Ṣàwárí › Àkòrí › Tábìlì àti oúnjẹ
Ìgbésí ayé ojoojúmọ́
Tábìlì àti oúnjẹ nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (36), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
Tábìlì
- Ibùsùn, tábìlì, àga àti fìtílà nínú yàrá kékeré Eliṣa2Ọb 4:10
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 4:10Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùsùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti fìtílà fún un. Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa.”
- Àádọ́rin ọba ń ṣa èérún oúnjẹ lábẹ́ tábìlì Adoni-BesekiOn 1:7
Àwọn ẹsẹ
On 1:7Nígbà náà ni Adoni-Beseki wí pé, “Àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Ọlọ́run ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn.” Wọ́n sì mú un wá sí Jerusalẹmu, ó sì kú síbẹ̀.
- Tábìlì àgọ́ ìpàdé: igi kasia tí a fi wúrà bò, pẹ̀lú ọ̀pá fún gbígbéEk 25:23–28
Àwọn ẹsẹ
Ek 25:23–28“Fi igi kasia kan tábìlì: ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní gíga. Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ìwọ ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. Ìwọ sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà fún ibi ọ̀pá láti máa fi gbé tábìlì náà. Ìwọ ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ìwọ ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà.
- Ìṣù àkàrà méjìlá ní ìlà méjì lórí tábìlì wúrà ní ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kanLe 24:5–8
Àwọn ẹsẹ
Le 24:5–8“Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan. Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fà mẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa. Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ sísun sí Olúwa. Àkàrà yìí ni kí ẹ gbé wá síwájú Olúwa nígbàkígbà, lọ́ṣọ̀ọ̀ṣẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé.
- Tábìlì wúrà àti tábìlì fàdákà fún ilé Olúwa1Kro 28:16
Àwọn ẹsẹ
1Kro 28:16Ìwọ̀n ti wúrà fun tábìlì, tábìlì fún àkàrà tí a yà sọ́tọ̀; ìwọ̀n fàdákà fún àwọn tábìlì fàdákà;
- Jesu ti tábìlì àwọn onípàṣípàrọ̀ owó ṣubúJh 2:15
Àwọn ẹsẹ
Jh 2:15Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú.
- Àwọn ajá ń jẹ èrúnrún tí ó bọ́ láti orí tábìlìMt 15:27, Mk 7:28
- Lasaru ń fẹ́ èérún láti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ (òwe kan)Lk 16:21
Àwọn ẹsẹ
Lk 16:21Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun, àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.
- Àwọn ọmọ rẹ dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ káSm 128:3
Àwọn ẹsẹ
Sm 128:3Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ; àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
Jíjókòó àti fífẹ̀yìn tì
- Abrahamu dúró nítòsí àwọn àlejò rẹ̀ lábẹ́ igi bí wọ́n ti ń jẹunGẹ 18:8
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 18:8Ó sì mú wàrà àti mílíìkì àti màlúù tí ó ti pèsè, ó sì gbé síwájú wọn. Ó sì dúró nítòsí wọn lábẹ́ igi bí wọn ti ń jẹ ẹ́.
- Rutu jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè ní àkókò oúnjẹRu 2:14
Àwọn ẹsẹ
Ru 2:14Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Boasi sọ fún Rutu pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yìí kí o sì fi run wáìnì kíkan.” Òun sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Boasi sì fún un ní ọkà yíyan. Òun sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù.
- Hamani ṣubú sórí àga tí Esteri ayaba fẹ̀yìn tìEt 7:8
Àwọn ẹsẹ
Et 7:8Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngàn àsè náà, Hamani ṣubú sórí àga tí Esteri ayaba fẹ̀yìn tì. Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?” Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hamani lójú.
- Jesu jókòó níbi tábìlì pẹ̀lú àwọn méjìláMt 26:20
Àwọn ẹsẹ
Mt 26:20Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jesu ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá,
- Ọmọ-ẹ̀yìn kan tí ó rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jesu fẹ̀yìn tì láti bi í léèrèJh 13:23–25
Àwọn ẹsẹ
Jh 13:23–25Ǹjẹ́ ẹnìkan rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jesu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí Jesu fẹ́ràn. Nítorí náà ni Simoni Peteru ṣàpẹẹrẹ sí i, ó sì wí fún un pé, “Wí fún wa ti ẹni tí o ń sọ.” Ẹni tí ó ń rọ̀gún ní àyà Jesu wí fún un pé, “Olúwa, ta ni í ṣe?”
