YCB · Orí 123 / 150
Saamu 123
1Orin fún ìgòkè. Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.
2Kíyèsi, bí ojú àwọn ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa.
3Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa; nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
4Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn onírera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org