Bible Explorer

Bíbélì › Saamu › 54

YCB · Orí 54 / 150

Saamu 54

1Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí àwọn ará Sifi lọ sọ fún Saulu pé, “Dafidi sá pamọ́ sọ́dọ̀ wa?” Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ: dá mi láre nípa agbára rẹ.

2Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run; fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

3Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí. Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa, àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.

4Kíyèsi i Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi; Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró, pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

5Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi; pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

6Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ, èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa, nítorí tí ó dára.

7Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org