Bible Explorer

Bíbélì › Saamu › 134

YCB · Orí 134 / 150

Saamu 134

1Orin ìgòkè. Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.

2Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́, kí ẹ sì fi ìbùkún fún Olúwa.

3Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé, kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org