Ṣàwárí › Àwọn Ìyìnrere lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn › Ìjìyà Jesu
Àwọn Ìyìnrere lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn · Ìjìyà Jesu
Ìdìtẹ̀ láti pa Jesu
Mt 26:1–5 · Mk 14:1–2 · Lk 22:1–2
Mt 26:1–51Nígbà tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé,
2“Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”
3Ní àsìkò tí Jesu ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfáà náà tí à ń pè ní Kaiafa.
4Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jesu pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á.
5Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”
Mk 14:1–21Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni àjọ ìrékọjá àti tí àìwúkàrà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jesu ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á.
2Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.”
Lk 22:1–21Àjọ ọdún àìwúkàrà tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́ẹ́rẹ́.
2Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn.
A sàmì sí: àwọn ọ̀rọ̀ tí gbogbo àkọsílẹ̀ ní, nínú ìtumọ̀ tí o ń kà. A kò sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wọ́pọ̀ jùlọ (“àti”, “ó”); ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ọ̀nà mìíràn lè máà ní àmì.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · A fi ọwọ́ yan àwọn abala tí ó jọra láti inú ọ̀rọ̀ Bíbélì, a sì ṣàyẹ̀wò wọn pẹ̀lú ìtọ́kasí OpenBible.info (CC BY). Ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà tàbí ọ̀rọ̀ kan náà nìkan ni a fi sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn. OpenBible.info · CC BY