Bible Explorer

Ṣàwárí › Àkòrí › Ìmutípara

Ìgbésí ayé ojoojúmọ́

Ìmutípara nínú Bíbélì

Àwọn àyọkà Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (30), ìlà sí ìlà, láti inú Nave’s Topical Bible.

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n

  • Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ni ọtí líleÒw 20:1
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 20:1Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
  • Ta ni ojú rẹ̀ pọ́n? Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnìÒw 23:29–35
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 23:29–35Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́? Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí? Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì; àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò. Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n, nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago, tí a gbé e mì, tí ó ń dùn. Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀. Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin, àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà. Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárín Òkun, tàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀. Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí; wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀: nígbà wo ni èmi ó jí? Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”
  • Ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun yóò di tálákàÒw 23:20–21
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 23:20–21Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí; àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun; nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà; ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.
  • Kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnìÒw 31:4–7
    Àwọn ẹsẹ
    Òw 31:4–7“Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli, kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì, kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle, kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí, kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n. Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora. Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.
  • Ègbé ni fún àwọn tí ń dìde ní kùtùkùtù láti lépa ọtí líleIsa 5:11–12
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 5:11–12Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti lépa ọtí líle, tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́ títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì. Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn, ṣaworo òun fèrè àti wáìnì, ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
  • “akọni nínú wáìnì mímu àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí”Isa 5:22
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 5:22Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,
  • Àlùfáà àti wòlíì ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líleIsa 28:7–8
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 28:7–8Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì wọ́n pòòrì fún ọtí líle, àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle, wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran, wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá. Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.
  • “ọ̀la yóò sì dàbí òní, tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ”Isa 56:12
    Àwọn ẹsẹ
    Isa 56:12Igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ni wí pé, “Wá, fún mi ní ọtí wáìnì! Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yó ọ̀la yóò sì dàbí òní, tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
  • Wáìnì ń gba òye lọHo 4:11
    Àwọn ẹsẹ
    Ho 4:11fún àgbèrè; wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́, àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù.
  • Wọ́n ń mu wáìnì ní ẹ̀kún ọpọ́nAm 6:6
    Àwọn ẹsẹ
    Am 6:6Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro.
  • Ègbé ni fún ẹni tí ó ń mú aládùúgbò rẹ̀ mu àmuparaHk 2:15
    Àwọn ẹsẹ
    Hk 2:15“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara, kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.”
  • Àwọn tí ń mu àmupara, a máa mú un ní òru1Tẹ 5:7
    Àwọn ẹsẹ
    1Tẹ 5:7Nítorí àwọn tí wọ́n ń sùn, a máa sùn ní òru, àwọn ẹni tí ń mu àmupara, a máa mú un ní òru.
  • Ẹ má ṣe mu wáìnì ní àmuparaEf 5:18, Ro 13:13, Lk 21:34
    Àwọn ẹsẹ
    Ef 5:18Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.
    Ro 13:13Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara.
    Lk 21:34“Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn.

Nínú Òfin

  • Òbí lè fi ẹ̀sùn kan ọmọ níwájú àgbàgbà: “Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtípara ni”De 21:20
    Àwọn ẹsẹ
    De 21:20Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtípara ni.”
  • Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ mu wáìnì nígbà tí wọ́n bá ń lọ inú àgọ́ ìpàdéLe 10:9
    Àwọn ẹsẹ
    Le 10:9“Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkígbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kù ú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran.
  • Nasiri yàgò fún wáìnì àti ọtí líleNu 6:3
    Àwọn ẹsẹ
    Nu 6:3irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èso àjàrà tútù tàbí gbígbẹ.

