Ṣàwárí › Àkòrí › Àìsàn àti oníṣègùn
Ìgbésí ayé ojoojúmọ́
Àìsàn àti oníṣègùn nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (41), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
Oníṣègùn
- Àwọn oníṣègùn Josẹfu ṣe òkú Jakọbu lọ́jọ̀Gẹ 50:2
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 50:2Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Israẹli baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀.
- Asa, tí ààrùn wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, wá àwọn oníṣègùn2Kro 16:12, 1Ọb 15:23
Àwọn ẹsẹ
2Kro 16:12Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan.
1Ọb 15:23Ní ti ìyókù gbogbo ìṣe Asa, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, ààrùn ṣe é ní ẹsẹ̀ rẹ̀.
- Obìnrin tí ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá ná gbogbo ohun tí ó ní lọ́dọ̀ oníṣègùnMk 5:25–26, Lk 8:43
Àwọn ẹsẹ
Mk 5:25–26Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i.
Lk 8:43Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá,
- “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá”Mt 9:12
Àwọn ẹsẹ
Mt 9:12Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá.
- Òwe kan: “Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn!”Lk 4:23
Àwọn ẹsẹ
Lk 4:23Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”
- “Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn”Kl 4:14
Àwọn ẹsẹ
Kl 4:14Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dema ki í yín.
- “Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí? Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀?”Jr 8:22
Àwọn ẹsẹ
Jr 8:22Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí? Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀? Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?
Oògùn
- Ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ fún oówo Hesekiah2Ọb 20:7, Isa 38:21
- Ará Samaria náà di ọgbẹ́, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí iLk 10:34
Àwọn ẹsẹ
Lk 10:34Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkára rẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
- Wáìnì díẹ̀ nítorí inú àti àìlera ìgbàkúgbà1Tm 5:23
Àwọn ẹsẹ
1Tm 5:23Ma ṣe máa mu omi nìkan, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ, àti nítorí àìlera ìgbàkúgbà.
- A ń fi òróró kun àwọn aláìsànMk 6:13, Jk 5:14
- Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidiÒw 17:22
Àwọn ẹsẹ
Òw 17:22Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
Àpẹẹrẹ
- Jakọbu ṣàìsàn; Josẹfu mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì wáGẹ 48:1
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 48:1Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ ń ṣàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Manase àti Efraimu lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀.
- Ọ̀gá ẹrú ará Ejibiti kan fi í sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn1Sa 30:13
Àwọn ẹsẹ
1Sa 30:13Dafidi sì bi í léèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ? Àti níbo ni ìwọ ti wá?” Òun sì wí pé, “Ọmọ ará Ejibiti ni èmi, ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ará Amaleki. Olúwa mi fi mí sílẹ̀, nítorí pé láti ọjọ́ mẹ́ta ni èmi ti ṣe àìsàn.
- Ọmọ Jeroboamu ṣàìsàn; ìyá rẹ̀ para dà lọ sọ́dọ̀ wòlíì1Ọb 14:1–3
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 14:1–3Ní àkókò náà Abijah ọmọ Jeroboamu sì ṣàìsàn, Jeroboamu sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́n ní aya Jeroboamu. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣilo. Ahijah wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yìí. Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì sọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.”
- Ọmọ opó ní Sarefati ṣàìsàn1Ọb 17:17
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 17:17Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣe àìsàn, àìsàn náà sì le tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi kú.
- Ọmọ ará Ṣunemu nínú oko: “Orí mi! Orí mi!”2Ọb 4:18–20
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 4:18–20Ọmọ náà dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀, ó wà pẹ̀lú àwọn olùkórè. “Orí mi! Orí mi!” Ó wí fún baba rẹ̀. Baba rẹ̀ sọ fún ìránṣẹ́, “Gbé e lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀.” Lẹ́yìn ìgbà tí ìránṣẹ́ náà ti gbé e sókè tí ó sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ, ọmọ ọkùnrin náà jókòó sórí ẹsẹ̀ rẹ̀ títí ó fi di ọ̀sán gangan, nígbà náà ó sì kú.
- Ahasiah fi ara pa nígbà tí ó ṣubú láàrín fèrèsé2Ọb 1:2
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 1:2Nísinsin yìí Ahasiah ti ṣubú láàrín fèrèsé láti òkè yàrá rẹ̀ tí ó wà ní Samaria, ó sì fi ara pa. Ó sì rán oníṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni, bóyá èmi ó lè rí ìwòsàn ìfarapa yìí.”
- Beni-Hadadi ará Siria béèrè lọ́wọ́ Eliṣa bóyá òun yóò sàn2Ọb 8:7–8
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 8:7–8Eliṣa lọ sí Damasku, Beni-Hadadi ọba Siria ń ṣe àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé, “Ènìyàn Ọlọ́run ti wá láti gbogbo ọ̀nà òkè síbí,” ọba sì wí fún Hasaeli pé, “Mú ọrẹ lọ́wọ́ rẹ, sì lọ pàdé ènìyàn Ọlọ́run. Kí o sì béèrè Olúwa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn yìí?”
