Bible Explorer

Bíbélì › Saamu › 28

YCB · Orí 28 / 150

Saamu 28

1Ti Dafidi. Ìwọ Olúwa, mo ké pe àpáta mi. Má ṣe kọ etí dídi sí mi. Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi, èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.

2Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú, bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè sí Ibi Mímọ́ rẹ Jùlọ.

3Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti, pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.

4San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn àti fún iṣẹ́ ibi wọn; gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn; kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.

5Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ òun ó rún wọn wọlẹ̀ kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.

6Alábùkún fún ni Olúwa! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7Olúwa ni agbára mi àti asà mi; nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀ àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

8Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀ òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀.

9Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ; di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org