Bible Explorer Gba àpù

Ojú-ìwé àkọ́kọ́ › Àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ó gbajúmọ̀ › Òwe 15:1

Ẹsẹ Bíbélì · YCB

Òwe 15:1

Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.

Ka gbogbo orí náà: Òwe 15

Nínú àyíká ọ̀rọ̀

1Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.

2Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.

3Ojú Olúwa wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.

4Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.

Òwe 15

Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì

Berean Standard BibleProverbs 15:1A gentle answer turns away wrath, but a harsh word stirs up anger.

Àwọn ìtọ́kasí

Àwọn àyọkà tí àwọn òǹkàwé máa ń so mọ́ èyí jùlọ.

Òw 10:12Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.
Òw 25:15Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.
Òw 15:18Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.
Òw 29:22Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè, onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.
Òw 28:25Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.

Orísun: OpenBible.info, CC BY 4.0 · Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. · Orísun àti ẹ̀tọ́