Bible Explorer

Bíbélì › Saamu › 4

YCB · Orí 4 / 150

Saamu 4

1Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi. Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, ìwọ Ọlọ́run òdodo mi. Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi; ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

2Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú? Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?

3Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

4Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀, nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín, ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.

5Ẹ rú ẹbọ òdodo kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

6Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?” Olúwa, jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,

7Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.

8Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà, nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni o mú mi gbé láìléwu.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org