Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Òbí

Ìgbésí ayé ojoojúmọ́

Òbí nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (42), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

Àyànfẹ́

  • Isaaki fẹ́ràn Esau; Rebeka fẹ́ràn JakọbuGẹ 25:28
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 25:28Isaaki, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran igbó fẹ́ràn Esau nítorí ẹran igbó tí Esau máa ń pa, ṣùgbọ́n Rebeka fẹ́ràn Jakọbu.
  • Rebeka gbèrò láti gba ìbùkún Isaaki fún JakọbuGẹ 27:6–10
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 27:6–10Rebeka sọ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń wí fún Esau ẹ̀gbọ́n rẹ pé, ‘Pa ẹran fún mi wá, kí o sì ṣe oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n ba à le súre fún ọ níwájú Olúwa kí èmi tó kú.’ Nísinsin yìí ọmọ mi, gbọ́ tèmi, kí o sì ṣe ohun tí èmi yóò wí fún ọ. Lọ sínú agbo ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì, kí ó lè ṣe oúnjẹ àdídùn fún baba rẹ, irú èyí tí ó fẹ́ràn dáradára. Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun ba à lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ, kí ó tó kú.”
  • Jakọbu kò rán Benjamini lọ, nítorí ẹ̀rù pé aburú lè ṣẹlẹ̀ sí iGẹ 42:4, Gẹ 42:38
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 42:4Ṣùgbọ́n Jakọbu kò rán Benjamini àbúrò Josẹfu lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bà á kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ sí i.
    Gẹ 42:38Ṣùgbọ́n Jakọbu wí pé, “Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Bí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí.”

Ìfẹ́ àti ìtọ́jú

  • Hagari jókòó níwọ̀n ìtafà kan, kò lè wo bí ọmọ rẹ̀ yóò ṣe kúGẹ 21:15–16
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 21:15–16Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó. Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà kan, nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún.
  • Ìyá àti arákùnrin Rebeka fẹ́ kí ó dúró ọjọ́ mẹ́wàá sí iGẹ 24:55
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 24:55Ṣùgbọ́n arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ fèsì pé, “A fẹ́ kí Rebeka wà pẹ̀lú wa fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá sí i, lẹ́yìn èyí, ìwọ le máa mu lọ.”
  • Ọkàn Jakọbu sọjí nígbà tí ó gbọ́ pé Josẹfu wà láààyèGẹ 45:26–28
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 45:26–28Wọn wí fún un pé, “Josẹfu ṣì wà láààyè! Kódà òun ni alákòóso ilẹ̀ Ejibiti.” Ẹnu ya Jakọbu, kò sì gbà wọ́n gbọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Josẹfu ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Josẹfu fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jakọbu, baba wọn sọ. Israẹli sì wí pé, “Mo gbà dájúdájú wí pé, Josẹfu ọmọ mi wà láààyè. Èmi ó lọ rí i kí n tó kú.”
  • Ìyá Mose fi í pamọ́ fún oṣù mẹ́ta, lẹ́yìn náà ó tẹ́ ẹ sínú apẹ̀rẹ̀Ek 2:2–3
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 2:2–3Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò Naili.
  • Manoa béèrè bí wọn yóò ti tọ́ ọmọ tí wọn yóò bíOn 13:8
    Àwọn ẹsẹ
    On 13:8Nígbà náà ni Manoa gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Háà Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.”
  • Àwọn òbí Samsoni kò fẹ́ kí ó fẹ́ obìnrin FilistiniOn 14:2–3
    Àwọn ẹsẹ
    On 14:2–3Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.” Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?” Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.”
  • Naomi fi ẹnu ko àwọn aya ọmọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ní kí wọ́n padà síléRu 1:8–9
    Àwọn ẹsẹ
    Ru 1:8–9Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Naomi wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, “Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú. Kí Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn.” Naomi sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé “Ó dìgbà,” wọ́n sì sọkún kíkankíkan.
  • Jobu dìde ní kùtùkùtù láti rú ẹbọ sísun fún ọmọ rẹ̀ kọ̀ọ̀kanJb 1:5
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 1:5Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.
  • Ọkàn Dafidi fà sí Absalomu2Sa 13:39
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 13:39Ọkàn Dafidi ọba sì fà gidigidi sí Absalomu, nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Amnoni: ó sá à ti kú.
  • Dafidi: “Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Absalomu fún mi”2Sa 18:5
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 18:5Ọba sì pàṣẹ fún Joabu àti Abiṣai àti Ittai pé, “Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Absalomu fún mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn balógun nítorí Absalomu.
  • Rispa ń ṣọ́ òkú àwọn ọmọ rẹ̀ kí ẹyẹ àti ẹranko má jẹ wọ́n2Sa 21:8, 2Sa 21:10
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 21:8Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rispa ọmọbìnrin Aiah bí fún Saulu, àní Ammoni àti Mefiboṣeti àwọn ọmọkùnrin márààrún ti Merabu, ọmọbìnrin Saulu, àwọn tí ó bí fún Adrieli ọmọ Barsillai ará Mehola.
    2Sa 21:10Rispa ọmọbìnrin Aiah sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sàn, tàbí àwọn ẹranko igbó lóru.
  • Ìyá tòótọ́ fẹ́ kí a fi ọmọ rẹ̀ fún ẹlòmíràn ju kí a pa á1Ọb 3:26
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 3:26Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láààyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!” Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ. Ẹ gé e sí méjì!”
  • Solomoni ní kí a gbé ìtẹ́ kan wá fún ìyá rẹ̀1Ọb 2:19
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 2:19Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.
  • Maria àti Josẹfu fi ìbànújẹ́ wá ọmọdékùnrin Jesu kiriLk 2:48
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 2:48Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n, ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.”
  • Ìyá Jesu dúró nítòsí àgbélébùúJh 19:25
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 19:25Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú,
  • Jairu bẹ̀bẹ̀ nítorí ọmọbìnrin rẹ̀ kékeréMk 5:23
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 5:23Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.”
  • Ọkùnrin ọlọ́lá kan: “sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú”Jh 4:49
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 4:49Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”
  • Baba ọmọkùnrin kan: “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́”Mk 9:24
    Àwọn ẹsẹ
    Mk 9:24Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”
  • Ìyá àwọn ọmọ Sebede béèrè ipò ọlá fún wọnMt 20:20–21
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 20:20–21Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀. Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?” Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”
  • Òbí ọmọ tí a bí ní afọ́jú: “ẹni tí ó ti dàgbà ni òun; ẹ bi í léèrè”Jh 9:20–23
    Àwọn ẹsẹ
    Jh 9:20–23Àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wí pé, “Àwa mọ̀ pé ọmọ wa ni èyí, àti pé a bí i ní afọ́jú, ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀, ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀, ẹni tí ó ti dàgbà ni òun; ẹ bi í léèrè, yóò wí fúnra rẹ̀.” Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn òbí rẹ̀ sọ, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù àwọn Júù: nítorí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan pé bí ẹnìkan bá jẹ́wọ́ pé Kristi ni, wọn ó yọ ọ́ kúrò nínú Sinagọgu. Nítorí èyí ni àwọn òbí rẹ̀ fi wí pé, “Ẹni tí ó dàgbà ni òun, ẹ bi í léèrè.”