Àpẹẹrẹ

  • Noa gbin ọgbà àjàrà, ó sì mu àmuparaGẹ 9:20–21
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 9:20–21Noa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà. Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀.
  • Àwọn ọmọbìnrin Lọti rọ baba wọn ní ọtí yóGẹ 19:32–33
    Àwọn ẹsẹ
    Gẹ 19:32–33Wá, jẹ́ kí a mú baba wa mu ọtí yó, kí ó ba à le bá wa lòpọ̀, kí àwa kí ó lè bí ọmọ, kí ìran wa má ba à parẹ́.” Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó. Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lòpọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìde.
  • Nabali mu àmupara níbi àsè rẹ̀, kò gbọ́ nǹkan títí di òwúrọ̀1Sa 25:36–37
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 25:36–37Abigaili sì tọ Nabali wá, sì wò ó, òun sì ṣe àsè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àsè ọba: inú Nabali sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara; òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀: títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ Ó sì ṣe; ni òwúrọ̀, nígbà ti ọtí náà si dá tán lójú Nabali, obìnrin rẹ̀ sì ro nǹkan wọ̀nyí fún un, ọkàn rẹ sì kú nínú rẹ̀, òun sì dàbí òkúta.
  • Dafidi mú kí ọtí pa Uriah, ṣùgbọ́n Uriah kò lọ sí ilé rẹ̀2Sa 11:13
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 11:13Dafidi sì pè é, ó sì jẹ, ó sì mú nítorí rẹ̀; ó sì mu kí ọtí pa á; òun sì jáde ní alẹ́ lọ sí ibùsùn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.
  • Absalomu dúró títí ọtí-wáinì yóò fi mú ọkàn Amnoni dùn2Sa 13:28
    Àwọn ẹsẹ
    2Sa 13:28Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.”
  • Simri pa Ọba Ela nígbà tí ó ń mu àmupara1Ọb 16:9–10
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 16:9–10Simri, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, olórí ìdajì kẹ̀kẹ́ rẹ̀, dìtẹ̀ sí i. Ela sì wà ní Tirsa nígbà náà, ó sì mu àmupara ní ilé Arsa, ìríjú ilé rẹ̀ ni Tirsa. Simri sì wọlé, ó sì kọlù ú, ó sì pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Asa, ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
  • Beni-Hadadi àti ọba 32 ń mu àmupara nínú àgọ́ ní ọ̀sán gangan1Ọb 20:16
    Àwọn ẹsẹ
    1Ọb 20:16Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Beni-Hadadi àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmupara nínú àgọ́.
  • Ahaswerusi, tí wáìnì mú inú rẹ̀ dùn, ránṣẹ́ pe ayaba FaṣtiEt 1:10–11
    Àwọn ẹsẹ
    Et 1:10–11Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Mehumani, Bista, Harbona, Bigta àti Abagta, Setari àti Karkasi, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún Ahaswerusi. Kí wọn mú ayaba Faṣti wá síwájú rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà.
  • Belṣassari mu nínú ohun èlò tẹmpili JerusalẹmuDa 5:1–4
    Àwọn ẹsẹ
    Da 5:1–4Belṣassari, ọba ṣe àsè ńlá fún ẹgbẹ̀rún (1,000) kan nínú àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó sì mu wáìnì pẹ̀lú u wọn. Bí Belṣassari ṣe ń mu wáìnì, ó pàṣẹ pé kí wọn kó kọ́ọ̀bù wúrà àti ti fàdákà wá, èyí tí Nebukadnessari baba rẹ̀ kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, kí ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ kí ó ba à le fi mu wáìnì. Wọ́n sì kó kọ́ọ̀bù wúrà àti fàdákà àti fàdákà èyí tí wọ́n kó jáde láti inú tẹmpili, ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀, sì fi mu wáìnì. Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta.

A rò pé wọ́n mu ọtí yó

  • Eli rò pé Hana tí ń gbàdúrà ní ìkọ̀kọ̀ ti mu ọtí yó1Sa 1:13–15
    Àwọn ẹsẹ
    1Sa 1:13–15Hana ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀. Eli rò wí pé ó ti mu ọtí yó. Eli sì wí fún un pé, “Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó? Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò.” Hana dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi, èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni.
  • A pe Jesu ní “Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí”Mt 11:19
    Àwọn ẹsẹ
    Mt 11:19Ọmọ Ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ‘Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.”
  • Ní Pentikosti: “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì tuntun”Ìṣe 2:13–15
    Àwọn ẹsẹ
    Ìṣe 2:13–15Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn ń ṣẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì tuntun”. Nígbà náà ni Peteru dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin; kí ẹ sì fetísí ọ̀rọ̀ mi. Àwọn wọ̀nyí kò mu ọtí yó, bí ẹ̀yin tí rò ó; wákàtí kẹta ọjọ́ sá à ni èyí.

Orísun

Láti Nave’s Topical Bible (Orville J. Nave, 1896; ohun ìní gbogbo ènìyàn): a yan àwọn àkòrí, a ké àwọn ìlà kúrú, a sì kọ wọ́n ní ọ̀rọ̀ òde òní, a fi àwọn ìlà ìtumọ̀ sílẹ̀; a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ kọ̀ọ̀kan.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.