- Eliṣa ṣàìsàn àìsàn tí ó pa á2Ọb 13:14
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 13:14Nísinsin yìí, Eliṣa ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn, lọ́wọ́ èyí tí ó sì kú. Jehoaṣi ọba Israẹli lọ láti lọ wò ó, ó sì sọkún lórí rẹ̀. “Baba mi! Baba mi!” Ó sọkún. “Àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin Israẹli!”
- Hesekiah ṣàìsàn dé ojú ikú, lẹ́yìn náà ara rẹ̀ yáIsa 38:1, 2Ọb 20:7
Àwọn ẹsẹ
Isa 38:1Ní ọjọ́ náà ni Hesekiah ṣe àìsàn dé ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí Olúwa wí nìyìí: Palẹ̀ ilé è rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìsàn yìí.”
2Ọb 20:7Nígbà náà ni Isaiah wí pé, “Mú odidi ọ̀pọ̀tọ́.” Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fi lé oówo náà, ara rẹ̀ sì yá.
- Jobu, tí oówo bò, ń fi àpáàdì họ ara rẹ̀Jb 2:7–8
Àwọn ẹsẹ
Jb 2:7–8Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀. Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.
- Daniẹli ṣàárẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn ìran kanDa 8:27
Àwọn ẹsẹ
Da 8:27Èmi Daniẹli sì ṣe àárẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. Nígbà náà, mo dìde, mo sì ń bá iṣẹ́ ọba lọ. Ìran náà sì bà mí lẹ́rù, kò sì yé mi.
- Ìyá ìyàwó Peteru dùbúlẹ̀ àìsàn ibàMt 8:14, Lk 4:38
- Ọmọ ọkùnrin ọlọ́lá kan ṣàìsàn ní KapernaumuJh 4:46–47
Àwọn ẹsẹ
Jh 4:46–47Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.
- Ọmọkùnrin kan tí ó ní wárápá ń ṣubú sínú iná tàbí omiMt 17:15
Àwọn ẹsẹ
Mt 17:15“Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubú sínú iná tàbí sínú omi.
- Ọ̀pọ̀ aláìsàn dùbúlẹ̀ létí adágún Betisaida; ọkùnrin kan fún ọdún méjìdínlógójìJh 5:2–3, Jh 5:5
Àwọn ẹsẹ
Jh 5:2–3Adágún omi kan sì wà ní Jerusalẹmu, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Betisaida ní èdè Heberu, tí ó ní ẹnu-ọ̀nà márùn-ún. Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dùbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti aláàrùn ẹ̀gbà.
Jh 5:5Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjìdínlógójì.
- Ọkùnrin tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ ni a ń gbé sí ẹnu-ọ̀nà tẹmpili lójoojúmọ́Ìṣe 3:2
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 3:2Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ.
- Lasaru ará Betani ṣàìsàn; àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí JesuJh 11:1–3
Àwọn ẹsẹ
Jh 11:1–3Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀. Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá. Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”
- Dọkasi ṣàìsàn, ó sì kúÌṣe 9:37
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 9:37Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òkè.
- Baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìnÌṣe 28:8
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 28:8Ó sì ṣe, baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.
- Epafiroditu ṣàìsàn títí dé ojú ikúFp 2:25–27
Àwọn ẹsẹ
Fp 2:25–27Mo kà á sí pé n kò lè ṣàìrán Epafiroditu arákùnrin mi sí yín, àti olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ mi, àti ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ mi, ìránṣẹ́ yín pẹ̀lú, tí ẹ rán láti ṣè ránṣẹ́ fún mi nínú àìní mi. Nítorí tí ọkàn rẹ̀ fà sí gbogbo yín, ó sì kún fún ìbànújẹ́, nítorí tí ẹ̀yin gbọ́ pé ó ṣe àìsàn. Nítòótọ́ ni ó ti ṣe àìsàn títí dé ojú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣàánú fún un; kì í sì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lórí ìbànújẹ́.
- Paulu kọ́kọ́ wàásù ní Galatia nítorí àìleraGa 4:13–14
Àwọn ẹsẹ
Ga 4:13–14Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìyìnrere fún yín ní àkọ́kọ́. Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí angẹli Ọlọ́run, àní bí Kristi Jesu.
- Paulu fi Tirofimu sílẹ̀ ní Miletu nínú àìsàn2Tm 4:20
Àwọn ẹsẹ
2Tm 4:20Erastu wà ní Kọrinti: ṣùgbọ́n mo fi Tirofimu sílẹ̀ ni Miletu nínú àìsàn.
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.