú gbogbo ìbínú rẹ̀ jáde; ọlọ́gbọ́n a kó o ní ìjánuÒw 29:11
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 29:11Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.
  • Bí fífún wàrà ti ń mú bọ́tà wá, rírú ìbínú sókè ń mú ìjà wáÒw 30:33
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 30:33Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá, tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde, bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”
  • Orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbéSu 7:9
    Àwọn ẹsẹ
    Su 7:9Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.
  • Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí; ibi nìkan ni ó ń mú wáSm 37:8
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 37:8Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀, má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
  • Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yínEf 4:26
    Àwọn ẹsẹ
    Ef 4:26Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yín,
  • Yára láti gbọ́, lọ́ra láti fọhùn, lọ́ra láti bínúJk 1:19–20
    Àwọn ẹsẹ
    Jk 1:19–20Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú; nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́.

Àpẹẹrẹ

  • Inú bí Kaini gidigidi, ó sì pa Abeli arákùnrin rẹ̀Gẹ 4:5–8
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 4:5–8ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojúrere wo Kaini àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Kaini gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro. Nígbà náà ni Olúwa bi Kaini pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro? Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.” Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.
  • Jakọbu sí Rakeli: “Èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run”Gẹ 30:2
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 30:2Inú sì bí Jakọbu sí i, ó sì wí pé, “Èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run, ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí?”
  • Inú bí Jakọbu, ó sì pe Labani ní ìjàGẹ 31:36
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 31:36Inú sì bí Jakọbu, ó sì pe Labani ní ìjà pé, “Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn?
  • Jakọbu: Simeoni àti Lefi “ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn”Gẹ 49:5–7
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 49:5–7“Simeoni àti Lefi jẹ́ arákùnrin— idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára. Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn, kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn, nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn, wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n. Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà! Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu, èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli.
  • Ọ̀gá Josẹfu bínú gidigidi sí ọ̀rọ̀ aya rẹ̀Gẹ 39:19
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 39:19Nígbà tí Potifari gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi.
  • Farao sí Mose: “Rí i dájú pé o kò wá sí iwájú mi mọ́”Ek 10:28
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 10:28Farao sọ fún Mose pé, “Kúrò ní iwájú mi! Rí i dájú pé o kò wá sí iwájú mi mọ́! Ọjọ́ tí ìwọ bá rí ojú mi ni ìwọ yóò kùú.”
  • Mose fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú FaraoEk 11:8
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 11:8Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, ‘Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀lé ọ!’ Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde.” Nígbà náà ni Mose fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Farao.
  • Mose fọ́ àwọn wàláà nígbà tí ó rí ẹgbọrọ màlúù náàEk 32:19
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 32:19Nígbà tí Mose dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì sọ wàláà ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ ní ìsàlẹ̀ òkè náà.
  • Mose lu àpáta lẹ́ẹ̀méjìNu 20:10–11
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 20:10–11Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?” Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.
  • Balaamu na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì sọ̀rọ̀Nu 22:27–29
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 22:27–29Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli Olúwa, ó sì jókòó ní abẹ́ Balaamu, inú sì bí i tó sì nà án pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀. Nígbà náà Olúwa ṣí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?” Balaamu sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, “Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ìbá pa ọ́ nísinsin yìí.”
  • Balaki fi ìbínú lu ọwọ́ rẹ̀ pọ̀ sí BalaamuNu 24:10
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 24:10Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.
  • Gideoni fi ìdáhùn pẹ̀lẹ́ tu àwọn ará Efraimu tí ń bínú lójúOn 8:1–3
    Àwọn ẹsẹ
    On 8:1–3Àwọn àgbàgbà ẹ̀yà Efraimu sì bínú gidigidi sí Gideoni wọ́n bi í léèrè pé, kí ló dé tí o fi ṣe irú èyí sí wa? Èéṣe tí ìwọ kò fi pè wá nígbà tí ìwọ kọ́kọ́ jáde lọ láti bá àwọn ará Midiani jagun? Ohùn ìbínú ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fiwé tiyín? Àṣàkù àjàrà Efraimu kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Abieseri lọ bí? Ọlọ́run ti fi Orebu àti Seebu àwọn olórí àwọn ará Midiani lé yín lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Mose ṣe tí ó tó fiwé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín?” Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọlẹ̀.
