Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ijó

Ìgbésí ayé ojoojúmọ́

Ijó nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (21), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

  • Miriamu àti àwọn obìnrin jó pẹ̀lú ìlù lẹ́yìn tí wọ́n la òkun kọjáEk 15:20
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 15:20Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó.
  • Mose rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijóEk 32:19
    Àwọn ẹsẹ
    Ek 32:19Nígbà tí Mose dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì sọ wàláà ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ ní ìsàlẹ̀ òkè náà.
  • Ọmọbìnrin Jefta jáde wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú ijóOn 11:34
    Àwọn ẹsẹ
    On 11:34Nígbà tí Jefta padà sí ilé rẹ̀ ní Mispa, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú timbrili àti ijó. Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní: kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan.
  • Àwọn ọmọbìnrin Ṣilo ń jó níbi ayẹyẹ ọlọ́dọọdúnOn 21:19–21
    Àwọn ẹsẹ
    On 21:19–21Wọ́n sì wí pé, “Kíyèsi i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣilo ní ìhà àríwá Beteli àti ìhà ìlà-oòrùn òpópó náà tí ó gba Beteli kọjá sí Ṣekemu, àti sí ìhà gúúsù Lebona.” Wọ́n sì fi àṣẹ fún àwọn ará Benjamini pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fi ara pamọ́ nínú àwọn ọgbà àjàrà kí ẹ sì wà ní ìmúrasílẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin Ṣilo bá jáde láti lọ darapọ̀ fún ijó, kí ẹ yára jáde láti inú àwọn ọgbà àjàrà wọ̀n-ọn-nì kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbé aya kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ṣilo kí ẹ padà sí ilẹ̀ Benjamini.
  • Àwọn obìnrin ń jó, wọ́n ń kọrin: “Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀”1Sa 18:6–7, 1Sa 21:11
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 18:6–7Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti pa Filistini, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Israẹli wá láti pàdé ọba Saulu pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tambori àti ohun èlò orin olókùn. Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé, “Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀ Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbàárún ní tirẹ̀.”
    1Sa 21:11Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀. Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?”
  • Dafidi fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú àpótí ẹ̀rí2Sa 6:14–16
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 6:14–16Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú Olúwa; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè. Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.
  • Mikali rí Ọba Dafidi tí ń jó, ó sì kẹ́gàn rẹ̀1Kro 15:29
    Àwọn ẹsẹ
    1Kro 15:29Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa ti ń wọ ìlú ńlá Dafidi, Mikali ọmọbìnrin Saulu ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dafidi ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.
  • Àwọn ọmọdé ń jó kiri sí ohùn ìlù àti haapuJb 21:11–12
    Àwọn ẹsẹ
    Jb 21:11–12Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri. Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu; wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.
  • “Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi”Sm 30:11
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 30:11Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi; ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
  • Ẹ fi ìlù àti ijó yìn ínSm 149:3, Sm 150:4
    Àwọn ẹsẹ
    Sm 149:3Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀ jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
    Sm 150:4Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,
  • Ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jóSu 3:4
    Àwọn ẹsẹ
    Su 3:4Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó,
  • “orin ijó Mahanaimu”Orin 6:13
    Àwọn ẹsẹ
    Orin 6:13Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulamati; padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò. Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣulamati wò, bí ẹni pé orin ijó Mahanaimu?
  • Àwọn wúńdíá yóò jó pẹ̀lú ayọ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin àti àgbà pẹ̀lúJr 31:4, Jr 31:13
    Àwọn ẹsẹ
    Jr 31:4Èmi yóò tún gbé e yín sókè, àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli. Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé, ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.
    Jr 31:13Àwọn wúńdíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin. Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú. Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.
  • “ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa”Ẹj 5:15
    Àwọn ẹsẹ
    Ẹj 5:15Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa; ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.
  • Àwọn ọmọdé ní ọjà: “Àwa ń fun fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó”Mt 11:17
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 11:17“ ‘Àwa ń fun fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó; àwa kọrin ọ̀fọ̀ ẹ̀yin kò káàánú.’
  • Orin àti ijó fún ọmọ tí ó padà déLk 15:25
    Àwọn ẹsẹ
    Lk 15:25“Ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ èyí ẹ̀gbọ́n ti wà ní oko: bí ó sì ti ń bọ̀, tí ó súnmọ́ etí ilé, ó gbọ́ orin àti ijó.
  • Ọmọbìnrin Herodia jó níbi àsè ọjọ́ ìbí HeroduMt 14:6–7, Mk 6:22
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 14:6–7Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi. Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún.
    Mk 6:22Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Herodia wọlé láti jó. Inú Herodu àti àwọn àlejò rẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀. Ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé, “Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.”

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.