Bible Explorer

Bíbélì › Saamu › 23

YCB · Orí 23 / 150

Saamu 23

1Saamu ti Dafidi. Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.

2Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù, Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,

3Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò. Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.

4Bí mo tilẹ̀ ń rìn láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan, nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ, wọ́n ń tù mí nínú.

5Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi. Ìwọ ta òróró sí mi ní orí; ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.

6Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo, èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa títí láéláé.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org