YCB · Orí 128 / 150
Saamu 128
1Orin fún ìgòkè. Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa: tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
2Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.
3Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ; àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
4Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà, tí ó bẹ̀rù Olúwa.
5Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá, kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
6Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ. Láti àlàáfíà lára Israẹli.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org