Bible Explorer

Bíbélì › Saamu › 13

YCB · Orí 13 / 150

Saamu 13

1Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé? Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?

2Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà, àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi? Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?

3Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi. Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú.

4Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,” àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.

5Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà; ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

6Èmi ó máa kọrin sí Olúwa, nítorí ó dára sí mi.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org