  • Eliabu bínú sí Dafidi àbúrò rẹ̀1Sa 17:28
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 17:28Nígbà tí Eliabu ẹ̀gbọ́n Dafidi gbọ́ nígbà tí ó ń bá ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀, ó bínú sí i, ó sì wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi sọ̀kalẹ̀ wá síbí? Àti pé ta ni ìwọ fi àwọn àgùntàn kékeré tókù ṣọ́ ní aginjù? Èmi mọ ìgbéraga rẹ, àti búburú ọkàn rẹ: ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá nìkan láti wòran ogun.”
  • Saulu ju ọ̀kọ̀ sí Jonatani ọmọ rẹ̀1Sa 20:30–34
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 20:30–34Ìbínú Saulu sì ru sí Jonatani ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jese fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú màmá rẹ tí ó bí ọ? Níwọ́n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láààyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹsẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀. Nísinsin yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọdọ̀ kú!” Jonatani béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?” Ṣùgbọ́n Saulu ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jonatani láti gún un pa. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dafidi ni. Bẹ́ẹ̀ ni Jonatani sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójútì í.
  • Ìbínú Dafidi ru sí ìtàn Natani nípa ọlọ́rọ̀ náà2Sa 12:5
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 12:5Ìbínú Dafidi sì ru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Natani pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkan yìí, kíkú ni yóò kú.
  • Ahabu wugbọ́, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì kọ̀ láti jẹun1Ọb 21:4
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 21:4Ahabu sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí Naboti ará Jesreeli sọ fún un; nítorí tí ó wí pé, “Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn baba mi.” Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun.
  • Naamani: odò Damasku kò ha dára ju Jordani lọ?2Ọb 5:11–12
    Àwọn ẹsẹ
    2Ọb 5:11–12Ṣùgbọ́n Naamani lọ pẹ̀lú ìbínú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn. Abana àti Fapari, odò Damasku kò ha dára ju gbogbo omi Israẹli lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú.
  • Asa ju aríran kan sínú túbú2Kro 16:10
    Àwọn ẹsẹ
    2Kro 16:10Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.
  • Ussiah bínú sí àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀2Kro 26:19
    Àwọn ẹsẹ
    2Kro 26:19Ussiah, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣetán láti sun tùràrí sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀.
  • Inú bí Ahaswerusi gidigidi nígbà tí ayaba Faṣti kọ̀ láti wáEt 1:12
    Àwọn ẹsẹ
    Et 1:12Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Faṣti kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidigidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.
  • Ìbínú kún Hamani nígbà tí Mordekai kò kúnlẹ̀Et 3:5
    Àwọn ẹsẹ
    Et 3:5Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú.
  • Inú bí Elihu sí Jobu àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́taJb 32:2–3
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 32:2–3Nígbà náà ni inú bí Elihu ọmọ Barakeli ará Busi, láti ìbátan ìdílé Ramu; ó bínú si Jobu nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre. Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jobu lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jobu lẹ́bi.
  • Nebukadnessari mú kí iná ìléru gbóná ní ìlọ́po méjeDa 3:13, Da 3:19
    Àwọn ẹsẹ
    Da 3:13Nígbà náà ni Nebukadnessari pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba.
    Da 3:19Nígbà náà ni Nebukadnessari bínú gidigidi sí Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀,
  • Jona nítorí ìtàkùn tí ó rọ: “láti bínú títí dé ikú”Jon 4:1, Jon 4:9
    Àwọn ẹsẹ
    Jon 4:1Ṣùgbọ́n ó ba Jona nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀.
    Jon 4:9Ọlọ́run sì wí fún Jona pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?” Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, o tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”
  • Inú bí Herodu gidigidi nígbà tí àwọn amòye tàn án jẹMt 2:16
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 2:16Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà.
  • Àwọn ará Sinagọgu Nasareti fẹ́ ti Jesu sílẹ̀ láti bèbè òkèLk 4:28–29
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 4:28–29Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú Sinagọgu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú bi wọ́n gidigidi, wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè sọ sílẹ̀ ní ògèdèǹgbé.
  • Jesu fi ìbínú wò wọ́n yíká nítorí líle àyà wọnMk 3:5
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 3:5Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.
  • Àjọ ìgbìmọ̀ bínú, wọ́n sì payínkeke sí StefanuÌṣe 7:54–58
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 7:54–58Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payínkeke sí i. Ṣùgbọ́n Stefanu, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jesu dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ó sì wí pé, “Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú, wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.
  • Paulu sí olórí àlùfáà: “ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun”Ìṣe 23:3
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 23:3Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!”

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.