Ṣàwárí › Àwọn Ìyìnrere lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn › Ní Jerusalẹmu
Àwọn Ìyìnrere lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn · Ní Jerusalẹmu
Ọrẹ opó
Mk 12:41–44 · Lk 21:1–4
Mk 12:41–4441Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i.
42Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.
43Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ.
44Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”
Lk 21:1–41Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra.
2Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀.
3Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ,
4nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.”
A sàmì sí: àwọn ọ̀rọ̀ tí gbogbo àkọsílẹ̀ ní, nínú ìtumọ̀ tí o ń kà. A kò sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wọ́pọ̀ jùlọ (“àti”, “ó”); ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ọ̀nà mìíràn lè máà ní àmì.
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · A fi ọwọ́ yan àwọn abala tí ó jọra láti inú ọ̀rọ̀ Bíbélì, a sì ṣàyẹ̀wò wọn pẹ̀lú ìtọ́kasí OpenBible.info (CC BY). Ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà tàbí ọ̀rọ̀ kan náà nìkan ni a fi sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn. OpenBible.info · CC BY