Ṣàwárí › Àwọn Ìyìnrere lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn › Ẹ̀kọ́
Àwọn Ìyìnrere lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn · Ẹ̀kọ́
Àdúrà Olúwa
Mt 6:9–13 · Lk 11:2–4
Mt 6:9–139“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín,
10kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe ní ayé bí ti ọ̀run.
11Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí.
12Ẹ dárí gbèsè wa jì wá, Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa,
13Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi. Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’
Lk 11:2–42Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ yín. Kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe, bí i ti ọrun, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.
3Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.
4Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá; nítorí àwa tìkára wa pẹ̀lú a máa dáríjì olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè, Má sì fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni búburú ni.’ ”
A sàmì sí: àwọn ọ̀rọ̀ tí gbogbo àkọsílẹ̀ ní, nínú ìtumọ̀ tí o ń kà. A kò sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wọ́pọ̀ jùlọ (“àti”, “ó”); ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ọ̀nà mìíràn lè máà ní àmì.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · A fi ọwọ́ yan àwọn abala tí ó jọra láti inú ọ̀rọ̀ Bíbélì, a sì ṣàyẹ̀wò wọn pẹ̀lú ìtọ́kasí OpenBible.info (CC BY). Ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà tàbí ọ̀rọ̀ kan náà nìkan ni a fi sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn. OpenBible.info · CC BY