YCB · Orí 125 / 150
Saamu 125
1Orin fún ìgòkè. Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni, tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.
2Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo; kí àwọn olódodo kí ó máa ba à fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.
4Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere, àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
5Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn; Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org