- Farisi kan pe Jesu wá jẹun, ó sì jókòó níbi tábìlìLk 7:36
Àwọn ẹsẹ
Lk 7:36Farisi kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisi náà lọ ó sì jókòó láti jẹun.
- Marta ń ṣe ìránṣẹ́, Lasaru sì jókòó níbi tábìlì pẹ̀lú JesuJh 12:2
Àwọn ẹsẹ
Jh 12:2Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀. Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́, ṣùgbọ́n Lasaru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀.
- Ẹgbẹ̀rún márùn-ún jókòó lórí koríko ní ẹgbẹ́ ọgọọgọ́rùn-ún àti àádọ́taMk 6:39–40, Lk 9:14
Àwọn ẹsẹ
Mk 6:39–40Nígbà náà ni Jesu sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ lórí koríko. Lẹ́sẹ̀kan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọọgọ́rùn-ún.
Lk 9:14Nítorí àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn. Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí wọ́n mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ní àràádọ́ta.”
Ta ni ó bá ta jẹun
- Dafidi kò wá sí tábìlì Saulu; Jonatani fi ìbínú kúrò níbẹ̀1Sa 20:29, 1Sa 20:34
Àwọn ẹsẹ
1Sa 20:29Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nìyìí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.”
1Sa 20:34Bẹ́ẹ̀ ni Jonatani sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójútì í.
- Àwọn ìjòyè agbègbè ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo àwọn tí ń wá sí tábìlì Solomoni1Ọb 4:27
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 4:27Àwọn ìjòyè agbègbè, olúkúlùkù ní oṣù rẹ̀, ń pèsè oúnjẹ fún Solomoni ọba àti gbogbo àwọn tí ń wá sí ibi tábìlì ọba, wọ́n sì rí i pé ohun kankan kò ṣẹ́kù.
- Tábìlì Solomoni àti ìjókòó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ya ayaba Ṣeba lẹ́nu1Ọb 10:4–5
Àwọn ẹsẹ
1Ọb 10:4–5Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́. Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!
- Ọ̀pọ̀ Júù àti ìjòyè ń jẹun ní tábìlì Nehemiah, láìka àwọn àlejòNe 5:17
Àwọn ẹsẹ
Ne 5:17Síwájú sí í, àádọ́jọ àwọn Júù àti àwọn ìjòyè jẹun lórí tábìlì mi, àti pẹ̀lú àwọn tí wọ́n wá bá wa láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká.
- Jehoiakini ń jẹun níwájú ọba Babeli ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀2Ọb 25:29
Àwọn ẹsẹ
2Ọb 25:29Ó sì pàrọ̀ àwọn aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
- Jesu bá àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun ní ilé MatiuMt 9:10–11, Mk 2:15–16, Lk 15:2
Àwọn ẹsẹ
Mt 9:10–11Ó sì ṣe, bí Jesu tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Matiu, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nígbà tí àwọn Farisi sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èéṣe tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun pọ̀?”
Mk 2:15–16Ó sì ṣe, bí ó sì ti jókòó ti oúnjẹ ni ilé Lefi, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jesu jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí tiwọn pọ̀ tiwọn tẹ̀lé e. Nígbà tí àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èétirí tí ó fi ń bá àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”
Lk 15:2Àti àwọn Farisi àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”
- “ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì”Lk 22:21
Àwọn ẹsẹ
Lk 22:21Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì.
- Jesu tí ó jíǹde: “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀”Jh 21:12
Àwọn ẹsẹ
Jh 21:12Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ ṣe?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni.
- Àwọn onígbàgbọ́ àkọ́kọ́ ń bu àkàrà láti ilé dé iléÌṣe 2:46
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 2:46Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹmpili. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn.
- Àwọn méjìlá kò fẹ́ fi ìwàásù sílẹ̀ láti máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlìÌṣe 6:2
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 6:2Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì.
- A bá Peteru wí nítorí ó bá àwọn aláìkọlà jẹunÌṣe 11:3
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 11:3wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”
- Ní Antioku, Peteru fàsẹ́yìn kúrò nínú bíbá àwọn aláìkọlà jẹunGa 2:12
Àwọn ẹsẹ
Ga 2:12Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà.
- Onítúbú gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú Paulu àti SilaÌṣe 16:34
Àwọn ẹsẹ
Ìṣe 16:34Ó sì mú wọn wá sí ilé rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́.
- Aláìgbàgbọ́ pè ọ́? Jẹ ohunkóhun tí a bá gbé kalẹ̀ fún ọ1Kọ 10:27
Àwọn ẹsẹ
1Kọ 10:27Bí ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àsè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àsè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn.
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.