Ṣàwárí › Àkòrí › Ọdẹ àti ìdẹkùn
Ìgbésí ayé ojoojúmọ́
Ọdẹ àti ìdẹkùn nínú Bíbélì
Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (14), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.
- Nimrodu, “ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa”Gẹ 10:9
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 10:9Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.”
- Iṣmaeli dàgbà nínú ijù, ó sì di tafàtafàGẹ 21:20
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 21:20Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ijù, ó sì di tafàtafà.
- Esau di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn okoGẹ 25:27
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 25:27Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Esau sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jakọbu sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń gbé láàrín ìlú.
- Isaaki fẹ́ràn ẹran igbó, ó sì fẹ́ràn EsauGẹ 25:28
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 25:28Isaaki, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran igbó fẹ́ràn Esau nítorí ẹran igbó tí Esau máa ń pa, ṣùgbọ́n Rebeka fẹ́ràn Jakọbu.
- Isaaki rán Esau jáde pẹ̀lú apó àti ọrun láti pa ẹran igbóGẹ 27:3–5
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 27:3–5Nítorí náà, mú ohun èlò ọdẹ rẹ, apó àti ọrún, nísinsin yìí kí o sì lọ pa ẹran wá fún mi nínú igbó. Kí o sì ṣe ẹran àdídùn fún mi, irú èyí tí mo fẹ́ràn, kí o gbe wá fún mi kí n jẹ, kí n sì súre fún ọ kí n tó kú.” Ṣùgbọ́n Rebeka ń fetí léko gbọ́ nígbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí náà, nígbà ti Esau ti ṣe ọdẹ lọ sínú igbó,
- Esau dé láti oko ọdẹ lẹ́yìn tí ìbùkún ti lọGẹ 27:30–33
Àwọn ẹsẹ
Gẹ 27:30–33Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé. Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.” Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.” Nígbà náà ni Isaaki wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un, sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un!”
Nínú Òfin
Ìdẹkùn àti àwọ̀n
- Àwọ̀n, okùn dídẹ, tàkúté, ìdẹkùn àti okùn tí a fi pamọ́ sínú ilẹ̀Jb 18:8–10
Àwọn ẹsẹ
Jb 18:8–10Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n, ó sì rìn lórí okùn dídẹ. Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀, àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀. A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sì wà ọ̀fìn fún un lójú ọ̀nà.
- Etu tí a dé mọ́nú àwọ̀nIsa 51:20
Àwọn ẹsẹ
Isa 51:20Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú; wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà, gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n. Ìbínú Olúwa ti kún inú wọn fọ́fọ́ àti ìbáwí Ọlọ́run yín.
- Àwọn pẹyẹpẹyẹ ń ba ní ibùba, wọ́n sì ń dẹ pàkútéJr 5:26
Àwọn ẹsẹ
Jr 5:26“Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ, àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.
- Wọ́n na okùn àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà, wọ́n sì dẹ ìdẹkùnSm 140:5
Àwọn ẹsẹ
Sm 140:5Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn: wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà; wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.
Àfiwé
- Dafidi: bí ẹni tí ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá1Sa 26:20
Àwọn ẹsẹ
1Sa 26:20Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó sàn sílẹ̀ níwájú Olúwa; nítorí ọba Israẹli jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.”
- “Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ”Ẹj 3:52
Àwọn ẹsẹ
Ẹj 3:52Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ.
- A gbà á “nínú ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ”Sm 91:3
Àwọn ẹsẹ
Sm 91:3Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.
Orísun
Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.