Wọ́n gba ọmọ láàyè jù

  • Eli kò dá àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́kun1Sa 3:13
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 3:13Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun.
  • Dafidi kò bá Adonijah wí rí1Ọb 1:6
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 1:6(Baba rẹ̀ kò bà á nínú jẹ́ rí nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi hùwà báyìí?” Ó sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin, òun ni a bí lé Absalomu.)

Nínú Òfin

  • Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹEk 20:12
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 20:12Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
  • Ikú fún ẹni tí ó lu tàbí tí ó ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀Ek 21:15, Ek 21:17
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 21:15“Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.
    Ek 21:17“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.
  • Àwọn òbí ń ṣàlàyé àjọ ìrékọjá fún àwọn ọmọ wọnEk 12:26–27, Ek 13:8
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 12:26–27Ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni ohun tí àjọ yìí túmọ̀ sí fún un yín?’ Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí Olúwa ni, ẹni tí ó rékọjá ilé àwọn ọmọ Israẹli ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Ejibiti. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Ejibiti.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn.
    Ek 13:8Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’
  • Baba àti ìyá mú ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ wá sọ́dọ̀ àwọn àgbàgbàDe 21:18–20
    Àwọn ẹsẹ
    De 21:18–20Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí, baba àti ìyá rẹ̀ yóò gbá a mú, wọn yóò mu wá fún àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú u rẹ̀. Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtípara ni.”

Ọ̀rọ̀ inú Òwe nípa òbí

  • Tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ baba rẹ àti ẹ̀kọ́ ìyá rẹÒw 1:8
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 1:8Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.
  • Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùnÒw 10:1
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 10:1Àwọn òwe Solomoni. Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.
  • Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀Òw 13:22
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 13:22Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.
  • Má ṣe gan ìyá rẹ nígbà tí ó bá gbóÒw 23:22
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 23:22Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó.
  • Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ yọ̀Òw 23:24–25
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 23:24–25Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi: ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n, yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀. Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀, sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.
  • Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì pè é ní alábùkúnÒw 31:28
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 31:28Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un.

Nínú àwọn lẹ́tà

  • Àwọn òbí ni ó ń to ìṣúra jọ fún àwọn ọmọ, kì í ṣe àwọn ọmọ fún òbí2Kọ 12:14
    Àwọn ẹsẹ
    2Kọ 12:14Kíyèsi i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá, èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn.
  • Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínúEf 6:4, Kl 3:21
    Àwọn ẹsẹ
    Ef 6:4Àti ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa.
    Kl 3:21Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.