Ṣàwárí › Ìrìn-àjò › Ìrìn-àjò Abrahamu
Ìrìn-àjò
Ìrìn-àjò Abrahamu
Láti Uri dé Kenaani · Iye ibùdó: 12 · ≈ 2,730 km ní ìlà tààrà
Àwọn ibùdó
- 1
UriGẹ 11:31Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.
- 2
HaraniGẹ 11:31Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.
- 3
ṢekemuGẹ 12:6Abramu sì rìn la ilẹ̀ náà já títí dé ibi igi ńlá kan tí à ń pè ni More ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani sì wà ní ilẹ̀ náà.
- 4
BeteliGẹ 12:8Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.
- 5
EjibitiGẹ 12:10Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, Abramu sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí ìyàn náà mú gidigidi.
- 6
BeteliGẹ 13:3Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai.
- 7
HebroniGẹ 13:18Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa.
- 8
GerariGẹ 20:1Abrahamu sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìhà gúúsù ó sì ń gbé ní agbede-méjì Kadeṣi àti Ṣuri; ó sì gbé ní ìlú Gerari fún ìgbà díẹ̀.
- 9
BeerṣebaGẹ 21:31Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Beerṣeba nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra.
- 10
MoriaGẹ 22:2Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Moria, kí o sì fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ.”
- 11
BeerṣebaGẹ 22:19Nígbà náà ni Abrahamu padà tọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Beerṣeba. Abrahamu sì jókòó ní Beerṣeba.
- 12
HebroniGẹ 23:2Ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara.
Àwọn ìlà so àwọn ibùdó pọ̀ ní ìtẹ̀léra ọ̀rọ̀ Bíbélì — a kò mọ àwọn ọ̀nà gan-an. Ìlà tí a gé: nínú ọkọ̀ ojú omi. Àwọ̀ tí kò ṣe kedere: a kò mọ̀ dájú ibi náà.
Àmì kọ̀ọ̀kan ni ibi tí ó ṣeé ṣe jùlọ (OpenBible.info); àmì tí àwọ̀ rẹ̀ kò ṣe kedere túmọ̀ sí pé a kò mọ̀ dájú. Àwọn ibi tí a kò mọ ibi tí wọ́n wà kò sí lórí máàpù.
Ibi tí wọ́n wà: OpenBible.info Bible Geocoding Data (CC BY 4.0).
Ààlà ilẹ̀: Natural Earth (ohun ìní gbogbo ènìyàn).